Dowen College: Àwọn mọ̀lẹ́bí Sylvester Oromoni bẹ Femi Falana lọ́wẹ̀ lórí ikú ọmọ wọn

Sylvester Oromoni ati kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, PERRIE/TWITTER

Ọmọ ile ẹkọ Dowen College to wa ni agbegbe Lekki nipinlẹ Eko, ti wa ni akata ileeṣẹ ọlọpaa lori iku akẹkọọ kan, Sylvester Oromoni to ku laipẹ yii.

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu lo sọ ọrọ yii, gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Channels Television sẹ sọ.

Odumosu sọ pe mẹta lara awọn akẹkọọ marun-un ti Sylvester darukọ wọn ko to o ku, ti wa ni akata ọlọpaa bayii, ti wọn si n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii iku ọmọ naa.

Botilẹ jẹ pe Ọgbẹni Odumosu ko darukọ awọn akẹkọọ mẹta naa, o ni gboogi ni wọn lara awọn afurasi.

Bakan naa lo sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti ṣetan lati lọ sibi ti wọn ti fẹ ẹ ṣe ayẹwo oku akẹkọọ naa nipinlẹ Delta, lati le mọ koko nkan to ṣe okunfa iku rẹ.

Àwọn mọ̀lẹ́bí Sylvester Oromoni bẹ Femi Falana lọ́wẹ̀ láti pe Dowen College lẹ́jọ́

Awọn mọlẹbi akẹkọọ Dowen College to ku nilu Eko, Sylvester Oromoni, ti bẹ agbẹjọro agba, Femi Falana lọwẹ lati ba awọn gbe ile ẹkọ naa lọ sile ẹjọ lori iku to pa ọmọ wọn.

Falana ti wa kọ lẹta si ọọfisi ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to n ṣe iwadii iku ọmọ naa lọna ati tuṣu de isalẹ ikoko ọrọ ọhun.

Lẹte naa, ti akọle rẹ n jẹ "Ibere fun iwadii lori iku to pa Sylvester oromoni ni Dowen College, Lekki" ṣalaye pe, lori ọrọ ti awọn mọlẹbi oloogbe sọ, ọmọ wọn jade laye lẹyin ti awọn 'senior' rẹ nile ẹkọ da seria fun.

Taiwo Olawale lo buwọlu lẹta naa ti wọn fi ṣọwọ si olori ikọ oluwadii iku naa.

Lẹta naa ni "Lẹyin iku aitọjọ Sylvester Oronmoni, o ti di dandan fun wa lati ṣe iwadii ohun to pa akẹkọọ naa."

Àkọlé fídíò, Mama Deeper Life Ondo

"Igbeṣe yii ṣe pataki ki a le mọ igbesẹ to kan gẹgẹ bii agbekalẹ ofin ipinlẹ Eko, ni abala karundinlogun, eyii ti wọn gbe kalẹ lọdun 2007 ṣe sọ."

"Ofin sọ pe iwadii gbọdọ waye ti iku ọhun ba waye nipasẹ ipa tabi ti ejo ba lọwọ ninu ori iku ọhun."

Àkọlé fídíò, A kò tíì dẹ́kun àdúrà pé kí àṣírí àwọn tó jí ọmọ gbé tú - Bisola Alfa Sotitobire

Femi Falana jẹ ọkan gboogi lara awọn agbẹjọro to dantọ ni Naijiria ati loke okun, o tun ajijagbara ati ajafẹtọ ọmọniyan.

Ẹwẹ, Sylvester Oromoni ku lẹyin ti iroyin ni awọn 'senior'rẹ da seria fun nile ẹkọ Dowen College to wa ni Lekki, niluu Eko.

Amọ awọn alaṣẹ ile ekọ naa ti sọ pe iro pata ni iroyin naa, ati pe ṣe ni ọloogbe ọhun ṣẹṣe lasiko to n ga bọọlu alafẹsẹgba pẹlu awọn akẹgbẹ.

Àkọlé fídíò, Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Mí ò ní sin òkú ọmọ mi títí yóò fi rí ìdájọ́ òdodo gbà- Baba Sylvester

Baba Sylvester to jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Dowen College ni Lekki ni ìpínlẹ̀ Eko ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òhun ko ní sin òkú ọmọ ohun títí wọn yóò fi rí ìdájọ òdodo gbà.

Mí o ni sin òkú ọmọ mi títí yóò fi ri ìdájọ́ òdodo gbà

Ó sọ èyí lásìkò ayẹyẹ ọjọ ibi ọmọ naa, eyi ti wọn ṣe lati ṣẹyẹ ọdun mejila ti o yẹ ki o se ki o to ku.

