Lock down: ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ní ẹnìkan ṣoṣo nínú ìdílé kan ni yóò gbà N20, 000 owó ìdẹ̀rùn igbele Covid-19

Sadiya farouq

Oríṣun àwòrán, Sadiya_farouq

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà tí kéde pé, èèyàn kan ṣoṣo ni yóò gbà owó ìdẹ̀rùn tí ìjọba ń pèsè fún ìdẹ̀rùn igbele àrùn Coronavirus.

Minisita fún eto ìdẹ̀rùn aráàlú, Sadiya Umar-Farouq lo sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń bá àwọn akọroyin sọ̀rọ̀ n'ilu Abuja.

Bákan náà lo sísọ lójú rẹ pé, ìjọba àpapọ̀ tí ń wá ọ̀nà láti gba nọ́mbà idamọ BVN aráàlú tó tọ́ láti gba owó náà, èyí tí kò ní jẹ ki àṣírí bí wọn ṣe ń pín owó náà bo fún aráyé.

Umar-Farouq ni, irọ ni pé èèyàn méjì nínú ẹbí kan gbà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírà ẹni kọ̀ọ̀kan bíi owo ìdẹ̀rùn, ó ní èyí kò leè ṣẹlẹ̀ láéláé.

"Ìlànà tá ń gba pín owó ìdẹ̀rùn lè pupọ nítorí náà, kò ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ìdílé kan láti gba owó náà.".

Minisita fún ìdẹ̀rùn aráàlú náà fikùn pé, ileesẹ òun ti fi ọkọ akeru ọrinlerugba ó dín kan (279) ransẹ sáwọn ìjọba Ìpínlẹ̀ nínú ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin tọọnu èròjà onihoro tí ìjọba àpapọ̀ fọwọ́ sì, gẹgẹ bii eroja oúnjẹ feto ìdẹ̀rùn aráàlú.

Lock down: Wo ọ̀nà mẹ́ta tí ìjọba fẹ́ gbà pín owó ìrànwọ́ fún ọmọ Nàìjíríà lásìkò kónílé-ó-gbélé yìí

Minisita n pin owo fun an eeyan kan

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad

Boo ba lẹbẹrun marun naira ni banki, gbagbe owo iranwọ latọdọ ijọba.

Ijọba apapọ lo ṣalaye pe owo iranwọ ti awọn n pin lati bomi pa inira arun coronavirus lorilẹede Naijiria ko si fun ẹnikẹni to ba ni owo to pọ ju ẹgbẹrun marun naira ninu aṣuwọn ifowopamọsi rẹ.

Minisita fun amojuto iṣẹlẹ ajalu lorilẹede Naijiria, Sadiya Farouq lo sọ bẹẹ.

O ni ọna mẹta ni ijọba yoo gba mu awọn ti yoo janfani eto naa. Akọkọ ni iwe iforukọsilẹ awọn eeyan to ku diẹ kaato fun lawujọ (Social register), ọna keji ni wiwo awọn akuṣẹ ni ilu nla nipa lilo nọmba idanimọ asuwọn igbalode (BVN) lati ṣawari awọn ti owo inu aṣuwọn wọn ko ba ju ẹgbẹrun marun lọ.

Bakan naa lo ni lilo awọn nọmba ibanisọrọ lati mọ awọn ti iye owo ipe to wa lori ẹrọ ibanisọrọ wọn ko ba ti ju ọgọrun naira lọ.

Lock down: Akojọpọ nkan amayedẹrun ti ijọba ti fun awọn ọmọ Naijiria nitori aarun coronavirus

Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Ṣaaju àsìkò yìí, ni aarẹ Buhari ti kọkọ ti awọn ẹnubodè to wọ Naijiria pa pẹlu igble ọlọjọ mẹrinla akọkọ ni Abuja, ipinlẹ Ogun ati Eko.

Ó si tun ti awọn papakọ ọkọ ofurufu pa lẹyin ti Naijiria ti ni akọsilẹ ajakalẹ arun coronavirus.Bakan naa ni Ijọba kede pe oun yoo pin owó àti oúnjẹ fun awọn alainiláwùjọ ni eyi ti wọn ni o wa fun miliọnu mẹta aabọ idile.

