Premier League final day: Aston Villa fọ́ Chelsea lẹ́nu, àmọ́ Tottenham daṣọ àṣírí bò wọ́n

Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ agbabọọlu ti pegede lati kopa ninu idije Champions league ti saa to n bọ lẹyin ti wọn ṣe ipo kẹrin, bi o tilẹ jẹ pe Astọn Villa san bantẹ iya fun wọn jẹ.

Pẹlu ọpọlọpọ idunnu ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea fi side eto lori papaa, amọ ẹgbẹ agbabọọlu Astọn Villa na fihan pe awọn ko wa sere.

Chelsea

Oríṣun àwòrán, Reuters

Agbabọọlu mẹwaa lo pari ifẹṣẹwọnṣẹ naa lori papa lẹyin ti Balogun ikọ Chelsea, Cesar Azpilicueta gba Red Card nitori aṣemaṣe.

Amọ, adura gba fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea nitori ikọ Leicester City to fidi rẹmi nile nigba ti wọn koju ẹgbẹ agbabọọlu Tothemham.

Eyi tumọ si wipe Chelsea pari pẹlu ami ayo 67 lori tabili nigba ti Leicester City pari pẹlu ami ayo 66.

Team P GD Pts

Man City 38 51 86

Man Utd 38 29 74

Liverpool 38 26 69

Chelsea 38 22 67

Leicester 38 18 66

Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images