Ban on Open Grazing: Iléeṣẹ́ ààrẹ ní fífi òfin de ìdaranjẹ̀ nígboro lòdì sófin

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilé iṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà bẹnu àtẹ́ lu àwọn àbájáde tí àwọn gómìnà Ìpínlẹ̀ to wa lẹkun Gúúsù Naijiria, tí wọn fofinde dídá ẹran ká ní àwọn ìpínlẹ̀ wọn.
Bakan naa ni wọn fi ẹ̀sùn kan pé oselu ni wọn fi ọ̀rọ̀ náà ṣe láti lo agbára wọn.
Èyí jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan ti olùrànlọ́wọ́ pàtàkì àgbà fún ààrẹ Buhari lórí ìpolongo àti eto ìròyìn, Garba Shehu fọwọ́ sí lọ́jọ́ ajé.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Lẹ́yìn ọdún méjì tí iná ìjà tí n jó láàrin wọn, Lizzy Anjorin sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Toyin Abraham ṣẹ̀ ẹ́
- Ìjà Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin tún búrẹ́kẹ́
- Ẹ̀yà Ìgbò ní aya mí láti Ìlà òòrùn Gúúsù Naijiria, mi ò fẹ́ ìyapa torí Yòrùbà Nation - Akeredolu
- Ètò àgùnbánirọ̀ NYSC yóò máa tẹ̀síwájú - Mínísítà ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ àteré ìdárayá
- Ṣé o mọ̀ pé o leè rí omira abẹ́ obìnrin míì rà tàbi yọ̀ǹda tìrẹ fún lílò?
- Akeredolu, yéé rí Ààrẹ Buhari fín mọ́- BMO
Ó ṣàlàyé pé àwọn gómìnà lẹkun Guusu kò wá ojútùú kankan sí ìṣòro àwọn àgbẹ̀ àti darandaran, eyi tó ń dá ojú orileede yìí bolẹ̀ láti ọdún pípẹ́ sẹ́yìn.
Àwọn gómìnà naa, nínú ìpàdé kan tí wọn ṣe ni ìlú Asaba ní Ìpínlẹ̀ Delta, ni wọn dijọ fẹnuko pé àwọn tí fi òfin de asa kí ẹnikẹni máa ko ẹran jẹ́ káàkiri ní Ìpínlẹ̀ àwọn.
Agbẹjọ́rò àgbà fún Nàìjíríà Abubakar Malami si lo kọkọ naka alebu sì igbesẹ awọn gomina naa.
Ilé iṣẹ́ ààrẹ fìdí rẹ múlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí nílò àyẹ̀wò lábẹ́ òfin nítorí pé ó yẹ kí gbogbo ará ìlú ni anfani láti rìn jákèjádò gbogbo ìpínlẹ̀ lai ni ìfòyà.
Ó wa pe akiyesi àwọn ènìyàn sì pe ààrẹ tí fi ìgbà kan buwọ́lu àwọn ọ̀nà àbáyọ sì ọ̀rọ̀ àwọn àgbẹ̀ àti darandaran, kí aawọ wọn lè wá sí òpin.
Àtẹ̀jáde náà ká báyìí pe: "Ààrẹ Muhammadu tí ṣàlàyé láti mú òpin dé bá wàhálà láàrin àwọn darandaran àti àwọn àgbẹ̀ àti àwọn ìṣòro mìíràn tó nii ṣe pẹ̀lú darandaran agbebọn tó ń pá ènìyàn kiri."
Ààrẹ tí buwọ́lu àwọn ìlànà kan pàtó láti mú òpin bá hilahilo gẹ́gẹ́ bí Alhaji Sabo Nanono, to jẹ́ mínísíta fún ètò ọ̀gbìn ṣe sọ nínú àbájáde ìwádìí tó ṣe tí o sì gbé fún ààrẹ láti buwọ́lu nínú oṣù kẹrin ọdún.
Igbesẹ yii si waye ṣáájú kí àwọn gómìnà tó lọ máa pàṣẹ fifi ofin de àwọn darandaran nípa bibuwọlu iwe gẹgẹ bi ara ọgbọn òṣèlú láti fi agbára wọn hàn.
Ó hàn gbangba gbangba pé kò sí ọ̀nà àbáyọ tàbí ojútùú tí wọn ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn darandaran, tí wọn ń fi ojoojumọ jajaku akátá láti ìgbà dé ìgbà.
Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlú ni ìhà gúúsù àti ara ìlú jákèjádò Nàìjíríà ni ẹ̀tọ́ láti gbọ́ nípa ọ̀nà àbáyọ tí àwọn olórí wọn tàbí aṣojú se, kii se bí ki wọn wá máa nawọ́ òfin pé "kii ṣe ìpínlẹ̀ mi.
Bákan náà ló fi hàn pé nnkan ti wọn n beere fún, mú ìwádìí lọ́wọ́ lábẹ́ òfin ẹ̀tọ́ ọmọniyan ni Nàìjíríà àti ẹ̀tọ́ olúkúlùkù láti rìn sì ibi tó bá wu u ni ìpínlẹ̀ mẹ́rẹ̀rindinlógójì, lai fi ìpínlẹ̀ to tí wá se.
Ṣùgbọ́n ó dùn mọ́ ni pé ìjọba tí gbe ìgbésẹ̀ ṣáájú àsìkò yìí, ààrẹ tí aawọ àwọn àgbẹ̀ àti àwọn darandaran n kọ lominu, ti wá ojuutu sì nípa bibuwọlu pé kí wọn ṣètò ibùjẹ ẹran ní gbogbo ìpínlẹ̀.