Yatọ si igbesẹ ijọba apapọ, àwọn ipinlẹ ti aarun naa ti de gbé igbesẹ tí wọn naa.Ipinlẹ KanoIjọba ipinlẹ Kano kede isede ọlọsẹ kan lẹyin to kede pe ẹni akọkọ ti ni aarun naa ni ipinlẹ Kano lati le dena itankalẹ rẹ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ijọba ipinlẹ Delta:Gomina ipinlẹ Delta, ti kede pe ko gbọdọ si lílọ ati bibọ laarin aago meje irọlẹ si meje àárọ̀ nitori aarun coronavirus.Gomina Ifeanyi Okowa sọ pe ọna lati dẹ́kun itankalẹ aarun naa ni ijọba ṣe pasẹ naa.Ọjọ kinni, oṣu Kẹrin ni isede naa kọkọ bẹ̀rẹ̀, ki gomina tun to o kede ọjọ mẹrinla miran.

Gomina Okowa sọ pe wọn yoo bẹ̀rẹ̀ si ni pin oúnjẹ fun araalu laarin wakati mejilelaadọrin.

Bakan naa ni wọn yoo pin iboju-bomu ti ijọba ipinlẹ naa ṣe funra rẹ ni ọ̀fẹ́ nigba ti yoo ba fi di opin ọsẹ yii.

Ijoba ipinle Eko

Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sanwo-Olu

Ijọba ipinlẹ Eko lo kọkọ kede pe ki awọn ọjà nlanla nipinlẹ naa ko wa ni titi pa.

Ọjọ karun un ti awọn ọlọja ti wa nile ni Aarẹ Muhammadu Buhari kede ofin konile o gbele fun ọsẹ meji, eyi to bẹ̀rẹ̀ ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹta.Bakan naa lo ni ki gbogbo ileewe o dawọ duro.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ofin tun de ipejọpọ eniyan to le ni aadọta ti wọn tun pada dinku si ogún, eyi to kan awọn ile ijọsin ati òde àríyá.Ọjọ ti ofin ọlọsẹ meji naa yẹ ko parí, ni Aarẹ tun kede afikun ọsẹ meji.Odi ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹrin ki opin to o de ba a.Ijọba ipinlẹ Eko kede pe oun ti n pin oúnjẹ bi irẹsi, sipagẹti, éwà, gàárì, ororo, ati tomato lílọ̀ fun awọn arugbo, akanda ẹ̀dá ati awọn alaini ni ipinlẹ naa.

Gomina Sanwo Olu ni nitori inira ti isede naa yoo mu ba wọn lasiko isede akọkọ ni oun ṣe bẹrẹ. Bakan naa ni ijọba kede lọjọ Iṣẹgun pe oúnjẹ sísè yoo jẹ́ pinpin lojoojumọ fun awọn ọdọ bi ẹgbẹrun lọna ọgọrun.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Yatọ si ọrọ oúnje, ijọba ipinlẹ Eko tun seto ẹ̀kọ́ kikọ lori redio ati tẹlifiṣan fun awọn akẹ́kọ̀ọ́ lasiko igbele naa.Bakan naa ni Gomina Sanwo-Olu kede pe ki ajọ amusẹya yọnda gbogbo ọkọ̀ to gbẹsẹ le lati ọjọ kinni, oṣu Kẹta.Igbesẹ Ijọba Ipinlẹ Ondo

Arakunrin Akeredolu

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo naa, Rotimi Akeredolu ti kede isede laarin aago meje irọlẹ si meje àárọ̀ nitori aarun coronavirus.Saaju ikede yii to waye lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin , ijọba ti fofin de ipejọpọ ọpọ eniyan, ileewe wa ni titi pa, ko si lílọ ati bibọ ọkọ lati ipinlẹ miran.Lati tu awọn eniyan ipinlẹ naa lara, ijọba kede pe oun yoo pin oúnjẹ ọ̀fẹ́ fun eniyan rẹ.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Ijọba ipinlẹ EkitiIgbesẹ ijọba ipinlẹ Ekiti ko fi bẹ ẹ yatọ.

