Ibadan Poly attack: Olùkọ̀ kan fara gbọta ìbọn lásìkò tí àwọn agbébọn ya bo ilé àwọn òṣìṣẹ́ Poly Ibadan

Poly Ibadan

Oríṣun àwòrán, Oyo affairs

Awọn agbebọn kan ti yabo ile awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ gbogboniṣe to wa niluu Ibadan, nibi ti olukọ kan ti ṣeṣe.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa ṣo fun awọn akọroyin pe olukọ kan ti ọpọ eeyan mọ si " Uncle O" fara gba ọta ibọn lasiko iṣẹlẹ naa.

O fi kun pe wọn tun ṣa okunrin naa ni ada lori, amọ o ti n gba itọju lọwọ nile iwosan kan ti ko darukọ.

Gẹgẹ bii ohun ti oṣojumikoro naa sọ, ọpọ awọn olugbe ile awọn oṣiṣẹ naa tun farapa yanayana nigba ti awọn agbebọn ọhun ko ọpọ dukia lọ.

Alukoro ile ẹkọ naa, Alhaji Soladoye Adewole ti fidi iroyin ọhun mulẹ fun awọn akọroyin niluu Ibadan.

Àkọlé fídíò, Ibadan Young Girl: Obi Demilade salaye iru iku to pa ọmọ wọn

Nigba to n dahun awọn ibeere kan lori ẹrọ tẹlifoonu, o ni ile ẹkọ ọhun ti gbe igbesẹ lati dẹkun irufẹ ikọlu bẹẹ lọjọ iwaju.

Adewole sọ pe "Lootọ ni, ọkan lara awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ wa ni okunrin naa... ọkan lara awọn to n ran awọn olukọ wa lọwọ ni."

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

"Ṣe ẹyuin naa mọ pe iwa ọdaran bayii maa n pọ si ni iru akoko yii."

"Ṣugbọn a ti tunbọ jawe sobi eto abo nile ẹkọ wa."

Ẹwẹ, niga ti akọroyin BBC Yoruba kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo lori iṣẹlẹ naa, o ni oun yoo fi atẹjade sita laipẹ.

Àkọlé fídíò, BBC News: Ifọrọwerọ pẹlu Sẹnẹtọ Olujimi