Akara oyinbo ti wọn fi asọ awakọ ofurufu ati ọkọ ofururu ni wọn se fun lati ṣẹyẹ iṣẹ tí o wu lati ṣe lọjọ iwaju han ati lati se iranti

Ọjọru ọsẹ to kọja ni okiki kan pe ọmọ naa ku ti ariwo rẹ si gba ori ayelujara kan lasiko ti ẹbi rẹ kan Perry Oromoni kede pe awọn ọmọ ile iwe rẹ ti o fẹ fi ipa mu wọ inu ẹgbẹ okunkun lo luu ni yara rẹ ni ile ẹkọ.

Ninu ọrọ rẹ pẹlu Baba Sylvester ni ọmọ oun darukọ awọn ọmọ Marun to se isẹ ibi naa, ọwọ si gbọdọ tẹ awọn ọmọ ọhun

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀

Bakan naa lo ni awọn olukọ, ọlọdẹ ati awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa ni yoo ṣalaye iku to pa ọmọ oun.

Ẹwẹ ile ẹkọ naa ni ko si nnkan to jọ pe awọn akẹkọọ ko luu ati pe oun ba awọn akẹgbẹ rẹ gba bọọlu ni wọn ni lẹyin ti o gba bọọlu tan ni o n kerora pe ẹsẹ ati itan n dun oun eyi ti awọn funra si pe o fi nibi bọọlu.

Ifeanyi Okowa

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ifeanyi Okowa

Ẹwẹ, o le ni eniyan ẹgbẹrun lọna ọgọrun to ti buwọluwe lori ayelujara lati pe fun idajó ododo ati oni kiakia fun Sylvester Oromoni bayii.

Iwe ẹsun naa ti ile isẹ kan Change.org gbe jade lati bere fun idajọ ni kiakia lati ọdọ ijọba ti wọn si pe akọle rẹ ni "Justice for Sylvester Oromoni Jr" tiri ibuwọlu ọpọ eniyan lori ayelujara to fẹ to ẹgbẹrun lọna ọgọrun lọsan ọjọ Aiku.

Àkọlé fídíò, Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...

Bakan naa ni ẹgbẹ Irede Foundation naa ti fi ipe sita lati gba idajọ ododo fun ọmọ ti wọn da ẹmi rẹ legbedo yii.

Wọn kepe kọmisọnna ile isẹ to n ri si eto ékọ ni ipinlẹ Eko, Folashade Adefisayo ati awọn ọga ajọ SUBEB to fi mọ ile iṣẹ to n ri si eto ẹkọ ni ipele ijọba apapọ lati sẹ iwadii ijnlẹ lori iwa ifiyanjẹni laarin akẹkọọ lawọn ile iwe girama.

Ijọba ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki wọn gbe ile iwe naa ti pa titi iwadii iku to pa Sylvester yoo se di mimọ.

Àkọlé fídíò, Afeez Akintunde: Àwọn ẹbí Tula Oyo figbe tá pé kò ní ohunkohun ṣe pẹ̀lú Yoruba Nation

Lórí ọ̀rọ̀ Sylvester Oromoni, a kò ní dáké títí ìdájọ́ òtító yóò fi jọba - Gómínà Ifeanyi Okowa

Gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa ti kede pe ijọba oun ti bẹrẹ igbesẹ lati ri pe idajọ otitọ jọba lori iṣẹlẹ to jasi iku Sylvester Oromoni.

Àkọlé fídíò, Baba Suwe: Aya àkọ́fẹ́ olóògbé ṣàlàyé bí àkókó ìkẹyìn ọkọ́ rẹ̀ ṣe rí

Sylvester Oromoni to jẹ akẹkọọ ileewe Dowen College lo fẹsun kan awọn ''senior'' rẹ pe wọn na oun nitori oun ko darapọ mọ ẹgbẹ okunkun wọn.

Awọn obi rẹ ni iya ti wọn fi jẹ ọmọ naa lo ja si iku rẹ, amọ ileẹkọ Dowen College ninu atẹjade ti wọn fi lede ni asiko ti ọmọ naa n gba bọọlu lo ṣubu to si fi ara pa, eleyii to jasi iku rẹ.

Ninu atẹjade loju opo Facebook rẹ, Gomina Ifeanyi ni o ṣeni laanu pe Sylvester ku lori iṣẹlẹ ti ko si aridaju lori rẹ ati awọn ẹsun to ba ni lẹru gidigidi.

