Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè gbẹ́sẹ̀lé ‘Container’ tó kún fún ìbọn nílùú Eko

Customs intercept container laden with guns

Oríṣun àwòrán, Anambra specials

Ileeṣẹ aṣobode Naijiria ti gbẹsẹle ile ẹru kan ti wọn ba ibọn atawọn ohun ija oloro mii ninu rẹ lagbegbe Tin Can Island, niluu Eko.

Wọn ṣawari ile ẹru ọhun lasiko ti wọn n ṣe ọkan lara awọn ayẹwo ti wọn maa n ṣe nileeṣẹ naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ aṣobode ni Tin Can Island, Uche Ejesieme lo fidi ọrọ naa mulẹ fun awọn akọroyin.

O ni awọn ṣawari ile ẹru ọhun lasiko ọkan lara awọn ayẹwo ti wọn maa ṣe.

"Lẹyin ti a ṣawari rẹ ni ni a paṣẹ ki wọn gbe ile ẹru naa lọ si ọọfisi wa fun ayẹwo ni kikun ati iwadii to peye."

O fi kun pe ọpọ ohun ni awọn ko tii mọ nipa bi ile ẹru naa ṣe jẹ ṣugbọn awọn ko ni fi ohunkohun pamọ fun awọn akọroyin lori iwadii awọn.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí o kò kàsí nípa mátírẹ́sì tí o ń sùn, ṣùgbọ́n tó ń ní ipa nínú ayé rẹ

Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ti ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, Usman Baba ke si awọn agbofinro lati jawe sobi iṣẹ wọn ni imurasilẹ ọdun 2022 to n bọ lọna.

Usman Baba sọ pe ọdun to ni apẹrẹ ni ọdun 2022 yoo jẹ nitori ọdun naa ni yoo ṣaaju ọdun 2023 ti eto idibi Aarẹ yoo waye.

Ẹwẹ, iroyin ni ẹni to ni ile eru naa ti kọkọ sọ ṣaaju pe ẹrọ tẹlifiṣọn agbelewo lo wa ninu rẹ ki akara to tu sepo.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'