Sex and the pandemic: Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe pá a mọ́ra ní ti ìbálòpọ̀ lásìkò ìséde?

Awọn ọdọ kaakiri agbaye n sọ iriri wọn nipa ibalopọ lasiko ti ajakalẹ arun Covid-19 bẹ silẹ lagbaye ti wọn si n s oniruuru ọna ti wọn gbe e gba lati mu ara wọn to n dide balẹ.
Awọn ọdọbinrin mẹta yii sọ bo ṣe ka wọn lara to tori wọn ko lanfan ati ba ololufẹ wọn lajọṣepọ. Kii ṣe pe ofin ma fara kan'ra wa lode amọ ofin isede kari gbogbo orilẹede agbaye to si jẹ pe ọdọ obi wọn lawọn obinrin yii ṣi n gbe.
Eyi jẹ jade latari iwadii nipa ihuwasi awọn eeyan si ibalopọ lati igba ti ajakalẹ arun Covid-19 ti bẹrẹ.

Ikọ aṣewadii kan, NatSal-Covid study beere lọwọ ọmọ ilẹ Britain to fẹrẹẹ to ẹgbẹrun meje ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mejidinlogun si mẹrinlelogun nipa igbe aye ibalopọ wọn ni oṣu mẹrin akọkọ ti ofin isede bẹrẹ.
Esi to jade fihan pe awọn ọdọ lo wọpọ ju ti yoo sọ pe awn ko fibẹẹ ri ibalopọ gbadun ti inu wọn ko si dun sii bi igba ti ko tii si ofin isede.
Omidan A: Ni temi, mi o ni ibalopọ fun ọdun kan nitori isede.
Omidan B: Ṣe ni gbogbo da bii pe o sare siwaju bii pe mo ti lo ogoji ọdun ninu igbeyawo.
O ni ṣe lo da bii pe inu igbeyawo ọlọjọ pipẹ loun wa lai til tii gbeyawo.
Omidan D: Emi lọ ra nkan iṣere ibalopọ ni o, nigba ti iya mi bi mi pe ki ni mo ra, mo ni ki wọn ma ṣeyọnu pe nkan itọju ara ni mo ra.

Iwadii naa fihan wipe ọpọ ninu wọn lo n ba ara wọn ṣere lati damira funrawọn (masturbation) lati fi ṣe itura lasiko ti ara wọn ba n dide fun ibalopọ ti ọpọlọpọ si lọ n ra nkan iṣere ibalopọ.
Layomi to jẹ sọrọ sọrọ lori oju opo asọrọmagbesi ni gbogbo asiko isede loun fi wa nile pẹlu awọn obi ohun ti ko si dẹrun fun oun rara.
Ẹni ogun ọdun ni Layomi to ni "mo kan rii pe iya n jẹ mi labẹlẹ, gbogbo igba ni baba mi n wa ni sakani mi ti mi o si le ṣe bo ṣe wu mi".
Lara iṣoro ti Hannah ẹni ọdun mọkalelogun to jẹ aladani oniroyin ori ayelujara ni oun koju ni adanikan wa. "Ko si nkan teeyan le ṣe bayii, ti ilẹ ba ti ṣu, mo ti maa ṣe ere idara lọ ti mo ba tun de, ki ni mo fẹ fi gbogbo alẹ ṣe. Maa kan ro o pe wo o, nkan iṣere bọ sibi".
O ni amọ nkan mii ti oun tun ro ni pe ko si mimọ eeyan tabi ifarakanra lati lee gbadun ara eeyan. Amọ o ni ibaraẹni sọrọ tun gbooro sii paapaa laarin awọn ọrẹ ti kii sọrọ tẹlẹ ti wọn n gba ara wọn nimọran nkan ti wọn lee lo.
Evie ẹni ọdun mẹtalelogun to jẹ olugbaninimọran nipa ibalopọ ṣalaye pe awọn mii to n fẹra wọn lasiko isede kan ṣee bii ifẹ aye atijọ ni ti awn si n ronu ọna ati ja oriṣiriṣi adun sii.
Ọjọgbn kan nipa imọ ẹk ilera ibalopọ tilẹ sọ pe ọna mii ti awọn miran n lo ni fifi ọrọ ibalopọ ranṣẹ si ra wọn eyi ti wọn in pe ni "sexting" tabi yiya fidio ihoho ara wọn fi ranṣẹ sira wọn.
Wọn ni o yẹ ki ijọba fi ọrọ ọna abayọ si nini ibalopọ sinu aato wọn nigba miran ti wọn ba n ṣe ofin isede ki awọn eeyan le ni iriri igbadun ibalopọ daadaa nipa fifi ara kan ara ki iya ibalopọ ma baa jẹ ẹnikẹni.