Gomina naa ni lasiko ti oun pe baba Sylvester ni oun fi to leti pe oun faramọ igbeṣẹ gomina ipinlẹ Eko ti wọn bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ iku Sylvester naa to wa lati agbegbe ijọba ibilẹ Warri South, ni ipinlẹ Delta.

Ihe Ifeanyi Okowa

Oríṣun àwòrán, Facebook screengrab

Gẹgẹ bi gomina to gbe ọrọ awọn araalu le ọkan, awọn yoo ri pe iṣẹlẹ yii jasi idajọ ti yoo fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

''Amọ bi a ṣe n reti abajade iṣẹlẹ naa ni a gbadura pe ki Ọlọrun tu awọn mọlẹbi Omoroni ninu lasiko iṣoro yii.

Lara awọn to tun sọrọ lori iṣẹlẹ naa ni igbakeji aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Atiku Abubakar ati ṣẹnetọ Ben Murray Bruce to fi igba kan ṣoju gbungun ipinlẹ Bayelsa laaarin ọpọ awọn ẹlomiran.

Ninu ọrọ tirẹ, Atiku ni iwadii gbọdọ bẹrẹ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa lai si magomago ki idajọ ododo le jọba lori iṣẹlẹ naa.

Atiku

Oríṣun àwòrán, Facebook screengrab

Bakan naa ni Ben Murray Bruce ni awọn fẹ mọ otitọ lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si ma fi ọwọ bo iṣẹlẹ ọhun.

Ben Bruce

Oríṣun àwòrán, Facebook screen grab

A kò gbọ́ ǹkankan nípa ikú Sylvester Oromoni- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn obi Sylvester Oromoni to di oloogbe nile ẹkọ Dowen College niluu Eko, tabi ẹbi rẹ kankan ko fi ọrọ naa to awọn leti.

Sylvester Oromoni

Oríṣun àwòrán, Perreri/Twitter

Agbenusọ ileeṣẹ ọhun, Adekunle Ajisebutu lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Ninu atẹjade ọhun lo ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadi lori iku ọmọ naa, iwadii si ti n lọ lọwọ.

O ni "Ileeṣẹ wa fẹ fi to awọn araalu leti pe bo tilẹ jẹ pe ẹnikẹni ko fi ọrọ iku akẹkọọ naa lọ ileeṣẹ wa, kọmiṣọnna ọlọpaa ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori ohun to ṣokunfa iku rẹ."

"Kọmiṣọnna ti ke si ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Makoko, lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lati yọju sile ẹkọ naa lati bẹrẹ iwadii."

"Ẹwẹ, nitori bi ọrọ naa ṣe lagbara to, a tun ti kan si ẹka ileeṣẹ wa to n ri si ọrọ ipaniyan lati gba akoso iwadii ọhun lẹsẹkẹsẹ."

Àkọlé fídíò, Murphy Afolabi: Kò dùn mí tí wọn bá ṣe yẹ̀yẹ́ mi torí mò fi sí pe ṣí, èdè Osogbo ìlú mi ni

Ajisebutu tẹsiwaju pẹlu ileri pe awọn yoo ṣe iwadii to munadoko, awọn yoo si tuṣu de isalẹ ikoko bi ọrọ naa ṣe jẹ.

Lẹyin naa lo ke si awọn araalu lati fun awọn ọlọpaa laye lati ṣiṣẹ wọn bo ṣe yẹ laisi si idiwọ kankan, ki wọn ma si da ofin ṣe lọwọ ara wọn.

O pari atẹjade naa pe kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ko ni fi abajade iwadii naa pamọ, gbogbo aye ni yoo si mọ ohun ti awọn ba ṣawari lẹyin iwadii ọhun.

Ọgbọn ọjọ, oṣu Kọkanla ni iroyin iku oloogbe naa jade lori ayelujara lẹyin ti ẹnikan to n jẹ @perrisonoromoni loju opo Twitter ke gbajare pe awọn akẹgbẹ rẹ lo ṣekupa lẹyin to kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.

Àkọlé fídíò, Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...

Amọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ti fesi ninu atẹjade kan pe irọ ni pe awọn Sylvester lo ṣokunfa iku rẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti ile ẹkọ naa sọ, asiko to lọ gba bọọlu alafẹsẹgba lo ṣeṣe.

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ Adedoyin jẹ́wọ́ fún wa pé àwọn pa àbúrò mi, ọ̀gá Adedoyin sì mọ̀ síi - Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke