Dowen College student death: Atiku, Burna Boy, Adesua Etomi-Wellington àtàwọn èèyàn míì sọ̀rọ̀ lórí ikú Sylvester Onoromi

Dowen College

Oríṣun àwòrán, Twitter/Perrie

Lẹyin iku Sylvester Onoromi , to jẹ akẹkọọ Dowen College to ku niluu Eko, awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori iku rẹ.

Iroyin ni awọn akẹgbẹ Sylvester Onoromi lo ṣekupa lẹyin to kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun, awọn ọlọpaa si ti bẹrẹ iwadii.

Ṣugbọn ile ẹkọ naa ti sọ ninu atẹjade kan pe irọ ni iroyin naa, ati pe ṣe ni akẹkọọ ọhun ṣubu lasiko to n gba bọọlu alafẹsẹgba.

Iṣẹlẹ naa ka awọn ọmọ Naijiria lara to bẹẹ ti oju opo Twitter fi n gbona giri, awọn eeyan si ti n ṣe ifẹhonuhan alalaafia lori Twitter pẹlu #Justiceforsylvester.

Ohun ti awọn ọmọ Naijiria n sọ lori iṣẹlẹ naa ree:

Atiku Abubakar

Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹri, Atiku Abubakar ti darapọ mọ awọn araalu lati pe fun idajọ ododo lori iku akẹkọọ ọhun.

Dowen College

Oríṣun àwòrán, Twitter/Screenshot

Atiku ni "A ti ba ojuṣe wa ku gẹgẹ bii obi ati alagbatọ, agbofinro ati ijọba ti a ko ba tuṣu de isalẹ ikoko bi ọrọ Sylvester Oromoni ṣe jẹ."

Tonto Dikeh

Gbajumọ oṣere tiata lede Gẹẹsi, Tonto Dike ti gbena woju awọn alaṣẹ ile ẹkọ girama ti oloogbe naa ti n kẹkọọ.

Oju opo Instagram rẹ lo ti fi ọrọ naa lede.

Dowen College student death

Oríṣun àwòrán, Twitter/Screenshot

O ni "Dowen College mi ọwọn, mo ti gbọ nipa ohun to ṣẹlẹ mo si ti bẹrẹ igbesẹ lati mọ si nipa iṣẹlẹ ọhun."

"Ko yẹ ki awọn ọmọ wa gba ile ẹkọ de inu iboji o."

Àkọlé fídíò, Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

Burna Boy

Burna Boy naa ko gbẹyin ninu awọn gbajumọ to ti sọrọ nipa iku Sylvester Onoromi loju opo Instagram rẹ.

O ni "Ko si ọmọ to yẹ ko ku sile ẹkọ rẹ, paapaa irufẹ iku bayii."

Oby Ezekwesili

Minisita fun eto ẹkọ tẹlẹ, Oby Ezekwesili ti sọrọ nipa iku akẹkọọ naa.

Ezekwesili sọ pe iku akẹkọọ ọhun jẹ ohun to ba eeyan ninu jẹ gidi."

Dowen College student death

Oríṣun àwòrán, Twitter/Screenshot

"Ko si ọrọ ti eeyan le fi tu awọn ọmọ ti irufẹ iṣẹlẹ yii ba ṣẹlẹ ninu.

Awọn eeyan jankan mii to tun sọrọ lori iku akẹkọọ naa ni Harrison Gwamnishu, Mercy Johnson Okojie, Uche Jombo, Adesua Etomi-Wellington, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