Oun naa ti gbogbo ileewe pa, o fofin de ipejọpọ ọpọ eniyan, o ti awọn ọjà pa, o ti gbogbo ẹnu ibode ipinlẹ naa, o fofin de lílọ bibọ ọkọ.Bakan naa lo kede pe dandan ni lilo iboju-bomu laarin igboro.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin l'oun naa tun kede afikun ọsẹ meji si isede to wa nilẹ tẹlẹ. Lara awọn nkan to ṣe lati mu itura ba araalu ni ẹ̀kọ́ kikọ lori redio ati tẹlifisan fun awọn akẹ́kọ̀ọ́. O tun kede pe oun yoo pese nkan amayedẹrun fun awọn araalu.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Igbese ipinlẹ ỌṣunỌjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta ni isede kọkọ bẹ̀rẹ̀ ni ipinlẹ Ogun ni eyi ti ko yọ awọn ileewe ati ile ijọsin silẹ.Ijọba kede pe oun yoo pin oúnjẹ fun awọn araalu.

Ọjọ Iṣẹgun ni Gomina Gboyega Oyetola tun kede afikun ọjọ mẹrinla si isede naa.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Gomina Oyetọla si tun kede pe oun yoo san ẹgbẹrun lọna ogún Naira fun eniyan 15,289 to jẹ arugbo ati akanda ẹ̀dá.

Bakan naa lo sọ pe ijọba yoo pin ẹgbẹrun meje àbọ̀ Naira fun ikọọkan awọn ọdọ 10,628 to n ṣe iṣẹ pẹpẹẹpẹ fun ijọba ipinlẹ naa.

Ipinlẹ OgunIpinlẹ yii ni wọn ti ri ẹni to kọkọ ni aarun coronavirus ni orilẹ-ede Naijiria.Oun naa si wa lara ipinlẹ ti ijọba apapọ kede isede fun, bo tilẹ jẹ pe ko bẹ̀rẹ̀ lọjọ ti Aarẹ Buhari kede.Ilana isede tìrẹ naa ko yatọ si ti ipinlẹ Eko.Gomina ipinlẹ naa kede pe ijọba fun awọn arugbo, akanda ẹ̀dá ati awọn alaini ni oúnjẹ ọ̀fẹ́.

Skip X post, 7
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 7

Ijọba tún seto idanilẹkọọ ori redio ati tẹlifisan fun awọn akẹ́kọ̀ọ́ lasiko igbele naa.

Bakan naa ni wọn fin oogun apakokoro si aarin ìlú.Ofin afikun isede ti Aarẹ Buhari kede ko yọ ipinlẹ Ogun naa silẹ.

Awọn igbesẹ wo ni ipinlẹ pinlẹ Kwara ti gbé?

Ọjọ kẹsàn-án, oṣu Kẹrin, ni ijọba ipinlẹ Kwara kede konile-o-gbele fun ọjọ mẹrinla. Gomina Abdul Razak fi ofin de ipejọpọ ọpọ eniyan, o ti awọn ọjà pa, o ti gbogbo ileewe pa, to fi mọ igbokegbodo ọkọ.

Ijọba ipinlẹ Kwara tun kede pe oun yoo tu awọn ẹlẹ́wọ̀n kan silẹ lati le dena itankalẹ aarun coronavirus.Bakan naa lo sọ pe awọn sọọbu oúnjẹ le ma a si lọjọ Aje, Ọjọru ati Ẹti, laarin aago mẹjọ àárọ̀ si mejila ọsan.

Igbesẹ Ipinlẹ OyoNi ti ipinlẹ Oyo, o fi ofin de ipejọpọ ọpọ eniyan, o ti gbogbo ileewe pa, o ti awọn ọjà nla pa.O si ti fín oogun apakokoro si aarin ìlú.

Skip X post, 8
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 8

Ipinlẹ Anambra naa ko gbẹyin:Ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ni ipinlẹ naa kede ẹni akọkọ to ni aarun coronavirus ni ipinlẹ naa.Ṣugbọn ko to o di ọjọ naa ni ijọba ti n gbe igbesẹ lati dena rẹ.Lara ohun to ṣe ni pe o kede konile-o-gbele,

O tun fi ofin de ipejọpọ ọpọ eniyan, o ti gbogbo ileewe pa, o ti gbogbo ẹnu ibode ipinlẹ naa,

Bakan naa lo tun kede pe oun ti fun awọn arugbo àti aláìní ni oúnjẹ ọ̀fẹ́.

