Coronavirus Lockdown: À ń gbáradì láti pàṣẹ òfin kóníléógbélé tó bá dójúẹ̀ tán - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo

Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Rotimi akeredolu

Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe idi ti oun ko ṣe tii paṣẹ igbele patapata ni awọn iṣoro to rọ mọ igbele ọhun.

Kọmiṣona ọrọ to n lọ ni ipinlẹ naa, Donald Ojogo lo sọ bẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC.

O ni ijọba n fi akoko yii mura silẹ fun awọn eto lati ran awọn ara ilu lọwọ, ati pe o n fi akoko yii fun wọn laaye lati ra ounjẹ sile.

Àkọlé fídíò, Amugbalẹgbẹ fun Gomina Akeredolu, Ọmọwe Doyin Ọdẹbọwale koro oju si

Ojogo sọ pe ijọba yoo pasẹ ofin konileogbele patapata to ba jẹ dandan, ṣugbọn o ti gbe agadagodo ṣenu gbogbo ibode to wọ ipinlẹ ọhun bayii.

O ni " A ko sọ pe a ko ni paṣẹ konileogbele o, ṣugbọn a n gbadura ki ọrọ naa ma de ipele yẹn ni.".

Kọmiṣọna ọhun sọ pe ijọba paṣẹ ofin gbele ẹ laarin aago meje alẹ si meje owurọ nitori awọn onifaaji to n gbafẹ lawọn agbegbe kan nilu Akure.

Nipa bi ipinlẹ Ondo ṣe n gbaradi de arun Covid-19, o ni ijọba Ondo n sa ipa rẹ lati gbogun ti arun naa.

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ́ àrùn Coronavirus leè wà lára èèyàn títí láílái?

Ẹwẹ, onimọ eto ilera kan, dokita Wilson Ikubese sọ pe ko yẹ ko ri bẹ.

Ikubese ni kii ṣe oru nikan ni arun Coronavirus n rin, nitori naa ko yẹ ki ijọba paṣẹ konileogbele laago meje alẹ si meje owuro.

Dokita ọhun fi kun pe ti ijọba apapọ ba fẹ kapa arun Coronavirus patapata, niṣẹ lo yẹ ko kede ofin konileogbele kaakiri gbogbo Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ṣé òfin kónílé-ó-gbélé lè mú àdínkù bá ìtànkálẹ̀ Coronavirus?

Ikubese ni ko yẹ ki ijọba kede konileogbele nikan, o yẹ ko ṣe ipese awọn ohun amayedẹrun fun awọn ara ilu.

Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan lati ma ṣe imọtoto araẹni gẹgẹ bi ajọ to n gbogun ti ajakalẹ ni Naijiria, NCDC ṣe gbe kalẹ.

Akeredolu ní ọlọ́pàá ń lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀láwọn tó ń kó Coronavirus wọ Ondo

Ijọba ipinlẹ Ondo ti fẹsun kan awọn agbofinro pe awọn gan n pẹlu ọbọ jawura lori bi iye awọn to ni aarun Coronavirus ṣe n waye ni ipinlẹ naa.

Eeyan mẹta ni ayẹwo ṣi fihan pe o ni arun yii ni ipinlẹ Ondo, ṣugbọn ijsba ipinlẹ naa n ṣalaye pe awọn to wọ ilu lẹyin igba ti wọn ti iloro ẹnubodu ipinlẹ naa gbogbo lawọn eeyan naa wọle.

Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Arakunrin akeredolu

Eeyan mẹta ni ajọ to n dena ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ṣi kede pe o laarun naa ni ipinlẹ Ondo eleyi ti o n kọ ijọba ipinlẹ naa lominu ni lọwọlọwọ.

Amugbalẹgbẹ fun gomina Rotimi Akeredolu lori akanṣe iṣẹ, Ọmọwe Doyin Ọdẹbọwale ṣalaye fun BBC News Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe awọn ọlọpaa ti wọn ko sẹnu ibọde ipinlẹ naa lati maṣe jẹ ki ọkọ kọọkan wọle lati awọn ipinlẹ miran n gbabọde fun ijọba ni.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, owo ẹyin lawọn ọlọpaa naa n gba lọwọ awọn awakọ ti wọn si n jẹ ki wọn wọle.

Coronavirus Lockdown: Gómìnà Akeredolu fárígá,Ó ṣèlérí àti ti ìpínlẹ̀ Ondo pa bí èèyàn míràn ba kó àrùn Coronavirus níbẹ̀

Arakunrin Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Arakunrin Akeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ti kede ofin konile-o-gbele kaakiri ipinlẹ Ondo.

Igbele naa yoo maa waye laarin agogo meje irọlẹ si meje aarọ.

gomina Akeredolu ninu ọrọ to ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọ lọsan ọjọ Iṣẹgun kminu lori iha kokanmi tawọn eeyan, paapaa awọn ọlọja, awọn onile ọti, awọn onile ijọsin atawọn eeyan kan n kọ si ilakaka gbogbo ti ijọba n sa lati dena itankalẹ arun naa.

Gomina Akeredolu ni bi oun ba tun gbọ pe eeyan kan ni ipinlẹ naa tun ko arun naa, oun yoo ti gbogbo ipinlẹ Ondo pa ni.

