The Church of Beer: Ìnira nlá ni òfin tó dé kátà-kárà ọtí líle lásìkò Covid-19 jẹ́ fún ilé ìjọsìn wà

Oríṣun àwòrán, Twitter
Orileede South Africa ti bẹrẹ ifilọlẹ ofin to de ọti tita lasiko Covid -19 fun igba ẹlẹẹkeeji.
Ijọba South Africa ṣe agbekalẹ ofin to de karakata ọti lilẹ lati mu adinku ba iye awọn eeyan to n lọ si ile iwosan.
Agbekalẹ ilana yi ni ipalara awọn ara ilu lọna orisirisi paapa awọn ile itaja to n ta ọti ati awọn ile ounjẹ.
Amọ ṣa ọrọ naa ṣeni ni kayeefi bi awọn ile ijọsin kan ti ṣe n kerora lori ofin to tako tita ọti yi nitori pe awọn ko ni ribi jọsin bo ti ṣe yẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Gabola-Church
Ọrọ naa ṣe yin ni haa hun abi?
Ile ijọsin kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni Ghabola Church to wa ni guusu olu ilu Johannesburg ni awọn ọmọ ijọ bẹẹ ti ni ki ijọba wa nkan ṣe si ofin ma ta ọti yi.
Nile ijọsin taa n wi yi, igbagbọ wọn ni pe mimu ọti lamupara jẹ ọna kan gbogi tawọn fi le ba Ọlọrun sọrọ .
Gabola ti wọn fi sọri ile ijọsin naa tunmọ si ọti mimu ni ede SeTswana.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Gabola-Church
Oludasilẹ ile ijọsin naa Pope Tsietsi Makiti salaye fun akọroyin BBC to ṣabẹwo sile ijọsin naa lati mọ bi nkan ṣe n lọ lasiko yi pe ''awọn ko kọ ki ijọba ti awọn mọle titi di igba ti Jesu yoo fi pada wa.''
Tsietsi to jẹ ẹni ọdun marundinlọgọta ṣalaye pe nkan bi ọdun meji sẹyin lawọn bẹrẹ ile ijọsin awọn.
''Ni ile ijọsin Gabola, o maa gbe ọti rẹ wa ti pasitọ yoo si ba ọ ya si mimọ ki o fi ma ṣe akoba f'ara rẹ''
O ni nigba ti ofin yi si ti bẹrẹ niṣe lawọn ko duro loju kan ṣe ijọsin ki awọn agbofinro ma baa mu awọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìjọba fòfin de kátà-kárà ọtí líle lásìkò igbele covid-19, àwọn èèyàn ń fi ọ̀gbìn oyinbo àti ọkà bàbà ṣe ọtí lílé labẹle
Òfin tí ìjọba fi dé oko-owo ọtí líle lásìkò igbele Coronavirus ni orílẹ̀ èdè South Africa tí mú kí ọ̀pọ̀ ibùsùn làwọn ilé ìwòsàn ṣófo, mú kí àìmọye oko-owo dojú de, tí làásìgbò oselu sì ń peléke si, èyí tó mú kí àwọn ènìyàn nifẹ báyìí sí ọgbin òyìnbó tá mọ si Pineapple.Ṣáájú kí àrùn Coronavirus tó wọlé sí ilẹ̀ South Africa, ó to àwọn èèyàn bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹrinlelọgbọn, tí wọn máa ń gbé wa sáwọn ílè ìwòsàn ni orílẹ̀ èdè náà ni ọṣẹ kan ṣoṣo, ẹyọ tó lọ́wọ́ ọtí líle ninu.Àmọ́ láti ìgbà tí ìjọba tí ṣe ìkéde konile ó gbele láti dènà itankalẹ àrùn Coronavirus ni osu kẹta ọdún, adinku tí bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà sì idà méjì nínú mẹta, èyí tíì ṣe ẹgbẹ̀rún méjìlá péré.
