Sotitobire: Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dá olùkọ́ èwe ṣọ́ọ̀ṣì Sotitobire, Magaret Oyebola sílẹ̀

Woli Alfa atawọn oṣiṣẹ ij rẹ nile ẹjọ

Ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa nilu Akurẹ ti wọgile idajọ ẹwọn gbere ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo gbe le arabinrin Magaret Oyebọla, olori awọn ṣọọsi ọmọde nile ijọsin Sotitobirẹ Praising Chapel nilu Akurẹ.

Adajo Oluṣẹgun Oduṣọla ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo ran Oyebọla, Wolii Babatunde Alfa atawọn miran lọ si ẹwọn gbere fun ẹsun jiji ọmọdekunrin Gold Kọlawọle gbe ni ijọ naa losu kọkanla ọdun 2019.

Ninu idajọ rẹ eyi ti onidajọ, James Gambo Abundaga sọ pe awijare ti ile ẹjọ giga gbe idajọ rẹ le lori ko fidi mulẹ to lati fihan pe wọn ji ọmọ naa gbe ni.

Bakan naa lo ni igbẹjọ naa ti ṣe yajoyajo jubii ina alẹ niwọn igba ti iwadii ṣi n lọ lọwọ ti gbogbo rẹ si n fihan pe ẹri ti wọn n gbe kalẹ ko rinlẹ to, bẹẹsi ni ko si idi fun riran wọn lẹwọn laisi ẹri to daju.

Àkọlé fídíò, Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

Agbẹjọro fun olupẹjọ naa, Ọladele Oke dupẹ lọwọ ile ẹjọ naa fun itusilẹ arabinrin Oyebọla, ṣugbọn adari ẹka ipenilẹjọ nijọba ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Leonard Ologun ṣalaye pe ijọba yoo gbe idajọ naa yẹwo lati gbe igbesẹ to ba kan.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

Oyebọla ni ẹnikeji ti yoo gba itusilẹ lara awọn olukọ ile ijọsin awọn ọmọdemarun un ni ṣọọṣi Sọtitobirẹ ti wọn ran lọ si ẹwọn gbere loṣu kẹwaa ọdun 2020.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti kọkọ tu Motunrayọ Egunjọbi silẹ ninu idajọ rẹ ni ọjọ kini oṣu kejila ọdun 2021.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yóò dájọ́ olùkọ́ èwe ṣọ́ọ̀ṣì Sotitobire lónìí

Loni ni idajọ olukọ agba ileejọsin awọn ọmọde ni ṣọọsi Sọtitobirẹ yoo waye.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni ọdun 2020 ni ile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Ondo da ẹjọ ẹwọn gbere fun Oludasilẹ ijọ naa, Wolii Alfa Babatunde lori ọmọdekunrin, Gold Kọlawọle to sọnu ninu ijọ naa.

ArabinrinMagareth Oyebọla ni adari ẹka awn ọmọde ni ileejọsin Sọtitobirẹ Praising Chapel nilu Akurẹ.

O wa lara awọn ti wọn da ẹjọ ẹwọn gbere fun pẹlu adari ijọ naa.

Oun pẹlu tọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ lati wọgile idajọ naa eleyi ti idaj yoo waye le lori loni.