Tọkọ-taya tó ta ọmọ wọn ní ₦50,000 dèrò àtìmọ́lé l'Ogun

Couple Sells Their Baby For ₦50,000 In Ogun

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi ṣikun ofin mu tọkọ-taya kan lẹyin ti wọn ta ọmọ wọn ti ọjọ ori rẹ ko tii ju oṣu kan lọ ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira.

Eze Onyebuchi ati iyawo rẹ, Oluchi, ti wọn n gbe lagbegbe Ilara, ni Ode Remo, ni ipinlẹ naa ko sọwọ awọn agbofinro lẹyin iṣẹlẹ naa.

Ṣaaju ni ẹnikan ti kọkọ ke si awọn ọlọpaa pe tọkọ-taya ọhun ti ta ọmọ wọn.

Eyii lo mu ki ọga ọlọpaa agbegbe Ode Remo, Olayemi Fagbohun atawọn oṣiṣẹ rẹ ṣabẹwo sile tọkọ-taya naa, ti wọn si ko wọn lọ si agọ wọn.

Lasiko ti wọn n fi ọrọ wa wọn lẹnu wo ni agọ ọlọpaa, tọkọ-taya ọhun sọ pe arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ruth Obajimi lo so wọn pọ mọ ẹni ti wọn ta ọmọ naa fun.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀

Wọn ni obinrin naa wa sọdọ awọn, o si sọ pe ajafẹtọ ọmọniyan ni oun, ati pe oun yo ba wọn tọju ọmọ naa.

Lẹyin naa ni obinrin ọhun fun wọn ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira, ti awọn naa si gbe ọmọ wọn wọn le lọwọ lai mọ obinrin ọhun ri tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi lede, o ni obinrin ti wọn ta ọmọ naa fun ti na papa bora.

Oyeyemi fi kun pe awọn ti n sa ipa awọn lati ri daju pe wọn ṣawari obinrin naa, ki wọn si da ọmọ naa pada fun awọn obi rẹ.

Àkọlé fídíò, KieKie

Ẹwẹ, kọniṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti ni ki wọn tari tọkọ-taya naa si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe iwadii iwa ọdaran, CID.

Bankole tun paṣẹ pe ki wọn ṣawari obinrin to ra ọmọ naa ni kankan.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí o kò kàsí nípa mátírẹ́sì tí o ń sùn, ṣùgbọ́n tó ń ní ipa nínú ayé rẹ