Gabriel Boric: Adarí ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀ wọlé ìbò ààrẹ Chile lẹ́ni ọdún 35

Chile

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olori ẹgbẹ akẹkọọ tẹlẹ, Gabriel Boric ti wọlé ibo aarẹ orilẹede Chile lẹni ọdun marundinlogoji.

Oun ni ààrẹ ti ọjọ ori rẹ kere julọ ninu itan orilẹ ede Chile.

Alatako rẹ ninu eto idibo naa, José Antonio Kast gan an gba pe Boric la oun mọlẹ ninu eto idibo ọhun to waye lọjọ Aiku.

Antonio tiẹ sọ loju opo ayelujara rẹ pe oun ti pe Boric lati kì í ku oriire.

Ninu gbogbo ibo ti wọn di, Boric ko ida mẹrindinlọgọta nigba ti Kast ri ida mẹrinlelogoji.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

Lẹyin oniruuru ifehonuhan ni eto idibo naa to waye.

Lẹni ọdun marundinlogoji, Boric wa lara awọn aarẹ orilẹede ti ọjọ ori wọn kere julọ.

Nigba ti o n ba aarẹ ana orilẹ ede Chile, Sebastián Piñera sọrọ lori foonu laarin ọpọ eeyan, Boric ni oun yoo ṣa gbogbo ipa ati agbara oun lati ṣe ijọba to dara fun araalu.

Oriṣiiriṣii ayipada lo ti n ba orilẹ ede Chile lẹyin tawọn araalu dibo lọdun 2020 lati tun iwe ofin ilẹ naa kọ yato si eleyii ti wọn lo laye ijọba jẹgujẹra Aarẹ Pinochet.

Chile

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ta ni Gabriel Boric gan an?

Gabriel Boric jẹ olori awọn akẹkọọ to n fẹhonu han tẹlẹ ri.

Boric ṣatilẹyin fun iwọde lati tako iwa aidọgba lawujọ ati iwa ajebanu lorilẹ ede Chile lọdun 2019 sí 2020.

Lati ile ẹkọ girama ni Boric ti bẹrẹ ijajagbara, o si kẹkọọ nípa ìmọ ofin ni fasiti orilẹ ede Chile níbi tí wọn ti dibo yan an gẹgẹ bí olori ẹgbẹ awọn akẹkọọ.

Chile

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọdun ti wọn dibo yan an naa ni awọn akẹkọọ bẹrẹ si ni ṣe ifehonuhan pe owo ti ijọba n na lori ẹka eto ẹkọ tí kere ju.

Awọn iwọde yìí so eso rere torí ohun lo jẹ kí ijọba ṣe agbekalẹ awọn eto to mọyan lori ni ẹka eto ẹkọ lorilẹ ede Chile.

Lọdun 2013 ni wọn yan Boric sí ile aṣofin ni Magallanes.

Lati igba naa ni Boric ti bẹrẹ si ni to iwe rẹ diẹ diẹ to si bẹrẹ si ni maa ṣe ipade pọ pẹlu orisirisi oloṣelu.

Àkọlé fídíò, BBC News: Ifọrọwerọ pẹlu Sẹnẹtọ Olujimi

Chile ti ọrọ aje wọn dara ju tẹlẹ lapa gusu ilẹ Amẹrika ti wa di ibi ti iya ti n jẹ ọpọ eeyan bayii nigba ti ida kan ninu mẹrin eeyan to wa lorileede naa lo n ṣakoso ọrọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Ibadan Young Girl: Obi Demilade salaye iru iku to pa ọmọ wọn

Amọṣa, Boric ti ṣeleri lati wa nkan ṣe si aidọgba lawujọ ni Chile nipa ṣiṣe atunṣe eto fawọn to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ ati ẹka eto ilera.

Bakan naa lo ṣeleri pe lati ṣe adinku wakati t'awọn eeyan fi n ṣiṣẹ lọsẹ kan lati wakati marundinlogoji sí ogoji.