Yoruba Nation: Gómìnà Akeredolu ní àná Ìgbò ní òun, òun sì tako ìyapa Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ni ọrọ pọ lori idi ti oun ko fi le faramọ iyapa Naijria nitori idasilẹ Yoruba Nation.
Gomina Akeredolu sọ ọrọ yii nibi ipade asọyepọ ati agbeyẹwo Iwe Ofin ilẹ wa tọdun 1999 eyi to n waye ni ilu Akure ati kaakiri orilẹede Naijiria.
Ipade apero naa lo jẹ ara ọna abayọ si gbogbo iṣoro to n koju Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Lẹ́yìn ọdún méjì tí iná ìjà tí n jó láàrin wọn, Lizzy Anjorin sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Toyin Abraham ṣẹ̀ ẹ́
- Ìjà Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin tún búrẹ́kẹ́
- Ètò àgùnbánirọ̀ NYSC yóò máa tẹ̀síwájú - Mínísítà ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ àteré ìdárayá
- Ṣé o mọ̀ pé o leè rí omira abẹ́ obìnrin míì rà tàbi yọ̀ǹda tìrẹ fún lílò?
- Akeredolu, yéé rí Ààrẹ Buhari fín mọ́- BMO
Akeredolu, lasiko to n sọrọ ni ifimọṣọkan ati irẹpọ lorilẹede Naijiria jẹ oun logun gidigidi ju nkan miran lọ.
O wa parọwa si awọn aṣofin ni ile igbimọ asofin ipinlẹ ati ti ijọba apapọ, lati tẹti bẹlẹjẹ gbọ igbe awọn eniyan nipa ohun ti wọn fẹ, to si jẹ ẹdun ọkan wọn.

''O ṣe ni laanu pe awọn eniyan ko ni igbagbọ ninu ijọba mọ nitori awọn iṣẹlẹ to n waye lemọ-lemọ ti ko si si ọna abayọ lori rẹ.
Ifẹ awọn eniyan ni pe ki ijiroro waye lori awọn ohun to jẹ wọn logun, bi eto ijọba ''True Federalism'' ati ọna abayọ to gbooro si iṣekupani ọlọgọọrọ to n waye lorilẹede Naijiria.
''Gbogbo igba ni mo ma n sọ wi pe orilẹede Naijiria ko gbọdọ yapa nitori pe ti a ba wa papọ ni ilọsiwaju le waye.''

Iyawo mi, Ila oorun Guusu ni o ti wa, awọn ọmọ mi si fẹ awọn ololufẹ wọn ti kii ṣe ọmọ Yoruba, nitori naa iyapa kọ ni ọna abayọ.''
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ondo ni ijọba apapọ ko kan le e sọ pe ki ija dopin pẹlu ọrọ ẹnu laarin awọn darandaran ati agbẹ, lai si ọna abayọ to munadoko.
- Ètò àgùnbánirọ̀ NYSC yóò máa tẹ̀síwájú - Mínísítà ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ àteré ìdárayá
- Ó d'ọbẹ̀! Ìjọba àpapọ̀ dá £4.2b tó gbà lọ́wọ́ James Ibori padà fún ìpínlẹ̀ Delta
- Ìjà Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin tún búrẹ́kẹ́
- Ṣé lóòtọ́ ni àdó olóró búgbàmù ní iléèwé kan ní ìpínlẹ̀ Ebonyi lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun?
- Ọkọ́ mi lá àlá pé bàálù já, kó tó kú nínú ìjàmbá bàálù lọ́jọ́ kẹta - opó olóògbé
Akeredolu fikun pe, ara awọn eniyan ti kan nipa iṣekupani awọn ọdaran darandaran yii, ti a ko si gbọdọ fi oju tẹmbẹlu nkan to n ṣẹlẹ si awọn araalu.












