6 months baby dies in Lagos: Ọmọ oṣù mẹ́fà tí ìròyìn sọ pé ọ̀gá ìyá rẹ̀ fi ipá gbà nítorí gbèsè nílùú Eko ti padà kú

Oríṣun àwòrán, The Punch
Ileṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti mu obinrin kan ati ọkọ rẹ, lori ẹsun pe wọn fi ipa gba ọmọ oṣu marun-un lọwọ ọmọ ọdọ wọn.
Eyi waye lẹyin ti iya ọmọde naa, Chinyere Nwafor to jẹ ẹni ọdun mejidinlogun sọ pe ọga oun gba ọmọ lọwọ oun nitori owo ti oun jẹ wọn.
Ọjọ Satide si ni awọn ọlọpaa ni agbegbe Ajah, mu tọkọtaya Tina ati Godwin Ogbonnaya, lẹyin ti fidio bi ebi ṣe sọ ọmọ naa di radarada, gba ori ayelujara.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan, Chinyere sọ pe lootọ ni oun gbe oyun wa silu Eko lati abule wọn nipinlẹ Abia. O ni ọkọ Arabinrin Tina lo mu oun wa si Eko pẹlu ileri pe yoo ran oun lọwọ.
"Amọ nigba ti mo de Eko, iyawo rẹ bẹrẹ si ni lo mi ni ilokulo, debi pe o ma n ran mi niṣẹ ni aarin oru. Mi o si fẹran iru nkan bẹẹ."
- Ọkọ mi ti ń sọ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò pa ara òun, àmọ́ ẹbí kò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí - Ìyàwó ọkùnrin tó bẹ́ sí odò ọ̀sà
- Àwọn ọlọ́pàá gbé òkú Sylvester Oromoni, akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College to ku l'Eko fún àwọn òbí rẹ̀ lẹ́yìn àyẹ̀wò 'Autopsy'
- Ó ti ṣe díẹ̀ tí mo ti ń gbé pẹ̀lú ìbànújẹ́, ayé ti sú mi - Ibrahim Chatta
- DSS fún mi ní omi kẹ́míkà mu látìmọ́lé, mi ò gbádùn láti ìgbà náà, wọ́n lù mú gan an- Lady K
O ni wọn fi ẹsun kan oun pe alori awọn agbero ni adugbo naa n ba oun ni ibalopọ.
"Lati igba naa ni wsn ti n sọ pe ma a kuro nile awọn. Mo si kuro.
"Alaafia ni mo fi ọmọ mi silẹ lọdọ wọn. Nigba ti mo pada wa pe mo fẹ ẹ gbe, wọn ni ki n san gbogbo owo ti awọn na le mi lori nileewosan pada."
"Igba ti mo pada wa ni mo ba ọmọ mi ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun."
A ko fi ipa gba ọmọ lọwọ rẹ
Tọkọtaya Ogbonnaya sọ fun awọn akọroyin ni agọ ọlọpaa pe awọn ko fi ipa gba ọmọ lọwọ Chinyere.
Ọkọ ni oun fi ọrọ to ileeṣẹ ọlọpaa leti nigba ti awọn fura pe o ti n ṣe iṣẹ aṣẹwo, ti DPO ibẹ si ni ki wọn o sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ba ti ko firi rẹ.
Ọgbẹni Ogbonnaya ni niṣe lo fi ọmọ tuntun naa silẹ si Eko, to ni oun lọ ṣe idanwo nipinlẹ Abia. "Ṣugbọn, irọ ni."
Arabinrin Tina sọ pe "ero wa ni pe yoo ma ba wa tọju ọmọ wa. Lootọ ni mo ri pe o loyun nigba ti a fẹẹ mu ni abule, ṣugbọn o bẹbẹ pe oun yoo tẹle wa, ki aṣiri oyun rẹ ma ba tu si ọwọ awọn abule.
