Olubadan of Ibadan dead: Wọ́n ti gbé Olubadan wọ káà ilẹ̀, bí ìsìnkú Ọba Adetunji ṣe lọ nìyí

Oríṣun àwòrán, other
Wọn ti gbe ara Kabiyesi Olubadan ti ilẹ Ibadan Ọba Salihu Adetunji wọ kaa ilẹ lọ nilu Ibadan.
Wọn ṣeto isinku Ọba Adetunji to waja lowurọ ọjọ Aiku, ọjọ keji, oṣu kinni, ọdun 2022 ni aafin rẹ to wa lagbegbe Popoyemọja.
Lara awọn eekan ilẹ Ibadan to wa nibi isinku rẹ ni gomina ipinlẹ Ọyọ nigbakan ri, Oloye Rashidi Ladọja ati iyawo rẹ, Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Adebayọ Alao Akala, igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, rauf Ọlaniyan ati Sẹnetọ Fatai Buhari to n ṣoju ẹkun ariwa ọyọ nile aṣofin agba.
- Mo ti ra ilẹ̀ ìsìnkú mi ní 'Ebony Vault' ṣùgbọ́n....
- Ọmọkùnrin tó fẹ́ kọ́ṣẹ́ Yahoo wá sọ́dọ̀ wa lẹyìn tó mu Colorado tán ló bá kú- Afurasí ọmọ Yahoo
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba àpapọ̀ fẹ́ pa Sunday Igboho sí ẹ̀wọ̀n? Agbẹjọ́rò rẹ̀ sọ̀rọ̀
- 'Àṣírí ọkọ mi tú sími lọ́wọ́, ṣé mo le dáríjì í?'
- Wo bí àwọn gbajúmọ̀ tí ẹ̀ fẹ́ràn yìí ṣe tẹ̀ẹ́ wọ́nú ọdún 2022 àtí ohun t'Ọ́lọ́hun gbé wọn borí

Oríṣun àwòrán, others
Wo ǹkan mẹ́jọ tí o kò mọ́ nípa Olubadan, Oba Saliu Adetunji tó re ìwàlẹ̀ àṣà..
Oba Saliu Adetunji ti darapọ mọ awọn Baba nla rẹ ni ajule ọrun.
Ori ade naa la gbọ pe o ku si ilewosan aladani kan nilu Ibadan ni owurọ ọjọ Aiku, ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2022.
Ẹni ọdun mẹtalelaaadọrun ni.
Ẹnikan ni aafin to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun sọ pe kii ṣe iroyin ibanujẹ ni iku kabiesi, nitori pe wọn dagba.
Bo tilẹ jẹ pe ko sọ nkan to pa kabiesi, o ni "ṣe ẹyin naa mọ pe ti eeyan ba ti dagba to ọjọ ori Kabiesi, ko si nkan ti ko le ṣẹlẹ''.
Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, ọdun 2016 ni wọn fi Ọba Adetunji jẹ gẹgẹ bi olubadan kọkanlelogoji.
Itan igbe aye Oba Saliu Adetunji Aje Oguguniso 1
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 1928 ni wọn bi Oloogbe Saliu Akanmu Adetunji ni agboole Adetunji, ni augbo Popoyemoja nilu Ibadan.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, Oba Adetunji ko lọ si ile ẹkọ kankan.
O ni ibaṣepọ oun pẹlu awọ̀n oyinbo alawọ funfun, gẹgẹ bi oniṣowo lo fun oun ni anfaani lati gbọ ede Gẹẹsi.
Iṣẹ aranṣọ ni Adetunji kọkọ kọ ni owurọ aye rẹ.
Olubadan ilẹ̀ Ibadan, Oba Saliu Akanmu Adetunji ti jáde láyé
Lẹyin naa lo bẹrẹ okoowo awo orin 'rẹkọọdu' ti ta nilu Eko.
Ṣababi ni okowo rẹkọdu tita jẹ fun un.
Idi ni pe ọrẹ baba rẹ kan to ri awọn awomọni kan to dara nipa rẹ lo ṣe atọna bo ṣe bẹrẹ iṣẹ naa.
Orukọ ẹni naa ni Badejo Okusanya, Badejo Sound Studio, ti iroyin sọ pe oun ni ọmọ Naijiria akọkọ to ni ileeṣẹ to n gbe orin jade.
Ọdun 1957 lo pa iṣẹ aranṣọ tì patapata to si bẹrẹ okoowo gbigbe orin jade ni ọọfisi rẹ to wa ni Oke Popo nilu Eko.
Orukọ ileeṣẹ orin rẹ ni Omo Aje Records.
Lara awọn olorin to gba ileeṣẹ Omo Aje Records jade ni Dauda Epo Akara, Tatalo Aremu, Amuda Agboluaje, Wasiu Ayinde K1, Jimoh Ayinla Anikura, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O pada sọ orukọ ileeṣẹ naa ni Babalaje Records.
Bawo lo ṣe bẹrẹ irinajo rẹ si aafin gẹgẹ bi ọba?
Gẹgẹ bi eto ọba jijẹ nilẹ Ibadan, ọdun 1976 ni Saliu Akanmu Adetunji di Mogaji agboole Adetunji.
Akasọ oye mẹtalogun lo gun ko to o di Olubadan lọdun 2016, lẹyin ti Oba Samuel Odulana waja.
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Oloogbe Abiola Ajimobi lo jawe oye le lori.




















