Aisha Buhari pregnancy rumour: Ṣé oyún ní Aisha Buhari ni àbí àìsàn jẹjẹrẹ tàbí kí ló fa ẹ̀jọ́ lórí ikún aya Aàrẹ Buhari?

Oríṣun àwòrán, @Buhari Sallau
Ọrọ naa jọ gate ko jọ gate........
O ṣe ẹsẹ gate gate abi ká sì ní o ṣe ikun gate gate ni?
O ṣe bi ẹni pe awada ni ọrọ yi nigba to kọkọ lu sita ṣugbọn bi awọn eeyan ṣe n gba a bi ẹni n gba ọti mu jẹ kí àwa naa sọ pe ka mu u wa si eti igbọ́ yin.
Ọrọ ti a n sọ nipa rẹ leleyii to ni i ṣe pẹlu iroyin pe iyawo Aàrẹ orílẹ̀-èdè Naijiria, Aisha Buhari ti loyun.
- Ìdí rèé tí Buhari fi kọ̀ láti buwọ́lu àbá àtúnṣe ètò ìdìbò Nàìjíríà
- Damola Olatunji di èrò àtìmọ́lé nítorí èdè àìyedè tó wáyé láàrin òun àti ọlọ́pàá l'Eko
- Wọ́n ti iléèwòsàn pa nítorí àwọn àlùjànú tó n fi ipá bá àwọn nọ́ọ́sì lòpọ̀
- Iléèṣẹ́ ológun fi sọ́jà obìnrin sí àtìmọ́lé nítorí pé kọ́pà fún un ní òrùka ilérí ìgbeyàwó ní Kwara
- Tinubu, fi ipò ààrẹ sílẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ lọ́dún 2023- Osita Okechukwu
- Wo bí olórí ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀, Gabriel Boric, ẹni ọdún 35 ṣe wọlé ìbò ààrẹ Chile
Bẹẹ ni.
Loju opo ayelujara l'awọn eeyan ti n mu ọrọ yi bẹnu leyin ti wọn ri aworan Aisha Buhari nibi ti o ti n jijọ rin pẹlu aare Buhari ni papakọ ofurufu Abuja.

Wọn n dari Irinajo bọ lati ipade Naijiria ati Turkey ni wọn ya aworan wọnyí.
B'awọn kan ṣe n sọ pé imura ati iriri iyawo aarẹ da bí ẹni pe o loyun nise lawon ileesẹ iroyin miran n so pe aarẹ kan lo mu iyawo ààrẹ.

Oríṣun àwòrán, @Buhari Sallau
Eyi tó jo pe aworan yi jọ ní pe ikun iyawo aarẹ dàbí pé o tobi ju ti tẹlẹ lọ.
Boya o loyun tabi ko ni ko si ẹni tó le so pato.
Kini wọn sọ fun BBC?
Amọ, Mallam Hadi Uba to jẹ oluranlowo pataki nile iṣẹ Aarẹ to n mojuto iṣẹ ni ọọfiisi iyawo Aare, Aisha Buhari salaye fun BBC pe ko ko ko lara iyawo aarẹ le ati pe ko sí nkankan to se.
O fi kun un pe awọn iroyin ẹlẹjẹ pe iyawo aarẹ ni arun jẹjẹrẹ kìí ṣé ootọ.
"Mo fẹ fi da yin loju pe alaafia ni iyawo aarẹ wa ati pe ko ni aisan jẹjẹrẹ tabi pe o loyun bi awon kan ṣe n gbe iroyin yi kaakiri"
"Awọn to fẹ dá wàhálà silẹ ni wọn n gbe iroyin yi kaakiri.
Se ẹ mọ pé kò sí irú ara ti awọn eeyan ko le da pẹlu aworan lóde oni?"
Esi ree ti Sulaiman fọ ni ìdáhùn sí ọrọ yi.
Ṣugbọn Aisha Buhari ti fi aworan sí ojú opo Instagram rẹ to se afihan igba ti balẹ sí papakọ ofurufu Abuja ni ọjọ Aiku.
Aisha Buhari, ẹni aadọta ọdun ati ọkọ rẹ Muhammadu Buhari ẹni ọdún mọkandinlọgọrin ti jọ bí ọmọ marun un ti wọn sì ní ọmọ ọmọ kan.

















