Ilé ẹjọ́ gba béèlì akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College márùn ún tó ń jẹ́jọ́ lórí ikú Sylvester Oromoni

Aworan Ile ẹkọ Dowen college ati oloogbe Sylvester Oromoni

Oríṣun àwòrán, other

Awọn akẹkọọ marun ti ọlọpaa mu lori iku akẹkọọ ile ẹkọ girama Doyen College nilu Eko, Sylvester Oromoni ti foju ba ile ẹjọ bayii.

Wọn gbe awọn akẹkọọ marun un naa lọ si ile ẹjọ lori ẹsun igbimọpo ṣiṣẹ ibi ati ṣiṣekupa Sylvester Ọrọmọni.

Lẹyin ọpọ atotonu ile ẹjọ Majisireeti agba to wa ni Yaba nilu Eko gba beeli ọkọọkan wọn pẹlu Miliọnu kan naira.

Ni ọjọ kẹsan an, oṣu kejila ọdun yii ni wọn ko awọn akẹkọọ naa si ahamọ awọn majesin, Juvenile home lori ẹsun naa.

Adajọ Majisireeti agba Ọlatunbọsun Adeọla to gbọ ẹjọ naa fi aye silẹ fun beeli wọn pẹlu oniduro meji-meji.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

Adajọ Majisireeti agba Adeọla ṣalaye pe ọkan lara awọn oniduro akẹkọọ kọọkan gbọdọ jẹ obi wọn, ti wọn si gbọdọ ṣe iwe adehun lati tẹle ilana naa.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

Bakan naa lo tun paṣẹ ki wọn gba gbogbo iwe irinna silẹ okeere wọn si ile ẹjọ, ki wọn si ṣe ifidimulẹ ootọ adirẹsi ile ti wọn ba fi silẹ wọn ko si gbọdọ rin jinna kọja kilomita meji si ile ti wọn n gbe nigba gbogbo.

Àkọlé fídíò, Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí