Assited suicide in Austria: Mọ̀ nípa òfin tuntun tó lé mú kí èèyàn rí ìrànlọ́wọ́ ìjọ̀ba láti gbẹ̀mí ara rẹ̀ ní Austria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹ-ede Austria ti fọwọ si ofin ti yoo mu ki awọn ọmọ orilẹ naa ni anfaani lati kọwe beere fun iku.
Bẹrẹ lati ọjọ Satide, ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2022, awọn to ba ni aisan gbẹmi-gbẹmi tabi to ni aisan ti ko gboogun le sọ fun dokita wọn lati ṣe atọna iku fun wọn.
Awọn ọmọde ati awọn to ni aarun ọpọlọ nikan ni ofin yii yọ silẹ.
Oṣu Kejila ni ile aṣofin buwọlu ofin tuntun naa.
- Wọ́n ti sin òkú Alhaji Bashir Tofa ni Kano báyìí
- 'Pelumi Olajengbesi kìí ṣe agbẹjọ́rò Sunday Igboho, Ilana Omo Oodua ló gbà á ṣíṣẹ́'
- Olóòtú ìjọba Sudan, Abdalla Hamdok ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn ìwọ́de àwọn ará ìlú
- Gomina Wike fi òfin de iṣẹ́ aṣẹ́wó, Night Club, kátàkárà alẹ́ àti àwọn nkan míràn
- Ta ni Oloye Lekan Balogun tí aráyé ń pariwo pé òun ni Olubadan ilẹ̀ Ibadan kàn?
Ninu ofin yii, dokita meji ni yoo ṣe agbeyẹwo iwe ẹbẹ alaisan naa - ẹnikan lara wọn si gbọdọ jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa bi eeyan ṣe n gbe igbeaye pẹlu aisan ọlọjọ pipẹ.
Bakan naa ni ijọba ti ya owo sọtọ lati gbọ bukaata itọju awọn to ni aisan to le yọri si iku daadaa, lai jẹ pe wọn yan iku layo fun'ra wọn.
Gẹgẹ bi nkan ti ajọ eto ilera ilẹ Gẹẹsi sọ, iranlọwọ iku (Ehanasia) jẹ finu-findọ gbẹmi eeyan nitori ki wọn o ma ba mọ irora.
Labẹ rẹ ni ṣiṣe atọna iku wa - eyi to sumọ si pe ki dokita gbà lati ran ẹlomiran lọwọ lati gbẹmi ara wọn.
- Iléewòsàn UCH kò lè bá Aafin Ibadan parọ́, ẹ dẹ́kún gbígbé ìròyìn òfegè nípa Oba Adetunji tó wàjà- Adeola Oloko
- Ọmọkùnrin tó fẹ́ kọ́ṣẹ́ Yahoo wá sọ́dọ̀ wa lẹyìn tó mu Colorado tán ló bá kú- Afurasí ọmọ Yahoo
- Ọmọkùnrin kan bẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin tó lóyún lórí nítorí pé...
- Mo ti ra ilẹ̀ ìsìnkú mi ní 'Ebony Vault' ṣùgbọ́n....
- Ilẹ̀ ń j'ẹ̀nìyàn! Ka nípa àwọn Ìlúmọ̀ọ́ka tó dágbére fáyé ní 2021
Iru ofin yii naa wa ni orilẹ-ede Switzerland to jẹ alamuleti Austria.
Alaisan to ba fẹ iru iranlọwọ yii gbọdọ pese ẹri pe lootọ lo ni aisan , ati pe o le ṣe ipinnu fun'ra rẹ.
Lẹyin ti dokita meji ba buwọlu u tan, iru alaisan naa gbọdọ duro fun ọsẹ mejila lati ronu jinlẹ lori igbesẹ rẹ - ọsẹ meji ni fun awọn to ba ni aisan gbẹmi-gbẹmi.
Ti wọn ba ṣi fẹ iranlọwọ iku lẹyin akoko ti wọn fi duro, dokita yoo kọ orukọ oogun oloro to le tete pa wọn. Wọn si ni anfaani lati ra a ni ile itaja oogun lẹyin ijiroro pẹlu amofin wọn.
Ko ma ba a si aṣilo ofin tuntun yii, awọn amofin tabi agbẹjọro nikan ni ijọba yoo fun ni orukọ awọn ile itaja oogun ti wọn ti n ta awọn oogun naa.
Ṣaaju asiko yii, idajọ ẹwọn ọdun marun-un lo wa fun ẹnikẹni to ba ṣe iranlọwọ iku fun ẹlomiran ni orilẹ-ede Austria.
Ṣugbọn ile ẹjọ kan to jẹ ti ijọba apapọ fagile ofin to de igbesẹ naa. O ni o tako ẹtọ ọmọniyan lati ṣe ipinnu nkan to wu wọn.
Amọ, ijiya naa ṣi wa fun ẹnikẹni to ba pa ẹlomiran, koda ko ṣe pe alaisan ọhun lo beere fun-un.


















