Lekan Balogun next Olubadan: Oloye Agba, Adewolu Ladoja nìkan ló lè sọ bóyá Oloye Lekan Balogun yóò gun orí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Olubadan tuntun

Oríṣun àwòrán, Others
Kii ṣe tuntun mọ pe iroyin ti n lọ kaakiri igboro pe Oloye Agba, Lekan Balogun ni oye Olubadan ilẹ Ibadan kàn Wọ́n ti gbé Olubadan wọ káà ilẹ̀, bí ìsìnkú Ọba Adetunji ṣe lọ nìyí
Ṣugbọn bi iroyin naa ṣe n lọ, ni awọn kan tun n sọ pe oye naa ko tọ si i.Ta ni Oloye Lekan Balogun tí aráyé ń pariwo pé òun ni Olubadan ilẹ̀ Ibadan kàn?
Amofin kan, Moses Orogade, sọ pe Oloye Agba Adewolu Ladoja nikan lo le sọ boya Oloye Lekan Balogun yoo gun ori itẹ gẹgẹ bi Olubadan tuntun.
- .Iléewòsàn UCH kò lè bá Aafin Ibadan parọ́, ẹ dẹ́kún gbígbé ìròyìn òfegè nípa Oba Adetunji tó wàjà- Adeola Oloko
- Èsì àyẹ̀wò òkú Sylvester Oromoni kò fihàn pé ẹnikẹ́ni ló pa á - Kọmiṣọnna ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
- IPOB fòfin dè kíkọ orin ògo Nàìjíría láwọn ilé ẹ̀kọ́ gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà nítorí pé...
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ Wasiu Eluyẹra tó fẹ́ pa ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó lóyún
- Koiki àti Olajengbesi ń jíṣẹ́ ara wọn ni, Igboho kọ́ ló rán wọn níṣẹ́, Agbẹjọ́rò Sunday Igboho faraya
- Mọ̀ nípa òfin tuntun tó lé mú kí èèyàn rí ìrànlọ́wọ́ ìjọ̀ba láti gbẹ̀mí ara rẹ̀
Ṣaaju ni Amofin kan ti sọ pe Oloye Balogun ko tọ si ipo naa, nitori pe o ti kọkọ de ade kan gẹgẹ bi ọba.Lekan Balogun wà lára ọba 21 tí Ajimobi fi jẹ, ipò Olubadan kò tọ́ sí i - Amòfin kọ̀wé sí Makinde
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Oloogbe Abiola Ajimobi lo fi oun ati ogún eeyan mii jẹ gẹgẹ bi ọba nilu Ibadan lasiko iṣakoso Oba Saliu Adetunji to waja lọjọ Aiku.
Gẹgẹ bi oun naa ṣe sọ fun BBC, Amofin Orogade sọ pe aini suuru Oloye Balogun nigba naa lo fẹ ẹ da wahala silẹ bayii ninu oye ọba jijẹ nilẹ Ibadan.
O ni ko ṣẹlẹ ri nibi kankan nilẹ Yoruba pe ọba kan gba ade lẹẹmeji.
Gẹgẹ bi tito oye ilẹ Ibadan, Oloye Ladoja lo tun kan lẹyin Lekan Balogun.
Eyi si lo mu ki amofin Orogade sọ pe Ladoja nikan lo le sọ boya Balogun yoo jẹ Olubadan tuntun tabi ko ni jẹ.
- Wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí ní ilé Oloye Lekan Balogun tí wọ́n n sọ pé oyè Olubadan kàn
- 'Pelumi Olajengbesi kìí ṣe agbẹjọ́rò Sunday Igboho, Ilana Omo Oodua ló gbà á ṣíṣẹ́'
- Olóòtú ìjọba Sudan, Abdalla Hamdok ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn ìwọ́de àwọn ará ìlú
- Gomina Wike fi òfin de iṣẹ́ aṣẹ́wó, Night Club, kátàkárà alẹ́ àti àwọn nkan míràn
- Ọmọkùnrin tó fẹ́ kọ́ṣẹ́ Yahoo wá sọ́dọ̀ wa lẹyìn tó mu Colorado tán ló bá kú- Afurasí ọmọ Yahoo
O ni "ti Oloye Ladoja ba fi gbe ẹjọ lọ sile ẹjọ pe oun yoo jọba, ko si ọna abayọ fun Balogun. Idi ni pe o ti gba oye ọba jijẹ rẹ lọwọ Gomina ajimobi, ti ko si tun le jẹ ọba miran mọ.
"Ṣugbọn ti Ladoja ko ba sọ ohunkohun, ti ko si pe ẹjọ tako iyansipo rẹ, ko sewu."
Amofin Orogade ṣalaye pe ọpọlọpọ ọdun sẹyin ni ilana ọba jijẹ nilẹ Ibadan ti wa, ti ko si si iṣoro ri.

