Àwọn agbébọn ti yìnbọn pa èèyàn 38 ní Kaduna

Oríṣun àwòrán, Ripples nigeria
O kere tan, eeyan mejidinlogoji ti jẹ Ọlọrun nipe lẹyin ti awọn agbebọn kọlu abule mẹta ni ipinlẹ Kaduna.
Awọn abule ti ọrọ naa kan wa ni ijọba ibilẹ Giwa, ni ipinlẹ ọhun.
Iroyin ni awọn agbebọn naa dana sun oniruru ọkọ ayọkẹlẹ ati ọkọ ajagbe, to fi mọ awọn ere oko labule Fawa, Marke ati Riheya.
- Wo ààrẹ orílẹ̀-èdè tó ṣiṣẹ́ awakọ̀ "taxi" kó tó di ààrẹ
- Àwọn olùjọ́sìn lu ọkùnrin kan pà nítorí pé ó wọ 'ibi mímọ́' jùlọ nínú ilé ìjọsin
- Tọkọ-taya dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tí wọ́n ta ọmọ wọn tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju oṣù kan lọ ní ₦50,000
- Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè gbẹ́sẹ̀lé ‘Container’ tó kún fún ìbọn nílùú Eko
- Àwọn ọlọ́pàá ti gbé tọkọtaya tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ọmọ oṣù mẹ́fà dí gbèsè tó fi kú
- Ó ti ṣe díẹ̀ tí mo ti ń gbé pẹ̀lú ìbànújẹ́, ayé ti sú mi - Ibrahim Chatta
- Àwọn ọlọ́pàá gbé òkú Sylvester Oromoni, akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College to ku l'Eko fún àwọn òbí rẹ̀ lẹ́yìn àyẹ̀wò 'Autopsy'
- Ìyàwó Timothy Adedoge ké gbàjarè lórí èsì àyẹ̀wò ikú tó pa ọkọ rẹ̀
- Ọkọ mi ti ń sọ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò pa ara òun, àmọ́ ẹbí kò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí - Ìyàwó ọkùnrin tó bẹ́ sí odò ọ̀sà
Iṣẹlẹ naa waye ni afẹmujọ ọjọ isinmi, ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii.
Ko sẹni to le sọ ni pato awọn to wa nidi ikọlu naa, amọ ipinlẹ Kaduna wa lara awọ ipinlẹ ti awọn agbebọn maa n dojukọ ju fun ipaniyan ati ijinigbe ni Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ti fi ogunlọgọ awọn ọmọ ogun ṣọwọ si ipinlẹ naa, sibẹ ikọlu awọn agbebọn atawọn janduku ko dinkun ni ipinlẹ ọhun.
Kọmiṣọna fun eto abo abẹle ni ipinlẹ naa, Samuel Aruwan, sọ ninu atẹjade kan pe ọrọ naa ti to gomina Nasir El-Rufai leti.
O ni gomina naa ti fi ọrọ ikẹdun ranṣẹ si ẹbi awọn ti ọrọ naa kan, o si n gbadura ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere.
Aruwan pari atẹjade naa pe awọn yoo fi orukọ awọn ti wọn ba iṣẹlẹ naa lọ lede laipẹ.
O fi kun pe awọn ẹṣọ alabo yoo tubọ tẹpẹlẹ mọ irinkerindo wọn lọna ati pese eto abo to peye ni ipinlẹ Kaduna.














