Zimbabwean Prostitutes: Olówó nàbì ní bí kò bá sí owó, àwọn ń gba iké àgbàdo àti agolo ẹ̀wà fún ìbálòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn olowo nabi lorilẹede Zimbabwe ni iroyin kan ti sọ pe wọn ti n gba ike agbado ati agolo ẹwa fun ibalopọ.
Ilana pasipaarọ ọja fun ibalopọ yii ni awọn olowo nabi naa n lo ni ẹkun Dema, lorilẹede naa.
Gẹgẹ bi ileesẹ iroyin abẹle kan, New Zimbabwe ti wi, awọn olowo nabi naa lo wa n rawọ ẹbẹ sijọba atawọn onileesẹ nla nla fun owoya ti owo ori rẹ ko gunpa.
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mẹ́sàn ká lẹ́yìn tí ọkọ fi ẹ̀sùn olè kan ìyàwó
- 'Ọkọ mi mú ọ̀bẹ jáde lápò, ó sì gé imú mi jábọ́...'
- Ẹyin ni wọ́n fi n gba ìbále ẹlòmiran lára wa ki a to lọ pàde àwọn oníbara
- Òyìnbó ẹni ọdún 46 wá ṣe mọ̀'mí n mọ̀ ọ́ ní Kano pẹ̀lú Isah olólùfẹ́ rẹ̀
- Àfi ìgbà tí mo bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá mí nínú ìrìnàjò ìfẹ́- Roshan
Owo yii ni wọn ni awọn fẹ maa lo lati fi se okoowo kekeke ti yoo maa mu owo wa, tawọn yoo fi gbọ bukata ẹbi wọn ti ebi n pa.
Ọkan lara awọn olowo nabi to ba iwe iroyin naa sọrọ ni "Laye ijọun la maa n gba dọla marun fun oorun alẹ ọjọ kan.
Lasiko yii, dọla kan pere la n gba, ka le ri owo ra ewebẹ ati tomato ta fi se ounjẹ fun awọn ọmọde ti ebi n pa."
Bakan ni obinrin olowo nabi naa tun sisọ loju rẹ pe ọmọ mẹta ni oun bi, ti ọkan ninu wọn si wa ni kilaasi kẹrin nile ẹkọ girama.
O fikun pe ọmọ oun naa nilo owo lati fi orukọ silẹ́ fun idanwo asejade nile ẹkọ girama (ZIMSEC) nigba ọmọ keji wa ni kilaasi kinni nile ẹkọ girama.
O ni ọmọ oun kẹta lo wa ni kilaasi keje nile ẹkọ alakọbẹrẹ bayii, ti bukata oun lojumọ si n ga soke si.
"Mo ti wa n gba ike agbado ati agolo ẹwa gbigbẹ bayii dipo owo fun ibalopọ, nitori ti mo ba ri awọn eroja ounjẹ wọnyi gba, o daju pe awọn ọmọ mi yoo jẹ adalu ẹwa."
Oninabi miran tun salaye pe awọn tiẹ setan lati sisẹ ọmọ ọdọ amọ awọn ara agbegbe naa kii sanwo.
Awọn olowo nabi yii to ba iwe iroyin ọhun sọrọ lo n kopa nibi eto idanilẹkọ kan jẹ ara ọna lati wa adinku si ọwọja kokoro arun HIV atawọn arun mii ta le ko lati ara ibalopọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Lẹ́yìn ọdún méjì tí iná ìjà tí n jó láàrin wọn, Lizzy Anjorin sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Toyin Abraham ṣẹ̀ ẹ́
- Ìjà Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin tún búrẹ́kẹ́
- Òfo lásán ni ìpinnu àwọn gómìnà tó fòfin de àṣà ìdaranjẹ̀ nígboro - Iléeṣẹ́ ààrẹ
- Ẹ̀yà Ìgbò ní aya mí láti Ìlà òòrùn Gúúsù Naijiria, mi ò fẹ́ ìyapa torí Yòrùbà Nation - Akeredolu
- Ètò àgùnbánirọ̀ NYSC yóò máa tẹ̀síwájú - Mínísítà ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ àteré ìdárayá
- Ṣé o mọ̀ pé o leè rí omira abẹ́ obìnrin míì rà tàbi yọ̀ǹda tìrẹ fún lílò?
- Akeredolu, yéé rí Ààrẹ Buhari fín mọ́- BMO


