Oríṣun àwòrán, others
Lekan Balogun wà lára ọba 21 tí Ajimobi fi jẹ, ipò Olubadan kò tọ́ sí i - Amòfin kọ̀wé sí Makinde
Agbẹjọ́rò kan kọ lẹ́tà tako gbígbé adé Olubadan lé Lekan Balogun lórí
Agbẹjọro kan to fi ilu Ibadan ṣe ibujoko, Michael Lana ti kọ iwe ẹsun si gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde pe ko gbọdọ gbe ade le Oloye Olalekan Balogun lori gẹgẹ bi Olubadan tuntun.
Lati ọjọ ti Olubadan tẹlẹ, Oba Saliu Adetunji ti ku ni iroyin ti n lọ kaakiri ori ayelujara pe Lekan Balogun ni oye kan.
Ṣugbọn ninu iwe ẹsun to kọ ni ọjọ Aje, Amofin Lana ṣalaye pe Balogun ati awọn oloye agba miran ti gba ade gẹgẹ bi ọba lasiko isẹjọba gomina tẹlẹ, Oloogbe Abiola Ajimobi.
O ni nitori naa ni gomina Makinde ko gbọdọ fi gbe ade miran le lori gẹgẹ bi Olubadan.
- Wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí ní ilé Oloye Lekan Balogun tí wọ́n n sọ pé oyè Olubadan kàn
- Ta ni Oloye Lekan Balogun tí aráyé ń pariwo pé òun ni Olubadan ilẹ̀ Ibadan kàn?
- Iléewòsàn UCH kò lè bá Aafin Ibadan parọ́, ẹ dẹ́kún gbígbé ìròyìn òfegè nípa Oba Adetunji tó wàjà- Adeola Oloko
- Wọ́n ti gbé Olubadan wọ káà ilẹ̀, bí ìsìnkú Ọba Adetunji ṣe lọ nìyí
Amofin Lana sọ pe ko si ninu itan ilẹ Yoruba pe ẹni to ti jẹ ọba tun gba igbega bọ si ipo ọba miran.
Tẹ o ba gbagbe, ẹ o ranti pe Gomina Ajimobi fi awọn ọba tuntun mọkanlelogun miran jẹ nilu Ibadan lasiko ti Oba Saliu fi wa lori oye.
Ọrọ naa fa wahala, debi i pe o di ọrọ ile ẹjọ.
Oloye Lekan Balogun si wa lara awọn ọba mọkanlelogun naa. Koda, lara oun lo fẹ ẹ jẹ olori wọn ninu rogbodiyan ti wọn ba Oba Adetunji fa.
Amofin Lana sọ ninu lẹta rẹ pe ko si eyi to tọ si ipo Olubadan ninu awọn ọba mọkanlelogun naa, to fi mọ Lekan Balogun.
O ni oun kọ lẹta naa si Makinde nitori wahala ile ẹjọ to le waye lori iyansipo Lekan Balogun.
Lana ni "labẹ awọn ofin ifinijoye, ẹni to ti jẹ ọba ko le gun ori itẹ Olubadan.
"Niwọn igba ti awọn oloye agba naa ṣi n lo oye ọba, wọn o le gun ori itẹ naa. Gbigbe ade Olubadan le ẹnikẹni ninu wọn lori ko si ba ofin mu."

Oríṣun àwòrán, daily post

Oríṣun àwòrán, daily post

Oríṣun àwòrán, daily post
