Skip X post, 9
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 9

Ijọba tún kede pe oun yoo dá idamẹwaa owo ori ọdun 2019 padà fun awọn to n san án deedee

O si tun kede ofin konile-o-gbele.

Awọn ọmọ Nàìjíríà yarí lórí àfikún ọjọ ìséde tí Ààrẹ Buhari kéde

Lockdown: Àwọn ọmọ Nàìjíríà yarí lórí àfikún ọjọ ìséde tí Ààrẹ Buhari kéde

Oníruuru fọnran ló lu orí àtẹjisẹ twitter pa láti fi han bi olúkúlùkù ṣe n se ààbò lóri àdúgbò wọ́n.

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad

Saaju ki aarẹ to ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ ni alẹ ọjọ Aje ni ọpọlọpọ ti fi ireti ohun ti wọn n reti lati ọdọ aarẹ hàn nikete ti ikede jade pe aarẹ Muhammadu Buhari yoo tun sọrọ l'ori itankalẹ aarun coronavirus.

Loju opo Facebook BBC news Yoruba, Shakirat Oke Ayanbode sọ pe ki aarẹ Buhari o tu awọn silẹ kuro ninu ofin konile o gbele, tabi ki ijọba o fun ẹni kọọkan ni apo irẹsi kọọkan nitori ki ebi o ma ba a pa wọn.

Ninu ọrọ ti ẹ, Harbimoo Ola sọ pe ki aarẹ Buhari o ma ṣe fi ọjọ kun isede ọlọjọ mẹrinla to wa ni ipinlẹ Eko, Ogun ati ilu Abuja.Fun awọn kan bi Queen Ola Ifeolamitide, ọrọ lori bi awọn adigunjale ṣe n da awọn agbegbe kan laamu niipinlẹ Eko ati Ogun lo fẹ ki aarẹ o sọrọ le lori.

Eero awọn wọnyi ko yatọ rara si nkan ti ọpọ sọ loju opo náà, ati ni awọn oju opo ayelujara bi twitter.Ṣugbọn sa, ijakulẹ ati ibanujẹ ni ọrọ Aarẹ Buhari ba de fun ọpọlọpọ ọmọ Naijiria, nitori bi aarẹ ṣe fi ọjọ mẹrinla miran kun isede. Bakan naa ni awọn kan sọ pe ko mẹnuba ọrọ eto aabo lasiko yii.Fun Prince Adewale Amidu, o ṣọrọ lori bi Ààrẹ Buhari ṣe sọ pe bi awọn orilẹ-ede miran naa ṣe n ṣe niyẹn nitori coronavirus.

Àkọlé fídíò, Hakeem: Mo lè sọ arúgbó dí ọmọge nígbà tó bá wù mí

"Walahi ọdaju abiamọ ni Aarẹ Muhammadu Buhari yi sá. Ẹ gbọ awọn ọrọ to n sọ lẹnu; wọn ti Saudi Arabia pa... O wa beere pe 'ṣe bi awọn olori Saudi Arabia ṣe n ṣe àwọn eniyan wọn nìyí? Ọrọ airounjẹ jẹ ati ebi ti isede naa ti fa ni ọpọlọpọ awọn to sọrọ fi sita, pe o yẹ ki ijọba o pese nkan amayedẹrun fun araalu ki ebi o ma ba pa wọn saaju coronavirus.Ẹ ka ekunrẹrẹ aroye wọn ni :

Ṣugbọn o, oju ọtọ ni Dare Adediji fi wo afikun isede naa. O sọ pe ki awọn eniyan o fara da a fun anfaani gbogbo araalu."Ẹyin eniyan mi ẹ jọwọ, ẹ jẹ kani suru fun awọn ijọba ba wa nitori fun anfaani ara wa ni..."Ẹ le wo fidio ọrọ ti aarẹ ba awọn ọmọ Naijiria sọ ni:

Coronavirus lockdown: Inú ìbèrù bojo ni àn gbé báyìí nítori àwọn jàndàkú- Olùgbé ilú Eko

Awon olopaa ati odaran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Inú ìbèrù bojo ni àn gbé báyìí- Awọn ènìyàn àdúgbo, Ogba, Agbado Ijaye àti Agege

Láti bi ojọ mẹ́ta sẹyin ni gbogbo ènìyàn ti n nagùn #LagosUnres àti #AgegeUnrest lori àtẹjisẹ twitter sùgbọn ni òru moju òní, o dàbi ẹni pe ọrọ náà ti fẹ kọja afarada.

