Wọ́n ti iléèwòsàn pa nítorí àwọn àlùjànú tó n fi ipá bá àwọn nọ́ọ́sì lòpọ̀

Ilewosan Shale

Oríṣun àwòrán, zimlive

Wọn ti gbe ilẹkun ileewosan alabọde kan ti pa ni agbegbe Umzingwane lẹyin ti awọn nọọsi pariwo sita pe awọn ẹmi airi n ba awọn ni ibalopọ.

Awọn ẹmi airi naa ni iroyin tun sọ pe wọn dan nkan wo ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ Shale to wa nitosi ileewosan naa.

Eyi si ti mu ki awọn olukọ ma a dunkooko pe awọn yoo fi iṣẹ silẹ ti atunṣe ko ba waye laipẹ.

Oṣu Keji ọdun yii ni wọn ṣi ileewosan Shale ni agbegbe Umzingwane ni orilẹ-ede Zimbabwe, lati pese ilera fun awọn ara abule to n gbe ni agbegbe naa.

Pẹlu bi wọn ti ṣe ti i pa, awọn ara abule n rin irianjo lọ si ilu miran, Esigodini lati gba itọju.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

Ara abule naa kan, Themba Moyo, sọ fun iwe iroyin ZimLive pe wọn ti ileewosan ọhun pa lẹyin ti nọọsi obinrin meji ati ọkunrin kan to jẹ oṣiṣẹ ibudo ayẹwo salọ nitori pe awọn kan n fi ipa ba wọn lopọ.

"Ti wọn ba ji ni ouwrọ, niṣe ni oju ara wọn ma n tutu pẹlu apẹẹrẹ pe wọn ni ibalopọ. Oru ni iṣẹlẹ naa n waye.

"Ni bayii, oluranlọwọ nọọsi kan pere ati aṣọgba to n gbe ninu abule nkan lo ku sibẹ."

Awọn araalu sọ pe oṣu Kẹsan-an ni ikọlu naa bẹrẹ.

Ilewosan Shale

Oríṣun àwòrán, zimlive

Wọn ni awọn nọọsi naa kọkọ ma n fi ẹsun ọkan han ti wọn ba ti bẹrẹ iṣẹ ni owurọ pe o rẹ awọn nitori pe awọn ko sun oorun gidi ni oru.

Nigba to ya ni wọn tu aṣiri nkan to ti n ṣẹlẹ ni ileewosan ọhun.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí o kò kàsí nípa mátírẹ́sì tí o ń sùn, ṣùgbọ́n tó ń ní ipa nínú ayé rẹ

Ara abule kan sọ pe "ọkunrin to n ṣiṣẹ ni ibudo ayẹwo ni iriri to ba ni lẹru pupọ lalẹ ọjọ kan. Niṣe ni awọn alujọnu naa n fa nkan ọmọkunrin rẹ.

"Pẹlu inira lo fi n rin ni owurọ ọjọ keji nitori nkan ọmọkunrin ati koropọn rẹ wú. Laipẹ yii ni oyun bajẹ mọ iyawo rẹ lara, igbagbọ wa si ni pe o le jẹ nitori iṣẹlẹ awọn alujọnu ni."

Àkọlé fídíò, BBC News: Ifọrọwerọ pẹlu Sẹnẹtọ Olujimi

Bakan naa ni iriri awọn olukọ to n gbe ninu ọgba ile ẹkọ alakọbẹrẹ to wa nitosi ileewosan naa.

"Nigba miran, ita gbangba ni awọn olukọ obinrin yoo ti ba ara wọn ni owurọ."

Àkọlé fídíò, Davido yàtọ̀ s'àwọn ọ̀dọ́ olórin kan tó lè yẹ̀yẹ́ àgbà olórin, òun ló kọ́kọ́ ná mi ní béèlì N1M lágbo - Yinka Ayefele

Awọn alaṣẹ ilu naa ti bẹrẹ igbesẹ lati wadii iṣẹlẹ ọhun pẹlu agbara ibilẹ, ti wọn si ni iya yoo jẹ ẹnikẹni ti aṣiri ba tu pe oun lo ni awọn alujanu naa.

Gbajugbaja ni ọrọ nipa awọn ẹmi airi ti wọn n pe ni Tikoloshes, ni orilẹ-ede Zimbabwe.

Àkọlé fídíò, Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...