Sanwo-Olu peace walk: MURIC képe àwọn ọ̀dò àti krìstẹ́nì láti kópa nínú ìrìn àlàáfíà l'Eko

Muric Akintola

Oríṣun àwòrán, @MURIC

Àkọlé àwòrán, Ishaq Akintola

A ṣetán láti bá Sanwo-Olu rìnrìn àlàáfíà, ẹ̀yin krìstẹ́nì, ẹ darapọ̀ mọ wa- MURIC

MURIC sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ eyi ti alakoso ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Ishaq Akintola buwọ lu.

Ẹwẹ, awọn ajafẹtọ ọmọniyan bii Mr Macaroni, Falz, Seun Kuti , Dele Farotimi at'awọn mii ti Sanwo-Olu pe lati ba a rin irin alaafia yii ni wọn ti sọ fun gomina pe awọn ko ni kopa ninu irin naa.

Eleyi ṣẹlẹ lẹyìn tí Sanwo-Olu gbe abọ iwadii igbimọ to ṣe itọpinpin gbogbo ohun to ṣẹlẹ lasiko iwọde EndSARS niluu Eko to fi mọ iṣẹlẹ isekupani to waye ni Lekki toll gate.

Àkọlé fídíò, Ilé tẹ́ẹ rò pé ìjọba Eko fún wa, wọ́n rẹ́ǹtì rẹ̀ ni, a kò tíì rí N1Miliọ̀nù kankan di àsìkò yìí - Iya Jumoke

Amọ, MURIC ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe okoo le ni irinwo miliọnu naira ni Sanwo-Olu ti san gẹgẹ bi owo gba mabinu fáwọn ẹbi awọn eeyan ti ọlọpaa ti sekupa tabi awọn ti wọn ti ṣe leṣee.

Àkọlé fídíò, A kò tíì dẹ́kun àdúrà pé kí àṣírí àwọn tó jí ọmọ gbé tú - Bisola Alfa Sotitobire

MURIC ṣalaye pe o yẹ ki onikaluku fọwọ so ọwọ pọ pẹlu Sanwo-Olu lati rinrin alaafia pẹlu rẹ nibi ti ọrọ de duro bayii.

Ẹgbẹ naa ni rogbodiyan ti to gẹ nipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀

MURIC wa rọ gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Eko lati darapọ mọ gomina wọn ti asiko irin naa ba ti to.

Ẹgbẹ MURIC fikun ọrọ rẹ pe awọn olori ẹsin ko gbọdọ wa nibi t'awọn eeyan ti da wahala sile.

Àkọlé fídíò, Davido yàtọ̀ s'àwọn ọ̀dọ́ olórin kan tó lè yẹ̀yẹ́ àgbà olórin, òun ló kọ́kọ́ ná mi ní béèlì N1M lágbo - Yinka Ayefele

Wọn ní nibi atunṣe lo yẹ ki awọn olori ẹsin maa wa.

MURIC wa rọ awọn ọmọ lẹyin Kristi at'awọn ọdọ naa wi pe ki wọn darapọ mọ Sanwo-Olu ninu irin alaafia to fẹ rin.

Àkọlé fídíò, Murphy Afolabi: Kò dùn mí tí wọn bá ṣe yẹ̀yẹ́ mi torí mò fi sí pe ṣí, èdè Osogbo ìlú mi ni

MURIC ni nipa didarapọ mọ gomina nibi irin alaafia ni o fi le fi ẹsẹ awọn eeyan ipinlẹ Eko le ọna alaafia.

MURIC ṣe apejuwe Sanwo-Olu gẹgẹ bi gomina to n ṣiṣẹ takuntakun ki awọn araalu le jẹ anfaani ijọba.