Oba Sunday Oladapo: Ṣé lóòtọ́ ni wọ́n rọ Oba Ijeru, Onpetu Sunday Oladapo lóyè?

Sunday Oladapo

Oríṣun àwòrán, Oba Sunday Oladapo

Onpetu ti Ijeru nipinlẹ Oyo, Oba Sunday Oladapo ti rọ awọn ọmọ ilu naa lati gboju kuro nibi iroyin kan to sọ pe wọn ti rọ oun loye.

Ilu Ijeru ko fi bẹẹ jina si Ogbomoso,ni eyi to si jẹ pe abẹ Ogbomoso si ni ilu naa wa ni ipinlẹw Oyo to wa ni Iwo oorun guusu Naijiria.

Ninu atẹjade kan to fi sita, eyi to tẹ BBC lọwọ ni Oba Oladapo ti sọ pe ayederu ni iroyin to n lọ lori ayelujara pe wọn ti rọ oun loye.

Oba Oladapo sọ pe idajọ ile ẹjọ kan lo mu ki awọn eeyan kan ma a gbe iroyin ọhun.

O ni ṣugbọn, abala kan pere ninu idajọ ni wọn n fi sinu iroyin wọn.

O ni ko si ẹjọ kankan lori iyansipo oun gẹgẹ bi ọba.

"Idajọ ile ẹjọ ti awọn ileeṣẹ iroyin kan fi gbe iroyin wọn jade, lo da lori ede aiyede to waye larin Oba Yesufu Abidoye Mobolade ati Oloye Adeleke Lawal, ati awọn meji miran.

Àkọlé fídíò, Ọdún tó súnmọ́ ìdìbò ni 2022, wọ́n ó ni ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀

Ti wọn si gbe ara wọn lọ si ile ẹjọ giga to wa nilu Ogbomoso.

"Koda, ile ẹjọ kotẹmilọrun ti Oba Mobolade pada gbe ẹjọ lọ nilu Ibadan sọ lọdun 1999 pe ọrọ oye ilu ni ọrọ naa, ti ko si dasi. "

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Oba Oladapo ni awọn meji ti ọrọ naa kan ti ku ṣaaju idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun, ati pe nkan ti wọn n ja si ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu ipo ọba Onpetu ti ilu Ijeru.

Àkọlé fídíò, Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì àti Kàyéfì tó wáyé lọ́dún 2021 rèé nínú fídíò