India, Aurangabad: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ókùnrin tó bẹ́ orí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin tó gbóyún

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn ọlọpaa ilu Maharashtra lorilẹ ede India ti mu afurasi ọdọkunrin kan to bẹ ẹgbọn rẹ obinrin oloyun lori.
Awọn ti ọrọ naa soju wọn ni ẹbi ko faramọ ọkọ ti obinrin naa fẹ lo ṣokunfa iṣẹlẹ yìí.
Iroyin sọ pe ọmọbinrin naa n mu tii lọwọ pẹlu mama ati buọda rẹ ki ọmọkunrin naa to kọ lu u lojiji.
- Wo ǹkan mẹ́jọ tí o kò mọ́ nípa Olubadan, Oba Saliu Adetunji tó re ìwàlẹ̀ àṣà..
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba àpapọ̀ fẹ́ pa Sunday Igboho sí ẹ̀wọ̀n? Agbẹjọ́rò rẹ̀ sọ̀rọ̀
- Ọmọkùnrin tó fẹ́ kọ́ṣẹ́ Yahoo wá sọ́dọ̀ wa lẹyìn tó mu Colorado tán ló bá kú- Afurasí ọmọ Yahoo
- Mo ti ra ilẹ̀ ìsìnkú mi ní 'Ebony Vault' ṣùgbọ́n....
- 'Àṣírí ọkọ mi tú sími lọ́wọ́, ṣé mo le dáríjì í?'
Lẹyin naa ni ọdọkunrin yìí ati mama re lọ fi ara wọn han lọdọ awọn olopaa.
Ileeṣẹ ọlọpaa fẹsun kan odomokunrin ọhún naa pe o duro ṣegbẹ obinrin to bẹ lori.
Ni oṣu kẹfa, ọdun 2021 ni obinrin yii kuro nile ti o si ko lọ ba pọ ololufẹ rẹ t'awọn ẹbi ko fọwọ sí.
Lootọọ ni ọkunrin naa wa lati ẹya miran, awọn ẹbi obinrin yii ko nifẹ rẹ tori ko wa lati idile olowo bi iyawo to fẹ.
Awọn ajafẹtọ ni ọpọ eeyan lo n ku lọdọọdun ni India tori awọn ẹbi ko fọwọ si iyawo wọn tori ẹni tí wọn fẹ lọkọ.
Loṣu kẹta ọdun 2021 ni awọn ọlọpaa mu ọkunrin kan nipinlẹ Uttar Pradesh lori ẹsun pe o bẹ ọmọbinrin rẹ lori tori pe o fẹ ọkunrin ti ẹbi ko fọwọ si.















