Electoral act amendment: Buhari dá àbádòfin àtúnṣe ètò ìdìbò padà sílé aṣòfin àgbà

Buhari

Oríṣun àwòrán, @Muhammadu Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣalaye idi ti ko fi buwọlu abadofin atunṣe ilana eto idibo lorilẹ ede Naijiria.

Lọjọ Aje ogunjọ oṣu Kejìl,á ọdun 2021 yii ni Aarẹ Buhari kọ lati buwọlu aba naa ti ile aṣofin fi ṣọwọ si i.

Ninu lẹta ti ààrẹ kọ si adari ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja, Sẹnẹtọ Ahmed Lawan, Buhari ni bi gbogbo nkan ṣe ri ni Naijiria lọwọ yii ni ko jẹ ki oun buwọlu aba naa.

Àkọlé fídíò, 8kyti,j

Akọkọ, Buhari ni eto abo to mẹhẹ kaakiri orilẹ ede Naijiria jẹ ọkan lara idi ti oun ko fi buwọlu atunṣe abadofin eto idibo naa.,

Eleyii to tun dabi rẹ ni pe owo gọbọi ni idibo abẹnu gbangba laṣa ta yoo jẹ.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

Aarẹ Buhari tun sọ pe abadofin atunṣe eto idibo ti ile gbe wa siwaju oun yoo fi ẹtọ awọn ọmọ Naijiria dun wọn.

Buhari tun sọ ninu esi rẹ pe iyanjẹ awọn ẹgbẹ oṣelu kekeke ni abadofin naa yoo jẹ ti oun ba le buwọlu u.

Àkọlé fídíò, BBC News: Ifọrọwerọ pẹlu Sẹnẹtọ Olujimi

Buhari ni oun ko da igbesẹ yii gbe, o ni oun gba imọran lati awọn ileeṣẹ ijọba ati oniruuru ajọ ijọba.

Aarẹ ni oun fun ra oun tun ṣe agbeyẹwo abadofin naa fini fini ki oun to gbe igbesẹ lati ma buwọlu luu.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí o kò kàsí nípa mátírẹ́sì tí o ń sùn, ṣùgbọ́n tó ń ní ipa nínú ayé rẹ

Buhari ni o san ki awọn ẹgbẹ oṣelu maa yan awọn oludije sí ipo kan tabi omiran for eto idibo.

Bi Aarẹ Buhari ṣe kọ láti buwọlu aba atunṣe eto idibo lana ti fa awuyewuye.

Ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ aarẹ.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