Domestic violence: ‘Ẹ̀rù ayé mi sì ń bà mí’ – obìnrin tí ọkọ gé imú rẹ̀

Zarka ni inu oun dun si iṣẹ abẹ to yọri si rere

Oríṣun àwòrán, BBC

Iwa jagidijagan si obinrin kii ṣe ohun tuntun ni Afganistan, koda, iwadii kan tilẹ sọ pe ida mẹtadinlaadọrun un awọn obinrin orilẹ-ede naa lo n dojukọ iwa ipa ninu ile ati nipa ibalopọ.

Eyii to buru ju ni bi awọn mọlẹbi atawọn ọkọ awọn obinrin naa ṣe ma n na wọn, ti wọn si maa n da kẹmika acid si wọn lara, tabi gun wọn lọbẹ.

Lara awọn obrinrin to n dojukọ iru nnkan bayii ni Zarka, ti ọkọ rẹ fi ọbẹ ge ni imu sọnu.

Zarka ni ọkọ oun ko jẹri oun, nitori igbagbọ rẹ pe oun maa n ṣe agbere.

O ni "Ọkọ mi maa n sọ pe alagbere ni mi, ṣugbọn mo maa n sọ pe ọrọ ko ri bẹ, ibi ti wahala ti bẹrẹ niyẹn."

Àkọlé fídíò, Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀
Zarka

Oríṣun àwòrán, Dr Zalmai Khan Ahamadzai

Zarka fẹ ọkọ rẹ ni nnkan bi ọdun mẹwaa sẹyin, o si ni ọmọkunrin to jẹ ọmọ ọdun mẹfa.

Bo tilẹ jẹ pe o ti mọ ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa lara ki ọkọ rẹ maa na a, ko lero pe yoo de ibi pe imu rẹ yoo di gigie sọnu.

Ija bẹrẹ nigba ti aye sun Zarka nile ọkọ rẹ, to si fi ile naa silẹ lati pada sile baba rẹ.

Ọjọ keji to gbe igbesẹ yii ni ọkọ rẹ ọhun wa si ile baba rẹ naa, to si ṣeleri pe oun ko ni na arabinrin naa mọ.

Gẹgẹ bi ohun to sọ fun BBC, Zarka ni oun ko mọ pe ijiya pọmbele ni ipadabọ oun sile ọkunrin naa yoo jẹ.

Lẹyin ọjọ diẹ to pada sile ọkunrin naa ni ọkọ rẹ ọhun bẹrẹ si ni na a, to si fi ọbẹ ge imu rẹ sọnu.

Àkọlé fídíò, 'Mo fẹ́ gbé ògo ìdílé ìyá àti bàbá mi ga pẹ̀lú iṣẹ́ Mọkálìíkì'
Zarka ni inu oun dun si iṣẹ abẹ to yọri si rere

Ninu igbiyanju lati lẹ imu naa pada lo ti ṣalabapade dokita Zalmai Khan Ahmadzai, to jẹ onimọ ijinlẹ nipa titun ẹya ara to ti bajẹ ṣe.

Dokita Zalmai ni iriri ọdun mẹwaa nipa ṣiṣetọju awọn obinrin ti ọkọ wọn ba ge ẹya ara wọn sọnu latari iwa jagidijagan ninu ile.

Zalmanni ni obinrin naa burẹwa gidi gan ki oun to dawọ le iṣẹ abẹ naa, ṣugbọn ni bayii o tis ̣e e wo loju.

Zarka fun BBC laṣẹ lati ka bi o ṣ e n gbawosan silẹ, o si ṣalaye ohun ti oju rẹ ri nile ọkọ rẹ naa.

Kekere ni wọn ti fa Zarka le ọkọ rẹ lọwọ ni paṣiparọ ọkan lara awọn aburo ọkọ rẹ to jẹ obinrin, ṣugbọn lẹyin to de ile ọkọ naa tan lo to ri pe ilu bara ni ọkọ naa maa n na awọn obinrin.

O ni oun ko mọ idi to fi n na oun, bo tilẹ jẹ pe kii mu siga, kii mu igbo bẹẹ ni ori rẹ ko daru.

Zarka lo ibomu

Oríṣun àwòrán, BBC

Zarka ṣalaye pe lẹyin ọdun kan ti oun fẹ arakunrin naa lo ni oun fẹ gbe iyawo tuntun miran, ṣugbọn o maa n fi ikanra airi owo ori iyawo tuntun naa san mọ oun.

Dokita to ṣetọju Zarka, Zalmai sọ pe oun ko gba kọbọ lọwọ rẹ bo tilẹ jẹ pe iye owo iṣẹ oun ko din ni ẹgbẹrun meji dọla.

O ni afojusun oun ni bi Zarka yoo ṣe gbagbe ohun to ti sẹlẹ latẹyinwa.

Ni ti Zarka, o ni ọmọ oun ṣi wa lọdọ awọn ẹbi ọkọ oun, ojojumọ si ni oun maa n ronu nipa alaafi rẹ.