Ọpọ àwọn olugbé ìpínlẹ Eko pàápàá jùlọ àwọn ènìyàn àgbègbè ọgba, Agege, Abesan, Ipaja, Ayobo lo ti gba ori twitter kan pe awọn o loju oorun mọ nitori iwa ìdigun jale to kún àdúgbò náà

Oníruuru fọnran ló lu orí àtẹjisẹ twitter pa láti fi han bi olúkúlùkù ṣe n se ààbò lóri àdúgbò wọ́n.

Skip X post, 10
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 10

Skip X post, 11

End of X post, 11

Skip X post, 12

End of X post, 12

Lára àwọn to bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lori iṣẹ̀lẹ̀ yìí, wọ́n sàlàyé pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò si eyí to sẹlẹ̀ si àwọn gangan síbẹ àwọn fi ojú ri láti ọ̀ọ̀kan bi àwọn ọmọ jàndùkú ṣe n kó , ọbẹ, àdá, òkúta àti igò, ti wọ́n a si maa rin ni ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ láti wọ ilé tabi já sọọ̀bù

Gẹ́gẹ́ bi ọkùnrin kan to n gbé agbègbè, Agbado Ijaye se sọ pé òpópóna ti o jẹ ikéji si òun ni oun ti ri bi àwọn ọdọ ti ọjọ ori wọ́n ko ti le jú ogun ọdun lọ se pa itú orísiri.

O ni wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ si ni lẹ okúta láti le àwọn ènìyàn sá ti wọ́n o si já sọọbu tábi ilé ti wọ́n ba ri wọ láti lọ kó gbogbo ǹkan ti wọ́n ba rí nibẹ.

Gẹ́gẹ́ bi o ṣe sọ o yẹ ki ìjọba tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi sàdá ki ọ̀rọ̀ maa ba bẹyìn nítori pe, lọ́wọ́ bayii àwọn ọdàran yìí kan n fi àdá àti okúta dẹrùba àwọn ènìyàn, sùgbọ́n ti o ba yá wọ́n o bẹ̀rẹ̀ si ni lo ibọn.

Ọkúnrin náà to fẹ ki BBC fi orúkọ bo oun lásírí sàlàyé pé nínú ibẹrun bojo ni àwọn n gbe ni àdúgbò báyìí nítori ẹru n ba olúkúlu láti jáde.

Bakan náà ni ẹlomiran to n gbe agbegbe Agege sàlàyé pe ni àgbègbè ti oun, ṣe ni oun gbọ iró ibọ̀n sùgbọ́n oun ko tilẹ̀ le jáde láti yoju sibẹ̀.

Lórí àtẹjisẹ twitter, oníruuru ẹri ti a ko ti le fi idi rẹ múlẹ̀ lo súyọ bi olúkúlúku se n sọ ǹkan to o sẹlẹ̀ ládùgbò wọ́n, ti wọ́n si n sọ idí ti wọ́n fi rò pe àwọn ènìyàn n jale ni irú àsìkò yii.

Àwọn kan ni, ìjọba ló fàá ti irú èyi fi n ṣẹlẹ nítori pe wọ́n ko ṣe ètò ti o yẹ fun ará ilú ki wọ́n to ni ki wọ́n gbélé jòkó.

Skip X post, 13
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 13

Skip X post, 14

End of X post, 14

Ẹ̀wẹ̀ àjọ ọlọpàá ni àwọn sa gbogbo ipá àwọn la'ti ri dáju pé, gbogbo àwọn oniwa janduku yìí so agbéjẹ́ mọ́wọ́

Skip X post, 15
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 15