"Ko mọ iṣẹ ile kankan ṣe. Awa la tun gba alagbatọ fun ọmọ rẹ, nigba to salọ. Asiko naa si ni ọmọ tuntun naa bẹrẹ aarẹ, to fi ri bo sẹ ri.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Adekunle Ajisebutu sọ fun BBC Pidgin pe awọn ti n ṣe iwadii iṣẹlẹ naa.
Ọmọ oṣù mẹ́fà tí ìròyìn sọ pé ọ̀gá ìyá rẹ̀ fi ipá gbà nítorí gbèsè nílùú Eko ti padà kú
Ọmọ oṣu mẹfa kan, Chidubem ti aworan rẹ jade sori ayelujara laipẹ yii, pẹlu iroyin pe ebi ti fẹ lu pa, ti pada ku.
Iya ọmọ naa to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun, Chinyere lo ke gbajare sita pe ki awọn ọmọ Naijiria dide fun iranlọwọ oun.
Ajafẹtọ ọmọniyan kan, Harrison Gwamnishu, ni Chinyere lọ ba, to si sọ fun pe ọga ti oun n ba ṣiṣẹ fi ipa gba ọmọ naa nitori gbese ti oun ko ri san fun.
O ni lasiko diẹ sẹyin, ọga oun ti wọn pe ni Madam Tina, ba oun san owo itọju nileewosan nigba ti oun wa ninu oyun, amọ o fi ipa gba ọmọ naa lọwọ oun nitori pe oun ko ri owo naa da pada.
"Oṣu kan gbako ni ọga mi fi gbe ọmọ mi sọdọ nitori mo jẹ lowo.
Lẹyin ti a fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa ati pẹlu iranlọwọ awọn ajafẹtọ, lo to o gbe ọmọ pada fun mi (to si ti fẹ ẹ kú)".
Aworan ọmọ naa ṣafihan rẹ lori ibusun nileewosan, to si jọ ẹni ti aarẹ n ṣe.

Oríṣun àwòrán, HARRISON GWAMNISHU
Botilẹ jẹ pe a ko mọ iru aarẹ to jẹ, ẹnikan lara awọn to n tọpinpin ẹjọ naa sọ pe awọn dokita ni ebi lo pa ọmọ naa.
Arabinrin Chinyere sọ pe ko si nkankan to sẹ ọmọ oun ki ọga oun to o fi ipá gba lọwọ oun nitori gbese. "Nigba ti mo gba ọmọ mi pada lo ti ri bayii."
Bakan naa ninu fidio naa ti ajafẹtọ Harrison Gwamnishu ti ba ọga Chinyere sọrọ, arabinrin naa sọ pe oun ti da ọmọ pada.
"Nkan ti mo fẹẹ sọ ni pe ki ẹ sọ fun Chinyere ko jẹ ka fi ẹnu ko lori bi yoo ṣe san gbese to jẹ mi.
- Ramon Adedoyin kò gbọdọ̀ kú sí àhámọ́ ọlọ́pàá o, àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ fohùn ránṣẹ́ s'ọ́gá ọlọ́pàá Nàìjíríà
- DSS fún mi ní omi kẹ́míkà mu látìmọ́lé, mi ò gbádùn láti ìgbà náà, wọ́n lù mú gan an- Lady K
- Amotekun fi ṣìkún òfin mú okùnrin tó jí àwọn olùjọ́sìn gbé lásìkò ìṣọ́ òru
- Wo bí wọ́n ṣe sin Ọba Satani pẹ̀lú ọkọ̀ àti orin tó fẹ́ràn jù
"Koda ti ko ba le san-an lẹkan, ma a gba diẹdiẹ."
O ni lootọ ni oun gba ọmọ naa, ti iya rẹ si jẹ oun lowo. Bakan naa lo sọ pe oun ni oun mu iya ọmọ naa, Chinyere wa silu Eko.
Gwamnishu sọ pe alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, ni ọmọ naa ku, lẹyin wakati diẹ ti ọrọ naa jade sori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, HARRISON GWAMNISHU
Ni bayii, Arakunrin Gwamnishu ni awọn yoo pada fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, pẹlu igbagbọ pe wọn o fi panpẹ ofin mu arabinrin naa.












