Revolution Now: Lẹ́yìn ọdún kan, DSS tún ti mú Olawale Bakare tó jẹ́jọ́ pẹ́lúu Sowore l'Osogbo

Awon osise DSS n wọ oluwọde kan lọ

Oríṣun àwòrán, citymirrornews.com

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọwọ awọn oṣiẹ alaabo DSS tun ti tẹ ajafẹtọ ọmọniyan kan to jẹ alakoso ẹgbẹ Revolution now ni ipinlẹ Osun, Ọlawale Bakare.

Iwoyi esi naa ni awọn oṣiṣẹ ajọ DSS mu Ọgbẹni Ọlawale Bakare ti wọn si gbe oun ati Ọmọyẹle Ṣoworẹ lọ sile ẹjọ nigba naa.

Loni to jẹ ọdun kan geerege lẹyin iwọde ati wiwọ gbaga ofin naa, Ọlawale Bakare tun ti ko sinu áwọ̀n àwọn agbofinro DSS naa lasiko to fi n lewaju ikọ ẹgbẹ Revolutionnow nilu Osogbo tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ọṣun.

Awọn oluwọde kan ni ilu Osogbo

Oríṣun àwòrán, citymirrornews.com

Lasiko ti iwọde naa fi n waye ni orita Ọlaiya ni ilu Osogbo, nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ naa ti n fẹhonu han lori ohun ti wọn pe ni aiṣedede iṣejọba, aisi ohun elo amayedẹrun to duro deede, iwa ipaniyan bi ẹni pẹran lọwọ awọn agbefọba ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn oluwọde naa n ba awọn ọlọpaa sọrọ lọwọ lawọn oṣiṣẹ DSS naa ya bo wọn ti wọn si mu Ọgbẹni Ọlawale Bakare atawọn aṣiwaju ẹgbẹ naa kan ki awọn yoku to juba ehoro.

Sowore pàtẹ ìfẹ̀hónú hàn míì lónìí

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, @yelesowore

Oludije fun ipo aarẹ ati asaaju ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni Revolution Now, Omoyele Sowore ti fi sita pe akọtun iwọde miran ti bẹrẹ kaakiri awọn ipinlẹ Naijiria.

Sowore, ẹni to fi ikede naa soju opo Twitter rẹ tun mu wa si iranti pe o pe ọdun kan bayii ti ikọ agbofinro gbe oun sahamọ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Awọn Iroyin tẹẹ le nifẹ si

Iwọde naa, to pe ni #Revolution Now lo sọ pe yoo bẹrẹ ni aago mẹjọ aarọ ladugbo Ikeja nilu Eko ati Unity Fountain nilu Abuja.

Nilu Abuja, Sowore fi aworan sita pe ṣe ni wọn ko awọn sọja di gbogbo ọna ki awọn ma baa ṣewọde.

Awọn sọja nigboro iluu Abuja

Oríṣun àwòrán, @yelesowore

Nigba to n salaye idi ti iwọde naa yoo fi waye, Sowore ni "ede kan ṣoṣo tijọba gbọ ni ifẹhonu han, bẹẹ si ni ọpọ ohun ti araalu n pohungbẹ rẹ, nijọba kọ eti ikun si".

Bakan naa, awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ, Revolution Now ni idi tawọn fi n wọde ni pe "a nilo iyipada adari ni Naijiria, ki awn to ni ifẹ araalu lọkan bọ sibẹ kawọn oloṣelu oni janduku ko ra wọn danu".

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

O tun wa kesi awọn araalu to fẹ lati dara pọ mọ ifẹhonu han naa yika Naijiria, lati ko ara wọn jọ soju popo fun iwọde alaafia.

Asaaju ikọ Revolution Now tun rọ awọn Oluwọde lati lo ibomu, ki wọn si ta kete sira wọn lati dena arun Coronavirus.

Iwọde yii ni ipinlẹ Eko naa ti gberasọ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Àkọlé fídíò, 'Mo fẹ́ gbé ògo ìdílé ìyá àti bàbá mi ga pẹ̀lú iṣẹ́ Mọkálìíkì'