Yọmi Alliyu tó jẹ́ agbẹjọ́rò Oloye Sunday Igboho ti sọ̀rọ̀sókè lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàrin Koiki àti Pelumi Olajengbesi pé ó tó gẹ́!

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, @Sunday Igboho

Lori edeaiyede to n waye bayii lagbo awọn ajijagbara fun Yoruba nation, agbẹjọro fun Sunday Igboho, Yọmi Aliyu ti sọ pe eekan aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba labẹ aṣia Yoruba Nation, Oloye Sunday

Igboho ko fi iṣẹ ran ẹnikẹni to ba n sọ ohunkohun fun araye gbọn bayii labẹ iboju pe ọrọ ti Oloye Igboho fi ran oun sawọn eeyan ni kan n parọ lasan ni.

Amofin agba Yọmi Alliyu SAN, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe ko si ẹnikẹni to lee gbẹnusọ fun Oloye Sunday Igboho ju awọn tawọn jẹ agbẹjọro rẹ lọ.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, alaye naa ṣẹlẹ nitori iroyin kan to jade sigboro aye pe amofin Pẹlumi Ọlajẹngbesi to jẹ agbẹjọro fun awọn eeyan mejila ti wọn ko nile Sunday Igboho.

Àkọlé fídíò, Orí Tẹlifísàn ni mo ti rí Sunday Igboho rí láyé mi, bí ìyà ṣe jẹ mi gbé láti Ibadan, dé Àtìmọ́lé DSS rèé - Ifasooto Dada

Oṣu keje ọdun 2021 ni wọn ko wọn nibẹ.

Olajengbesi wa sọ pe oun jawọ lori gbigbọ́ ẹjọ ro fun Oloye Sunday Igboho.

Àkọlé fídíò, New year prayers: Gbọgbọọgbọ lọwọ́ n yọ ju orí, gbogbo wa laó yọ ju ọ̀tá wa lọ

Amofin Agba Ymi Aliyu sọ pe, ati Koiki to n pe ara rẹ lagbẹnusọ Sunday Igboho ati amofin Pẹlumi Ọlajengbesi to ni oun kọwe fi iṣẹ gbigba ẹjọ rẹ ro, ko si eyikeyi to laṣẹ lati gbẹnusọ fun Sunday Igboho ninu wọn.

Amofin Aliyu SAN ni Gbogbo ohun ti wọn ba n sọ lori Igboho, Iṣẹ ara wọn ni wọn n jẹ ki araalu maṣe kbi ara si wọn.

Àkọlé fídíò, O tó ìdá méjì àwọn ènìyàn àgbáyé to wà nínú ewu àìsàn ibà

Aliyu ni lootọ odi ọrọ ni Adari ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye sọ nigba to n wi pe ko ni si idibo ni ipinlẹ Ekiti ati Ọṣun.

Àkọlé fídíò, 'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

O ni ki araalu maṣe tẹti si gbogbo ọrọ ti Koiki ati Ọlajẹngbesi n sọ nigboro pe Oloye Sunday lo ran awọn.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo