Ibrahim Chatta ké gbàjarè pé inú ìbànújẹ́ ni òun wà báyìí

Ibrahim Chatta

Oríṣun àwòrán, ibrahimchatta_lordthespis

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Ibrahim Chatta ti sọ pe aye ti su oun.

Chatta lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Instagram rẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti gbajumọ oṣere naa sọ, o ni o ti to nnkan bii ọjọ melokan ti oun ti gbe ninu ibanujẹ.

O ni "Ọlọrun jare, o ti ṣe diẹ ti mo ti n gbe pẹlu ibanujẹ ṣugbọn mo n dibọn bii pe gbogbo nnklan n lọ dede fun mi."

"Lọwọ yii, aye ti su mi, Ọlọrun jọọ, gba mi la."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ tiata lo ti bẹrẹ si n fi adura ranṣẹ si loju opo Instagram naa lẹyin to fi ọrọ naa lede tan.

Bakan naa ni ọpọ awọn ololufe rẹ mii ti n gba niyanju lati tu ninu.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí o kò kàsí nípa mátírẹ́sì tí o ń sùn, ṣùgbọ́n tó ń ní ipa nínú ayé rẹ

Bi awọn kan ṣe fi adura ranṣẹ ni awọn mii fi ọrọ iyanju sọwọ si, ti awọn mii pẹlu n sọ pe ki gbajunmọ oṣere naa ma mikan nitori ko si iṣoro ti Ọlọrun ko le yanju rẹ.

Wayi o, ọpọ awọn ololufẹ oṣere naa lo ti n woye eredi to ṣe fi irufẹ ọrọ bẹẹ sita lori ayelujara.

Ibrahim Chatta jẹ ọkan pataki lara awọn oṣere tiata Yoruba to dantọ ti ko si ipa ti ko le ko.

To ba jẹ ni ti ere ṣiṣe ni, Ibrahim Chatta le ṣe bii ọdọ langba, arugbo, babalawo, oniṣegun tabiu afaa.

Adura wa nip e ki Ọlọrun tu ninu, ko sib a yanju ohunkohun to ba n la kọja.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ eré bíi adití àti ojú táwọn olólùfẹ́ mi ma fi ń wò mí níta nìyìí - Madam No Network