Òyìnbó ẹni ọdún 46 wá ṣe mọ̀'mí n mọ̀ ọ́ ní Kano pẹ̀lú Isah olólùfẹ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Maude
Arabinrin ọmọ ilẹ Amẹrika kan Janine Sanchez to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ti wa sile awọn ololufẹ rẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Sulaiman Isah.
Oṣu bii mẹwaa sẹyin ni ololufẹ meji yii pade lori instagram ti arabinrin Sanchez si bẹrẹ sii yo ifẹ Sulaiman.
"O kọ ọrọ ranṣẹ si mi lori instagram pe "Ẹ n lẹ o.
Mi o kọkọ dahun tori mo ti ni iriri awọn ọmọ Naijiria to n gba eeyan lori ayelujara.
Ṣugbọn ọkunrin kan wa to n kọ ọrọ ranṣẹ si mi ti Sulaiman si mọ pe onigbajuẹ ni o si sọ fun un pe "lọ wa iṣẹ koo jawọ ninu gbigba awọn alaimọwọ mẹsẹ".
Tori naa mo wo o pe eniyan daadaa ni."
Ọgbẹni Musa ni oun ti maa n la ala ki oun fẹ oyinbo alawọ funfun gẹgẹ bi aya ki oun si jẹ baba awọn ti wọn ni ẹya meji.

Oríṣun àwòrán, Maude
"O jẹ ki ala mi wa si imuṣẹ nigba to da mi lohun lẹyin ti mo ki i. La ba bẹrẹ si ni ba ara wa sọrọ ti okun ibaṣepọ wa si n le sii".
Isah to jẹ mọ Minna ni ipinlẹ Niger gangan ni "mo ba ni ko wa bẹ mi wo ni Kano".
O dẹ ṣẹlẹ bẹẹ.
Arabinrin Sanchez to jẹ alase ni Lindon, California sọ pe oun yoo maa mu Ọgbẹni Isah pada lọ si ilẹ Amẹrika lẹyin igbeyawo wọn.
O sọ fun un pe oun ti ni ọmọ meji - ọkunrin kan, obinrin kan ninu igbeyawo rẹ tẹlẹ ṣugbọn oun ko ltọ lati gba awọn ọmọnaa tori adehun to wa laarin oun ati baba wọn.
Si eyi Ọgbẹni isah to n ṣiṣẹ irun gigẹ to si tun jẹ akẹkọọ ni ko si iṣoro pẹlu iyẹn. O ni oun yoo maa bẹ awọn obi oun ati mọlbi wo daadaa ati pe aranbinrin Sanchez ti gba pe awọn ọmọ awọn yoo maa wa si Naijiria wa bẹ awọn bi oun wo.
- Kéere o! Davido àti Chioma aya rẹ̀ ti d'ọ̀rẹ́ padà ní Instagram
- Ìlẹ̀kẹ̀ ìdí mi ló kó mi yọ lọ́wọ́ àwọn afipábánilòpọ̀ ní Lebanon
- Ẹgbẹ́ kan fún Tinubu ní wákàtí mẹ́rìnlélógún láti sọ èrò rẹ lórí Amọtẹkun
- Àwọn ọjọ́ ìsìnmi tó máa wà nínú ọdún 2020 ní Nàìjíríà
- 'A kẹ̀yìn sí Ivory Coast, owó yín ò lè máa jẹ́ "eco" táa ti mú fún àjọná owó ECOWAS'
Ni ti ogun ọdun to wa laarin wọn nkọ?
Awọn mejeji ni ko si iyọnu pe ẹnikan ju ẹnikeji lọ fiifii.
"Mi o woye pe mo ma fẹ ẹni to kere ju ọgbọ́n ọdun lọ ṣugbọn o gbọn ju ọjọ ori rẹ lọ. Bi mo ba n ba a sọrọ mo maa n ro pe ẹgbẹ mi ni". Arabinrin Sanchez sọ bẹẹ.
Iha ti idile Isah kọ
Inu idile Isah dun gidi gan si igbeyawo wọ́n to mbọ lọna tori wọn ni o ti fun awọn ni iyi lawujọ.
Gbogbo ẹbi rẹ naa lo fọwọ sii pe ki o fẹ Oyinbo alawọ funfun.















