Sylvester Oromoni autopsy report: Kọmisọnna ọlọ́pàá Eko ní èsì àyẹ̀wò òkú Sylvester Oromoni kò fihàn pé ẹnikẹ́ni ló pa á

Oríṣun àwòrán, others
Baba Sylvester Oromoni ,akẹkọọ Dowen College to ku laipẹ yii sọ pe oun ko ni i sin oku ọmọ naa titi idajọ ododo yoo fi waye lori iku rẹ.
Ọgbẹni Oromoni sọrọ naa lẹyin ti Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu kede pe iku lati ọdọ Ọlọrun lo pa ọmọ naa.
Ọgbẹni Odumosu sọ pe ayẹwo ti wọn ṣe si oku ọmọdekunrin naa fihan pe kii sẹ ẹnikẹni lo fa iku rẹ, gẹgẹ bi iroyin ṣe n sọ .
Ṣugbọn nigba to ba iwe iroyin Punch sọrọ, Ọgbẹni Oromoni sọ pe idile oun ti pinnu pe dandan ni ki awọn ri idajọ gba lori iku ọmọ wọn.
O ni oun ko ni i sin oku ọmọ naa titi idajọ yoo fi waye, koda ko sẹ ọgbọn ọdun.
"Idile mi ko ni agbara. Ọlọrun ni a gbojule. Ṣugbọn, ti Ọlọrun ba da ẹmi mi si fun ogun ọdun tabi ọgbọn ọdun, mi o ni jawọ ninu ẹjọ yii.
"Ẹru ko ba mi, nitori mo mọ pe ijọba kan ko le wa nibẹ lailai. Ẹmi ọmọ naa n ké kaakiri. Ọlrun wa laaye, ko si si ẹni to le fun ni abẹtẹlẹ."
O ṣalaye pe oun mọ pe magomago wa ninu esi ayẹwo oku ti ijọba ipinlẹ Eko kede.
Ikú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló pa Sylvester Oromoni - Ọlọ́pàá
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe ko si ẹri to daju lati fidi rẹ mulẹ pe awọn kan lo lu akẹkọọ ile ẹkọ Dowen ni Lekki, Sylvester Oroomoni ki ẹmi to bọ lẹnu rẹ.
Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ṣalaye fawọn akọroyin lọjọ Ẹti pe ko si ẹri to fidi rẹ mulẹ pe wọn fipa fun Sylvester ni kẹmika mu ki o to ku.
Odumosu ni esi ayẹwo oku ti wọn ṣe lara oku Sylvester fihan pe iku ati ọdọ Ọlọrun wa ni akẹkọọ ọmọ ọdun mejila naa ku.
- Mi ò retí kí àwọn ọmọ Naijria gbóríyìn fún mi lẹ́yìn ìṣèjọba mi - Buhari
- Àwa náà ṣetán láti ma gbé oúnjẹ àti máàlù wà silẹ Igbo- Oloúnjẹ̀ ilẹ̀ Àríwá
- Lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta tí wọ́n kéde pé ìyá mi kú, ó tún mi ọwọ́ rẹ̀ ooo - Ọmọ Iyabo Oko
- Àrà mérìírí! Ìbejí tí a bí ní ọdun 2021 àti 2022 pẹ̀lú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dògún láàrin wọn
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti wẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún àti òṣìṣẹ́ márùn-ún ilé ẹ̀kọ́ Dowen College mọ́
- Ojú máa ń tì mí láti rẹ́rìn ín nítorí irú eyín ẹnu mi ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ mo padà dí arìnrìnoge- Omotola Ekundayo
Ọga ọlọpaa naa tun sọ pe ko si ẹri bakan naa lati fidi rẹ mulẹ pe awọn akẹgbẹ Sylvester kan fẹ fi ipa mu wọ ẹgbẹ okunkun bakan naa.
Ọgbọnjọ oṣu kọkanla ọdun 2021 ni Sylvester ku lọna to ya ọpọ eeyan lẹnu.
Ileeṣẹ ọlọpaa mu akẹkọọ marun un ati olukọ mẹta ti Sylvester darukọ wọn ki ẹmi to bọ bọ lara rẹ.
Amọ, wọn ti gba beeli gbogbo wọn lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ko si ẹri to le fidi rẹ mulẹ pe wọn mọ nipa iku Sylvester.
Ẹwẹ, baba Sylvester ti sọ pe ohun ti idile oun n fẹ ni ki ile ẹkọ Dowen ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ni ọmọ oun.
