Gomina Wike fi òfin de iṣẹ́ aṣẹ́wó, Night Club, kátàkárà alẹ́ àti àwọn nkan míràn

Oríṣun àwòrán, NYESOM WIKE/FACEBOOK
Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti fofin de iṣẹ aṣẹwo ati ile ijo 'Night Club' nipinlẹ naa.
Ninu ọrọ to ba awọn eniyan ipinlẹ Rivers sọ fun ọdun tuntun lo ti kede pe ko gbọdọ si kara-kata ni alẹ mọ, to fi mọ awọn aṣẹwo to n duro ni ẹ́gbẹ́ titi, paapaa ni awọn adugbo bii Abacha road ati awọn opopona to yi i ka bi Casablanca.
- Ta ni Oloye Lekan Balogun tí aráyé ń pariwo pé òun ni Olubadan ilẹ̀ Ibadan kàn?
- Ọmọkùnrin tó fẹ́ kọ́ṣẹ́ Yahoo wá sọ́dọ̀ wa lẹyìn tó mu Colorado tán ló bá kú- Afurasí ọmọ Yahoo
- Ṣé lóòtọ́ ni wọ́n rọ Oba Ijeru, Onpetu Sunday Oladapo lóyè?
- Ọmọkùnrin kan bẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin tó lóyún lórí nítorí pé...
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba àpapọ̀ fẹ́ pa Sunday Igboho sí ẹ̀wọ̀n? Agbẹjọ́rò rẹ̀ sọ̀rọ̀
O ni aṣẹ tuntun yii yoo fi opin si ipa buruku ti iṣẹ ainitiju yii n ni lara ihuwasi awọn ọmọde ati awujọ ni apapọ.
Yatọ si eyi, Gomina Wike tun kede pe ijọba yoo gba awọn ilẹ ti ko si ile lori wọn ati awọn ile akọ pati to wani GRA nilu Port Harcourt ati Obio Akpor.
Gomina sọ pe igbesẹ na yoo waye nitori pe awọn ọdaran ti n lo wọn fun iṣẹ ibi.
Ijọba ni yoo si ta awọn ilẹ naa fun awọn to ṣetan lati kọ ile sori wọn ni kiakia.
Bakan naa lo tun paṣẹ fun awọn alaga ijọba ibilẹ pe ki wọn o ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn olori agbegbe lati mọ awọn to ni ibudo ifọpo ti ijọba ko fọwọ si.
Lati asiko diẹ ni awọn eeyan ilu Port Harcourt ti n ke irora lori bi gbogbo inu ile wọn, ọkọ to fi mọ ẹya ara wọn ṣe n dudu nitori eefin to n jade lati awọn ibudo ifọpo naa.
Wike sọ pe ijọba oun yoo bẹrẹ si ni kọju ija si awọn eniyan naa bayii, nitori pe ijọba apapọ ko dahun si iwe ti oun kọ si lati fi opin si iṣẹ awọn ibudo ti wọn ti n fọ eporọbi, ti ijọba ko fi ọwọ si.
- Ohun tí CAN fi ṣíde ọdún 2022 fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà nìyí
- 'Àwọn olóṣèlú Nàìjíríà náà máa n ṣàbèwò sí àwọn wòólì, wọn kò lè fòfin de àsọtẹ́lẹ̀ ọdún tuntun'
- Wo àwọn Sẹlẹ́bírítì fíìmù àti Olórin Yorùbá tí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ wọ́n àti ìṣẹ̀lẹ̀ míì dàgboro rú lọ́dún 2021
- Àsọtẹ́lẹ̀ 2022 àti ìgbésẹ̀ tí Pásítọ̀ Enoch Adeboye fẹ́ gbé lórí ìdojúkọ Nàìjíríà nìyí
Awọn ofin miran to tun sẹ fun ọdun tuntun ni pe ijọba yoo ma a gbẹsẹ le ọkọ ti wọn ba gbe si ojupopo ju wakati mejidinlaadọta lọ. Bakan naa ni ijọba yoo tun wó awọn ile ti wọn kọ si oju àgbàrá.
O kede pe ijọba oun yoo gbe ajọ alaabo kogberegbe kalẹ lati ma a fi ofin mu awọn toba ru awọn ofin tuntun.