Arakunrin Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Arakunrin Rotimi Akeredolu

Gomina Akeredolu ni o ṣenmi laanu pe pẹlu gbogbo igbesẹ ti ijọba n gbe lati dena ajakalẹ arun naa nibẹ, eeyan kan ṣi lee rapala gbe arun naa wọle.

O ni ijọba yoo gbe igbesẹ to laapọn sii lati dẹkun itankalẹ arun Coronavirus ni ipinlẹ Ondo.

Afikun nipa aarun Coronavirus
Banner

Bàbá ẹni ọdún 71 fi ẹ̀ṣẹ́ rán ìyàwó rẹ̀ lọ s'ọ́run àpàpàǹdodo ní Ìdànrè

Igboro ilu Idanre

Oríṣun àwòrán, others

Agbẹ kan ni ilu Idanre ni ipinlẹ Ondo ti fi ẹṣẹ lu iyawo rẹ pa.

Baba agbẹ ẹni ọdun mọkanlelaadọrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Eric Olowokande ni awọn ọlọpaa ṣalaye pe o fi ẹṣẹ lu iyawo rẹ, ti orukọ rẹ n jẹ Mojere.

Gẹgẹ bi ohun ti eeyan kan to ṣoju rẹ sọ ni kete ti ọrọ ja jo alagba Olowokande lọwọ tan lo bẹlugbẹ to si na papa bora lati lee sa mọ panpẹ awọn ọlọpaa lọwọ.

Awọn to ṣoju wọn ṣalaye pe ọrọ lo ṣe bi ọrọ laarin lskọlaya mejeeji yii eleyi to di yanpọnyanrin laarin wọn debi pe baba agbalagba yii ys ẹṣẹ ti iyawo rẹ yii titi ti obinrin naa fi ju ẹmi silẹ

Wọn ni ni kiakia ni wọn gbee digbdigba lọ si ile iwosan nibi ti dokita ti sọọ di mimọ pe arabinrin naa ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Àkọlé fídíò, Ijọba ipinlẹ Ondo gbe agadagodo sẹnu ọna awọn ile ijọsin to tapa sofin konileogbele

Coronavirus lockdown: Síńimá kòṣewòtán, Pásítọ̀ fo fẹ́ǹsì láti sá mọ́ agbófinró lọ́wọ́ ní Àkúrẹ́

Oniruuru ọbẹ nijọ iku erin. Oriṣiriṣi iṣẹlẹ manigbagbe lo ti n waye lati igba ti aṣẹlẹ igbele lati dena itankalẹ arun COVID-19 yii ti bẹrẹ.

Ni ilu Akurẹ tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo, nṣe ni pasitọ kan gbiyanju lati fo fẹnsi to yi ijọ rẹ ka nibi to ti n gbiyanju ati sa mọ awọn agbofinro ikọ amuṣẹya lori ofin gbele ẹ ti ijọba ipinlẹ Ondo gbe kalẹ lọwọ.

Ijọba ipinlẹ Ondo ati ẹgbẹ ọmọlẹyin kristi nibẹ ti kọkọ fi ẹnu ko pe awsn yoo ṣeto ipade ajọyọ ọdun Ajinde ni ọjọ Aiku ki ijsba to yi ohun pada nitori eeyan kan to tun ni arun naa nipinlẹ ọhun.

Eyi lo mu ki amugbalẹgbẹ fun gomina ipinlẹ Ondo lori ọrọ akanṣe iṣẹ, Ọmọwe Doyin Ọdẹbọwale ati ikọ amuṣẹya ijọba o fọn si igboro lati rii daju pe awọn ileejọsin tẹle aṣẹ yii.

Àkọlé fídíò, Coronavirus lockdown: Síńimá kòṣewòtán, Pásítọ̀ fo fẹ́ǹsì láti sá mọ́

Bi o tilẹ jẹ pe awọn ileejọsin kan tẹle ofin yii pe kawọn ileejọsin ileejọsin o maa ṣi ilẹkun wọn fun ijọsin, ọpọ awọn ile ijọsin miran lo keti ikun si aṣẹ naa.

Lara awọn ileejọsin yii ni ijọ CAC Okelisa, ijọ TAJEM ni Irese, ijs Assemblies of God lagbegbe olufoam nibi ti awọn ọmọ ijọ ti tilẹkun mọ ara wọn sinu ijọ naa ki awọn ọmọ ikọ amuṣẹya naa to fi tipatipa ṣi ilẹkun naa.

Amọṣa ọrọ naa di ti sinima awodamiẹnu nigba ti pasitọ ijọ naa gbiyanju ati fo fẹnsi lọna ati sa mọ awọn ikọ amuṣẹya naa lọwọ.

Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Rotimi akeredolu

Amugbalẹgbẹ fun gomina lori ọrọ akanṣe iṣẹ, ọmọwe Doyin Ọdẹbọwale ṣalaye pe gbogbo awọn Pasitọ tọwọ ba naa nijọba yoo fi jofin lẹyin ti oun ba ti jabs fun gomina lori rẹ.

O ni awọn ileejọsin maraarun ni wọn ti ti pa.

Bakan naa ni ikọ naa tun koro oju si bi awọn ọlọpaa to n ṣọ ibode ipinlẹ naa ṣe n gba owo lọwọ awọn ọlọkọ ero latijẹ ki wọn wọ ipinlẹ Ondo.