Villarreal win Europa League: Ìdè ọjọ́ pípẹ́ já, Villarreal fi Man United ṣe àtẹ̀gùn dé ilẹ̀ ìlérí ní àṣekágbá Europa League

Oríṣun àwòrán, Twitter/villareal/manchester united
Pẹnariti ni Villarreal fi gba ife idije Europa League mọ Manchester United lọwọ l'Ọjọru.
Ami ayo 11-10 ni wọn fi sọ ireti Man United di ofo lẹyin ti goli wọn, De Gea ko ri pẹlu pẹnariti to kẹhin mu.
Igba akọkọ re e ti Villarreal gba ife naa.
Bi Villareal ṣe jawe olubori yii mu ko jẹ igba akọkọ ti wọn gba ife to nitumọ, bakan naa lo si jẹ igba kẹrin ti olukọni Artsenal nigba kan, Unai Emery, gba ife naa.
Asiko ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mẹẹdọgbọn ni Gerard Moreno gba bọọlu sinu awọn, ko to o di pe Manchester United ri i da pada ni iṣẹju karundinlọgọta lati ọwọ Edinson Cavani ati Marcus Rashford.
Ko si si ẹni to gba bọọlu sinu awọn lẹyin naa titi ti ifẹsẹwọnsẹ fi pari, eyi to mu ki wọn o gba 'extra time'.
Ọdun 2014 ni aṣekagba Europa League ti wọ extra time kẹhin , nigba ti Emery Sevilla fi pẹnariti naa Benfica.
Villarreal ko gba ife pataki kankan ri lati ọdun mejidinlaadọrun to ti wa, ko to o di pe wọn fi iya jẹ Arsenal ni saa yii lati bọ si ipele to kẹhin.
Manchester United si ti bẹ awọ̀n ololufẹ wọn, paapaa awọn to lọ si papa iṣere ni Gdansk pe awọn mọ riri wahala wọn
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post














