Nkechi Blessing: Ta ló kán gbajúmọ̀ òṣèré, Nkechi Blessing Sunday lẹ́sẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Nkechi blessing sunday/ instagram
Gbajumọ oṣere sinima ni, Nkechi Blessing ni oun ti kan lẹsẹ o.
Nkechi ni lasiko ti oun lọ woran awodamiẹnu nibi ijo gbajumọ olorin agbaye, Wizkid ti wọn ṣe ni gbagede ileetura transcorp Hilton hotel nilu Abuja lẹsẹ oun fi kan o.
- Ọkọ mi ti ń sọ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò pa ara òun, àmọ́ ẹbí kò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí - Ìyàwó ọkùnrin tó bẹ́ sí odò ọ̀sà
- Ọ̀kùnrin to tú àṣírí ohùn Olóyè Sunday Igboho lórí fóònù ti bọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
- Ta ni Ọba Sátánì tó fẹ́ ìyàwó 57 kó tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 74?
- Ṣé lóòtọ́ ni ọlọ́pàá Osun fẹ́ fi panpẹ́ mú ọmọ Adedoyin tó ni Hòtẹ́ẹ̀lì tí Timothy Adegoke kú sí? Ọ̀rọ̀ ń rùn bọ̀ o
- 'Lójú mi, ọmọ ìyá mẹ́fà jóná, ọkàn kú nínú iná gàásì nílùú Abuja'
- Arákùnrin kan r'ẹ́wọ̀n ọdún 24 he lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ pẹlú ọmọ ìkókó
Ilumọọka oṣere naa ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye loju opo Instagram rẹ pẹlu fido bo ṣe ṣẹlẹ gan.
Gẹgẹbi alaye to ṣe, Nkechi ni ọkan lara awọn ololufẹ Wizkid to wa wo ere naa lo ṣa dede fo soke sori itage ti gbajumọ olorin naa ti nkọrin to si dii lẹsẹ mu daindain.

Oríṣun àwòrán, Screenshot/ nkechi blessing sunday/ instagram
Nibi ti awọn ẹṣọ onigẹ ara ti wọn n pe ni bouncers ti gbe arakunrin naa ti wọn si wọn ọ danu bii eeran ara igi. Ọgangan ibi ti Nkechi Blessing joko si ni wọn wọn arakunrin naa danu si ni nkechi ba ṣubu yakata o.
"Ta lo ran mi niṣẹ o? Ki lẹṣẹ mi o? Ere ti pari ṣugbọn ẹsẹ mi ti kan."









