Man City vs Chelsea: Chelsea fi ogun ẹ̀yìn ja Manchester City ṣáájú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá Champions League

Manchester Citi Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọjọ Abamẹta ni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ko ba gba ife ẹyẹ idije Premier League ti saa bọọlu yii to ba jẹ pe wọn lu Chelsea ni papa iṣere Etihad.

Ṣugbọn Man City ni lati duro di ọjọ mii ki wọn to le gba ami ẹyẹ naa nitori Chelsea ti ẹyin gbe ru wọn.

Raheem Sterling lo kọkọ gba goolu sawọn Chelsea ni abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa.

Lẹyin naa ni Manchester City tun ri pẹnariti eyi ti wọn gbe fun Sergio Aguero wi pe ko gba.

Ṣugbọn akọ ni Aguero fi gba pẹnariti ọhun eyi ti golu Chelsea mu lai laagun rara.

Abala keji ere bọọlu naa ni Chelsea ni sọji mọ Man City lọwọ.

Hakim Ziyech lo kọkọ da goolu ti Sterling gba wọle pada, ki Marcos Alonso to fi ọba le.

Ni bayii, Man City ṣi le gba ife ẹyẹ EPL lọjọ Aiku ti Aston Villa ba lu Manchester United ni Villa Park.

Lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un lawọn mejeeji yoo jọ pade ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije Champions League.