Tortured to death: Ilẹeṣẹ́ ìròyìn BBC tú àsírí bí àwọn ọmọ ogun Myanmar ṣe pa àwọn aráàlú

Two people digging

Iwadii ileeṣẹ iroyin BBC kan ti fi han pe ileeṣẹ ọmọ ogun orilẹ-ede Myanmar ti ṣekupa eeyan ti ko din ni ogoji lọna aitọ.

Awọn oṣojumikoro kan ṣalaye fun BBC pe awọn ọmọ ogun naa, ti ọjọ ori awọn mii lara wọn ko ju ọdun mẹtadinlogun lọ, ya bo abule awọn, wọn ya awọn okunrin sọtọ, wọn si ṣina ibọn fun awọn okunrin naa.

Oniruru fidio ati aworan lati orilẹ-ede naa fi han pe wọn kọkọ fi iya jẹ awọn eeyan naa lọna aitọ ki wọn to pa wọn.

Iṣẹlẹ naa waye ninu oṣu Keje ọdun yii nigba mẹrin ọtọtọ niluu Kani, to wa lagbegbe Sagaing.

Igbagbọ wa pe awọn ọmọ ogun ọhun ṣe ikọlu naa lati gbẹsan bi awọn ẹgbẹ alatako ṣe maa n kọju ija si wọn lọna ati da ijọba alagbada pada silẹ ọhun.

Ṣaaju ni awọn ọmọ ogun naa ti kọkọ ditẹ-gbajọba lẹyin ti wọn le Aarẹ Aung San Suu Kyi kuro lori oye, ṣugbọn gbogbo igba ni awọn araalu n tako wọn.

Ileeṣẹ iroyin BBC ba oṣojumikoro mọkanla sọrọ ni Kani, a si ṣe afiwe ọrọ ti wọn sọ papọ mọ awọn fidio ti o tẹ wa lọwọ, to fi mọ awọn aworan kan naa.

Kani map

Ibi ti wọn ti pa eeyan to pọ ju ni abule Yin nibi ti wọn ti lu okunrin mẹrinla titi ti ẹmi fi bọ lẹnu wọn, ti wọn si ju oku awọn eeyan naa sinu igbo.

Oṣomikoro kan labule Yin yii sọ fun BBC pe awọn ologun fi okun so ọwọ awọn eeyan mọ ẹyin wọn, ti wọn si lu wọn nilu bara ki wọn ṣeku pa wọn.

Ẹnikan ti ori ko yọ ninu ifẹmiṣofo ọhun sọ pe wọn sọ awọn mii lara wọn lokuta pa.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

Niluu Zee Bin Dwin, awọn eeyan ri oku mejila ninu iboji kan ni ipari oṣu Keje, lara awọn eeyan naa ni abarapa kan ati ọmọ kekere wa.

Wọn tun ṣawari oku okunrin kan ti wọn so mọ igi, ileeṣẹ iroyin BBC si fidi rẹ mulẹ lẹyin ayẹwo fidio oku okunrin naa pe wọn ti kọkọ lu nilu bara ki wọn gbẹmi rẹ.

Ẹwẹ, awọn mọlẹbi awọn eeyan ti wọn paa naa ti sọ pe awọn eeyan awọn ko si lara awọn to n kọju ija si awọn ọmọ ogun.

Àkọlé fídíò, BBC News: Ifọrọwerọ pẹlu Sẹnẹtọ Olujimi

Obinrin kan ti wọn pa ẹgbọn rẹ labule Yin sọ pe oun bẹ awọn ọmọ ogun ọhun ki wọn da aburo oun si nitori ko le pa era lasan anbelete lati pa ọmọ ogun, ṣugbọn wọn kọti ikun si oun.

Lọwọ yii, ajọ iṣọkan agbaye, UN, ti n ṣe iwadii iwa ifiyajẹni lọna aitọ ti awọn ọmọ ogun orilẹ-ede Myanmar wu.