Miss Nigeria 2021: Shatu Garko, di omidan àkọ́kọ́ tó ń lo hijab tí yóò gba adé Omidan tó rẹwà jùlọní Nàìjíríà

Shatu Garko

Oríṣun àwòrán, Miss Nigeria

Àkọlé àwòrán, Ọmọ dun mejidinlogun ni, ohun si ni ọjọ ori rẹ kere julọ alara awọn oludije to kopa ni aṣekagba idije naa

Shatu Garko, ọmọ ọdun mejidinlogun ti gbe igba oroke nibi idije omidan to rẹwa julọ lorilẹede Naijiria, eyi ti wọn n pe ni 'Miss Nigeria beauty pageant'.

Lalẹ ọjọ Ẹti nibi idije ẹlẹẹkẹrinlelogoji iru ẹ Miss Nigeria to waye nilu Eko, Garko fi ajulọ ẹwa han awọn omidan mẹtadinlogun miran.

Shatu Garko lati ẹkun iwọ oorun orilẹede Naijiria ni yoo si jẹ omidan akọkọ to n lo ibori Hijab ti yoo gba ade omidan to rẹwa ju ni Naijiria lati igba ti wọn ti bẹrẹ ami ẹyẹ naa. Nicole Ikot, ati Kasarachi Okoro ni wọn ṣe ipo keji ati ikẹta ni ṣisẹ n tẹle.

Gẹgẹbi ohun tawọn to ṣagbatẹru idije naa sọ, miliọnu mẹwaa naira, gbigbe ni ile olowo iyebiye kan fun ọdun kan, ọkọ ayọkẹlẹ tuntun kan pẹlu awọn ẹbun miran kun ara awọn ẹbun ti Garko yoo fi ṣe ifa jẹ.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí o kò kàsí nípa mátírẹ́sì tí o ń sùn, ṣùgbọ́n tó ń ní ipa nínú ayé rẹ

Ọmọbibi ilu Kano ni Shatu Garko.

Ọmọ ọdun mejidinlogun ni, oun si ni ọjọ ori rẹ kere julọ lara awọn oludije to kopa ni aṣekagba idije naa lọdun yii.