Àwọn olùjọ́sìn lu ọkùnrin kan pà nítorí pé ó wọ 'ibi mímọ́' jùlọ nínú ilé ìjọsin

Tẹmpili yii ti wọn fi wura kọ, ni ibi mimọ awọn ẹlẹsin Sikhism

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Tẹmpili yii ti wọn fi wura kọ, ni ibi mimọ awọn ẹlẹsin Sikhism

Awọn ọlọpaa ni India ti kede pe awọn eeyan lu ọkunrin kan pa nitori pe o fẹ ẹ ba ojubọ oriṣa jẹ.

Iroyin sọ pe ọkunrin naa lo fi agidi wọ ibi mimọ julọ ni gbọngan tẹmpili 'Golden Temple' nilu Amritsar, lọjọ Satide.

Iṣẹlẹ naa waye lasiko ti isin adura n lọ lọwọ.

Ibi mimọ julọ ti ọkunrin naa gbiyanju lati wọ ni wọn gbe iwe mimọ Guru Granth Sahib si.

Ni kete to wọ ibẹ lo gbiyanju lati fi ọwọ kan idà iṣẹmbaye kan ti wọn gbe si ẹgbẹ iwe naa, amọ awọn ẹṣọ ati awọn olujọsin kapa rẹ.

Gbangba ni awọn eeyan ri bi iṣẹlẹ naa ṣe n waye nitori wọn n ṣafihan eto isin adura alẹ naa lori ẹrọ amohunmaworan.

Botilẹ jẹ pe a ko le sọ nkan to ṣẹlẹ lẹyin naa, awọn ọlọpaa sọ pe ọkunrin naa ti ku nigba ti awọn yoo fi de ibi iṣẹlẹ ọhun.

Wọn ni iwadii ti bẹrẹ.

Bayii ni awọn ajafẹtọ ṣe pejọ si ọfiisi igbimọ to n dari ilẹ mimọ naa lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bayii ni awọn ajafẹtọ ṣe pejọ si ọfiisi igbimọ to n dari ilẹ mimọ naa lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ọjọ diẹ ti ọwọ tẹ ọkunrin kan ti wọn fi ẹsun kan pe o ju iwe mimọ kekere Sikh, Gutka Sahib, sinu òdò to yi tẹmpili naa ka.

Ṣiṣe nkan ẹgbin si Guru Granth Sahib jẹ nkan to ma n fa ibinu laarin awọn to n sin.

Ọpọ igba ni iwa ẹgbin waye ni ọdun 2014 si 2015, to si di ija oṣelu ni Pujab lọdun 2017 ati 2019.

Awọn ẹlẹsin Sikh ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako si ma n na ika aleebu si ẹgbẹ to pọju nile aṣofin pe wsn kuna lati fi iya jẹ awọn to n hu iwa ẹgbin si tẹmpili awọn.