Bashir Othman Tofa: Wọ́n ti sin òkú Alhaji Bashir Tofa ni Kano báyìí

Tofa

Wọn ti sin oku Alhaji Bashir Tofa oludije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria nigbakan ri.

Ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin ni Tofa, wọn sin in ni ilana musulumi lẹyin to jade laye lọjọ Aje, ọjọ kẹta osu kini ọdun 2021.

Ni ile rẹ to wa ni agbegbe Gandul Albasa nilu Kano ni adura ni ilana musulumi ti waye.

Emir ti ilu Kano, Aminu Ado Bayero ati ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn peju si ibi adura naa ki wọn to lọ sin oku rẹ si itẹ kan nilu Kano.

Tofa

Alhaji Bashir ni oludije to ba Oloogbe MKO Abiọla du ipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria lọdun 1992.

Kounsilo ni Tofa fi bẹrẹ iselu ni ijọba ibilẹ Dawakin Tefa ni odun 1977

Emir Bayero nibi Oku Tofa

Tofa du ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu National Republican Convention, NRC nigba ti MKO Abiola dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu SDP.

Saaju iku rẹ, Tofa jẹ alaga igbimọ agba ipinlẹ Kano

Tofa