Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ Wasiu Eluyẹra tó fẹ́ pa ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó lóyún

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ ọlọpaa ipinlẹ ogun ti nawọ gan arakunrin kan ẹni ọdun marundinlogoji Wasiu Eluyẹra fun ẹsun wi pe o lẹdi apopọ mọ ọrẹ rẹ kan Adeyẹmi Samuel lati ṣekupa iyawo rẹ tẹlẹ ri, Bọla Taiwo ẹni ọdun mọkandinlọgbọn to loyun fun-un.
Alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje sọ wi pe afurasi naa ni o ti fi igba kan ri fẹ Bola Taiwo sile gẹgẹ bi aya ki ipinya to de si aarin wọn to si ti fẹ iyawo miiran to n gbe pẹlu rẹ
- Lekan Balogun wà lára ọba 21 tí Ajimobi fi jẹ, ipò Olubadan kò tọ́ sí i - Amòfin kọ̀wé sí Makinde
- Koiki àti Olajengbesi ń jíṣẹ́ ara wọn ni, Igboho kọ́ ló rán wọn níṣẹ́, Agbẹjọ́rò Sunday Igboho faraya
- Mọ̀ nípa òfin tuntun tó lé mú kí èèyàn rí ìrànlọ́wọ́ ìjọ̀ba láti gbẹ̀mí ara rẹ̀ ní Austria
- Wọ́n ti sin òkú Alhaji Bashir Tofa ni Kano báyìí
- 'Pelumi Olajengbesi kìí ṣe agbẹjọ́rò Sunday Igboho, Ilana Omo Oodua ló gbà á ṣíṣẹ́'
O ṣalaye pe Eluyera tun rina pade iyawo rẹ tẹlẹ ri yii ni wọn ba nawọ gan ere ifẹ nibi ti wọn fi pamọ ti ere naa si di oyun.
Eluyera ni ki Taiwo ṣẹ oyun yii latari ki iyawo ile rẹ ma ba gbọ ṣugbọn Taiwo kọ jalẹ eyi si mu ki o pinnu lati gba ẹmi rẹ toyuntoyun
Eluyera sọ pe ẹmeeji ọtọọtọ ni oun ti gbiyanju lati ran Taiwo lo sọrun apapandodo nipa fifi majele sinu ounjẹ ṣugbọn ori n ko o yọ
Eyi jẹ lataari pe ko jẹ awọn ounjẹ naa eyi lo si mu u gbe iṣẹ agbanipa fun ọrẹ rẹ Samuel Adeyemi.
Agbenuso Oyeyemi sọ siwaju pe ni agbegbe Oponuwa, Ogijo ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi mejeeji yii nibi ti wọn ti n yọwọ ẹṣẹ si ra wọn.
O fi kun pe ninu ifọrọwanilẹnuwo ni Adeniyi Samuel ti jẹwọ wi pe Eluyera lo ṣeleri lati fun oun ni ẹgbẹrun mẹwaa naira ti oun ba ba oun ṣekupa iyawo oun tẹlẹ ri ọhun to si ti fun oun ni ẹgbẹrun marun-un ninu owo naa.
- Wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí ní ilé Oloye Lekan Balogun tí wọ́n n sọ pé oyè Olubadan kàn
- 'Pelumi Olajengbesi kìí ṣe agbẹjọ́rò Sunday Igboho, Ilana Omo Oodua ló gbà á ṣíṣẹ́'
- Olóòtú ìjọba Sudan, Abdalla Hamdok ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn ìwọ́de àwọn ará ìlú
- Gomina Wike fi òfin de iṣẹ́ aṣẹ́wó, Night Club, kátàkárà alẹ́ àti àwọn nkan míràn
- Ta ni Oloye Lekan Balogun tí aráyé ń pariwo pé òun ni Olubadan ilẹ̀ Ibadan kàn?
Eluyera ni ija bẹ silẹ laaarin wọn nigba ti ọrẹ kọ lati ṣe iṣẹ ti o gbe fun-un to si kọ lati da ẹgbẹrun marun un naira ti o ti ṣaaju fun pada
Kọmiṣọnna ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti pe fun iwadii ijinlẹ sinu iṣẹlẹ naa ki wọn si fi oju awọn afurasi naa ba ile ẹjọ.