Àwọn ọ̀dọ́ Ijaw ṣe ìwọ́de láti fi ẹ̀hónú hàn pé ìdájọ́ ikú Sylvester Oromoni kò tẹ́ wọn lọ́rùn
Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ijaw ní Ọjọ́bọ̀ ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn ní iwájú ilé ẹ̀kọ́ Dowen College, Lekki.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ṣe wẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ náà mọ́ lórí ikú Sylvester Oromoni.
Àwọn Olùfẹ̀hónú hàn ọ̀hún tí wọ́n gbé àkọ́lé onírúurú lọ́wọ́, ni wọ́n ń bèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ náà, kí ìjọba gba ilé ẹjọ́ láyè láti ṣe iṣẹ́ wọn.Èsì àyẹ̀wò òkú Sylvester Oromoni kò fihàn pé ẹnikẹ́ni ló pa á - Kọmiṣọnna ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
- Oṣù díẹ̀ ṣẹ́yìn lé fún mi nítorí bí ojú ìyá mi tó fọ́ ṣe tún le koko - Funmi Awelewa
- Ẹgbẹ̀rúndínlàádọ́ta àwọn Agbéṣùmọ̀mí láti ṣekúpa láàrín oṣù méje- Iléeṣẹ́ ológun Nàìjírà
- Obìnrin kan ń pa ẹgbèrún méjìdínlógójì Pọ́ùn lọ́sẹ̀ fún isó títa
- Ka nípa àwọn Fásìtì 25 péré tí àjọ NUC ní ètò ẹ̀kọ́ wọ́n kájúẹ̀ ní Nàìjíríà
- Lásìkò ìséde Covid 19, wo bí àwọn olùgbé ìlú yí ṣé n fí fóónù ṣé pàṣípààrọ̀ oúnjẹ
- Inú wa dún pé Oba Oke dá ẹ̀mí Iyabo Oko padà, a gbàgbọ́ pé ìya wa ṣì máa gbádùn pẹ̀lú àdúrà- Omo Iyabo Oko
Bákan náà ni wọ́n ń sọ wí pé ilé ẹ̀kọ́ Dowen College kò tí ì gbọdọ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà.
Ewẹ̀, bàbá Sylvester Oromoni ti rọ ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó láti fi èsì àyẹ̀wò ikú ọmọ òun léde fún gbogbo aráyé.

Oríṣun àwòrán, Rapid response/facebook/other
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti wẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún àti òṣìṣẹ́ márùn-ún ilé ẹ̀kọ́ Dowen College mọ́
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún àti òṣìṣẹ́ márùn-ún ilé ẹ̀kọ́ Dowen College kò lọ́wọ́ nínú ikú olóògbé Sylvester Oromoni.
Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n ti fẹ̀sùn kàn ṣaájú wí pé wọ́n lọ́wọ́ nínú okùnfà ikú ọmọ ọdún méjìlá náà ni wọ́n ní wọn kò ní ẹjọ́ kankan láti jẹ́ mọ́ lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.
Adétutù Oshinusi tó jẹ́ Adarí ẹ̀ka abániṣẹjọ́ ìpínlẹ̀ Èkó (DPP) ló gba Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó lámọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí àyẹ̀wò ilé ìwòsàn ti ní kìí ṣe kẹ́míkà ló pa á.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ Wasiu Eluyẹra tó fẹ́ pa ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó lóyún
- Lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta tí wọ́n kéde pé ìyá mi kú, ó tún mi ọwọ́ rẹ̀ ooo - Ọmọ Iyabo Oko
- Ta ni Oloye Lekan Balogun tí àwọn Afọbajẹ mẹ́wàá nínú mọ́kànlá fẹnukò pé òun ni Olubadan ilẹ̀ Ibadan kàn?
- Afenifere, PDP, Ohaneze sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Buhari lórí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ètò ààbò
- Ìgbìmọ̀ Afọbajẹ ilú Ìbàdàn buwọ́lu Lékan Balógun gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn tuntun ṣùgbọ́n....
Nínú àkọráńṣẹ́ kan tí wọ́n fi ṣowọ́ sí igbákejì kọ́míṣọ́nà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó, SCID àti májísíréètì tó wà nídìí ẹjọ́ náà ni Oshinusi ti gba ìjọba lámọ̀ràn bẹ́ẹ̀.
Bákan náà ni ìjọba ní kò sí ẹ̀rí kankan láti fi fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wà nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn kankan.
Orúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni Favour Benjamin (16), Micheal Kashamu (15), Edward Begue (16), Ansel Temile (14) ati Kenneth Inyang (15).
Orúkọ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ní wọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìwà àìbìkíkà tí wọ́n fi kàn wọ́n ni Celina Uduak, Valentine Igboekweze, Hammed Ayomo Bariyu, Adesanya Olusesan Olusegun ati Adeyemi.