- Ọ̀nà àbáyọ fún olóyún lásìkò àjàkálẹ̀ ààrùn Covid-19
- Ẹnìkan ṣoṣo nínú ìdílé kan ni yóò gbà N20, 000 owó ìdẹ̀rùn igbele Covid-19 - ìjọba àpapọ̀
- Lórí ọ̀rọ̀ Ogun Majek, mi ò lọ́rọ́ láti sọ, ẹ lọ pe ẹni tára rẹ̀ kò yá- Mr. Latin lórí àìsàn Ogun Majek
- Ewu ń bẹ! Coronavirus lè tara òkú Abba Kyari ran àwọn tó péjú síbi ìsìnkú rẹ̀- Ààrẹ ẹgbẹ́ dókítà ní Nàìjíríà
- Auxiliary lo ń jà káàkiri ìlú Ibadan lọ́jọ́ Aje, ẹgbẹ́ ọlọkọ èrò NURTW kọ - Ejiogbe
- Ìyàn ń bọ̀ ní Nàìjíríà lẹ́yìn coronavirus àyàfi... - ẹgbẹ́ àgbẹ̀ kìlọ̀Ọjọgbọn Charles Parry, to ń ṣe àfihàn bí òfin ti jọba fi dé oko-owo ọtí ṣe mú adinku bá iye èèyàn ti igbimọ oluwadi nípa ìwòsàn ni South Africa ń yẹ wo sọ pé, "ipa tó ṣe pàtàkì ni eyi". Parry wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé " tá bá fi òpin si ofin tó dena kata-kara ọtí líle yìí, a rí tó aláìsàn ẹgbẹ̀rún márùn-ún tó ní nkan ṣe pẹlu ọtí líle, tí yóò máa yọjú ni ọṣẹ kọ̀ọ̀kan". Àmọ́ àwọn onímọ̀ isegun, lásìkò tí wọn ń rọ ijọba láti mase gbé ẹsẹ kúrò lórí òfin tó fi dé kata-kara ọtí lile, tún tọkasi pé ọtí amuju máa ń mú ki èròjà tó ń dáàbò bo agọ̀ ara di alailagbara ni, tó sì leè ni ipa lórí bí èèyàn ṣe ń mi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Covid-19 yóò nípa burúkú lórí àwọn ọmuti alamupara, bẹ́ẹ̀ si ni nilẹ South Africa, àwọn èèyàn ń gbé ní àgbègbè tó kún fún èrò" Nítorí náà, kata-kara ọtí líle leè mú kí itankalẹ àrùn Covid-19 ni agboolé pọ si, nítorí àwọn èèyàn máa ń ṣe awọmu ni, ó si ṣeé ṣe kí ọwọja ìwà ipá sì abo àti ọmọdé pọ sì" Ọjọgbọn Parry tún ṣe ikilọ.Àmọ́ ń jẹ ó ṣeé ṣe kí wọn tún ṣe àfikún àkókò òfin to de oko-owo ọtí líle, to tí wáyé ṣáájú fún ọ̀sẹ̀ márùn-ún tẹ́lẹ̀, síwájú sí, lẹyin ọgbọnjọ oṣù kẹrin tó yẹ kí òfin náà kasẹ nlẹ?Bẹẹ si ni ọga ọlọ́pàá tí tí ìbínú àwọn èèyàn sókè nígbà tó kéde pé káwọn agbofinro máa lo ọwọ líle àti ọna ti ko bófin mú, fìyà jẹ àwọn èèyàn tó ba tako òfin náà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita fún ọrọ ọlọ́pàá, Bheki Cele, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ fún sísọ ọ̀rọ̀ kobakungbe àti iwanwara rẹ lórí amusẹ òfin to de ọtí tita, lo sí ti fi ikilọ síta laipẹ yìí pé, àwọn ikọ òun "yóò ba àwọn ohun èlò ti wọn ba fi ń ta ọtí jẹ".Àmọ́ Apiwe Nxusani-Mawela, tí ṣe obinrin àkọ́kọ́ tí yóò dá ileesẹ ipọnti silẹ, to tún jé alaga ẹgbẹ́ àwọn oloko owó ọtí títa ni South Africa ṣàlàyé pé "èyí kò dára rárá", to sì fi ibẹru hàn pé, ó ṣeé ṣe kí oko-owo òun dojú de, tí òfin tó dé kata-kara ọtí líle náà bá tẹsiwaju. O ni "ọpọ èèyàn ti ko ni isẹ lọ́wọ́ lo ń fi ọtí pa ìrònú rẹ, dípò kí wọn lo oogun oloro, tó sì tún daba pé, tí ìjọba bá fi ààyè gba títa ìwọ̀nba ọtí díẹ̀, èyí kò ní jẹ́ kí oko-owo òun dẹnu kọlẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bákan náà ni Nick Smith, tíì ṣe ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó ní ibùdó ipọnti lẹ́yìn odi ìlú Cape Town sọ pé " isẹ tán fún wa nìyẹn"O fikùn pé " òfin tó dé oko-owo ọtí náà tí ṣe àkóbá nla fún àwọn oko-owo alabọde".Ṣùgbọ́n ní báyìí, àwọn èèyàn ti ń lo ọgbin oyinbo pineapple láti fi ṣe ọtí líle nínú ilé.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ̀pọ̀ èèyàn sì lo ń wá fídíò kiri lórí ayélujára nípa bí wọn ṣe leè lo pineapple àti ọkà bàbà pẹlu sogomu fi ṣe ọtí líle ni abẹle, tí wọn ń pè ní "Umqombothi".Ikilọ sì ti ń lọ káàkiri pé tí wọn kò bá pèsè ọtí ìbílẹ̀ náà pẹ̀lú imọtoto, a jẹ pe ewu ń bẹ ní oko longẹ.