Ìjọba wá pa á láṣẹ wí pé tí ọ̀kan nínú àwọn afurasí yìí bá ṣì wà ní àhámọ́ ni kí wọ́n tú sílẹ̀ lẹ́yẹ ò sọkà.
- Ìjọba Nàìjíríà kéde àwọn agbébọn gẹ́gẹ́ bíi agbésùnmọ̀mí káàkiri Nàìjíríà
- Sanwo-Olu ṣèlérí láti ṣiṣẹ́ lórí àbọ̀ ìgbìmọ̀ olùwádìí ilé alájà 21 tó wó ní Ikoyi
- Erin tẹ obìnrin kan àti ọmọ rẹ̀ pa lọ́jọ́ ọdún
- Ọwọ́ Ọlọ́pàá ti tẹ̀ Obìnrin ọlọ́pàá tó kí ọwọ́ ọmọ tó ń gbé pẹ̀lú rẹ̀ bọ omi gbígbóná nítorí pé o jí ẹran jẹ lásìkò ọdún Kérésìmesì
- Àwọn akẹgbẹ́ Gómìnà Sanwo-Olu f'ohùn sílẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìdójútini tó ṣẹlẹ̀ sí i lọ́wọ́ ọlọ́pàá ní Magodo
Èsì àyẹ̀wò òkú Sylvester Oromoni kò fihàn pé ẹnikẹ́ni ló pa á - Kọmiṣọnna ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
Baba Sylvester Oromoni, akẹkọọ ile ẹkọ Dowen College nilu Eko ti iroyin sọ pe awọn akẹẹgbẹ rẹ pa ti sọ pe ayẹwo oku ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta fọwọ si ni oun fọwọ si.
Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2021 ni esi ayẹwo naa jade.
Ninu ayẹwo naa ni onimọ nipa ẹya ara, Dokita Clement Vhriterhire ti sọ pe ọgbẹ ti kẹmika oloro fa ninu ẹdọforo ọmọ naa lo pa a.
Awọn nkan miran to tun mẹnu ba ni pe:
- Oke ètè rẹ bó
- Egbo wa ni ẹyin rẹ
- Ikun rẹ wu
- ọgbẹ wa ninu ẹdọforo rẹ
- Ẹdọ rẹ wu
Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si
- Ikú Sylvester Oromoni: Wo kókó òfin ìpínlẹ̀ Eko mẹ́wàá tó tako ẹgbẹ́ òkùnkùn
- Àbùkù ńlá ni ikú Sylvester Oromoni jẹ́ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó- ìyàwó Gómìnà Sanwo-Olu
- Ilé ẹjọ́ gba béèlì akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College márùn ún tó ń jẹ́jọ́ lórí ikú Sylvester Oromoni
- Ọmọkùnrin tó fẹ́ kọ́ṣẹ́ Yahoo wá sọ́dọ̀ wa lẹyìn tó mu Colorado tán ló bá kú- Afurasí ọmọ Yahoo
- Ikú d'óróó! Àjálù ikú míì tún ṣe Pásítọ̀ Taiwo, ọkọ Bimbo Odukoya
Baba Sylvester, ọgbẹni Oromoni sọ ọrọ yii lẹyin ti iroyin sọ pe kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ní esi ayẹwo ti wọn ṣe si oku ọmọ naa nipinlẹ Eko, ko tọka si pe ẹnikẹni lo ṣokunfa iku rẹ.
Ọgbẹni Odumosu sọ pe awọn obi oloogbe, awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn fi ẹsun iku rẹ kan, awọn alaṣẹ ile ẹkọ Dowen, ati aṣoju ijọba lo wa nibi ti awọn ti ṣe ayẹwo nipinlẹ Eko.
Bakan naa lo sọ pe awọn gba beeli awọn olukọ ile ẹkọ naa ati awọn akẹkọọ to jẹ afurasi, nitori pe ko si nkankan to tọka si pe awọn lo pa Sylvester Oromoni.
Ati pe wọn ti lo ju ogunjọ lọ ni ahamọ, eyi to tako ẹtọ wọn.
O ni gbigba beeli wọn ko tumọ si pe ẹjọ ti pari lori ọrọ iku ọmọ naa.
O ni esi ayẹwo miran ti wọn fi n mọ boya nkan oloro wa ninu ara lo ku ti awọn n reti bayii.
Ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 ni Sylvester kú, ti awọn obi rẹ si sọ pe awọn akẹkọọ kan lo lu u nitori o kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.
Ṣugbọn awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa sọ pe ori papa bọọlu ni Sylvester ti farapa.






















