IPOB: A kò tún gbọdọ̀ rán àwọn ọmọ wá létí pé wọ́n wà lábé amunisin nípa kíkọ orin orilẹ ède Nàìjíría

Oríṣun àwòrán, @IPOB
Ikọ ajijagbara ilẹ Igbo ti fohun silẹ pe awọn ko ni faaye gba kikọ orin orileede Naijiria taa mọ si National Anthem lawọn ile ẹkọ to wa ni guusu ila oorun Naijiria.
Alakoso eto ilu ẹgbẹ naa arakunrin Chika Edoziem lo kede ọrọ yi ninu ikini ọdun to se alakalẹ awọn eto ikọ naa ni 2022.
Edoziem ni ki awọn alasẹ ile ẹkọ ni agbegbe yi maa kọ awọn akẹkọọ ni orin orileede Biafra nikan.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ Wasiu Eluyẹra tó fẹ́ pa ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó lóyún
- Lekan Balogun wà lára ọba 21 tí Ajimobi fi jẹ, ipò Olubadan kò tọ́ sí i - Amòfin kọ̀wé sí Makinde
- Mọ̀ nípa òfin tuntun tó lé mú kí èèyàn rí ìrànlọ́wọ́ ìjọ̀ba láti gbẹ̀mí ara rẹ̀ ní Austria
- Koiki àti Olajengbesi ń jíṣẹ́ ara wọn ni, Igboho kọ́ ló rán wọn níṣẹ́, Agbẹjọ́rò Sunday Igboho faraya
- Wọ́n ti sin òkú Alhaji Bashir Tofa ni Kano báyìí
Labẹ ofin Naijiria ijọba ti fofin de ikọ IPOB gẹgẹ bi eleyi to ni se pẹlu igbesunmọmi.
Bẹẹ naa si ni ẹgbẹ ọmọ ilẹ Igbo iyẹn Ohanaeze Ndigbo naa si ti sọ pe IPOB ko gbẹnu sọ fawọn tabi awọn eeyan ilẹ Igbo lapapọ.
Eni to jẹ olori ikọ IPOB Nnamdi Kanu si wa ni ahamọ lẹyin ti ọwọ ijọba Naijiria tẹ ti wọn si wọ lọ siwaju ile ẹjọ lori ẹsun pe o gbimọran ati doju ijọba bolẹ ati ẹsun mi.
Ninu ọrọ rẹ, Edoziem sọ pe ''ao se idasilẹ ẹka kan labẹ IPOB lati fi kun awọn eyi to wa nilẹ labẹ ẹka to n risi ọrọ ilu''.
O ni awọn yoo pe ẹka yi ni ẹka idanilẹko IPOB.
Koko pataki kan taa ri fayọ ninu ọrọ rẹ to sọ lọjọ Kini ọdun 2022 ni pe o ni '' .
A ko gbọdọ maa ran awọn ọmọ wa leti pe wọn wa labẹ imunisin nipa jijẹ ki wọn kọ orin orileede awọn to mu wa sin''
- Wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí ní ilé Oloye Lekan Balogun tí wọ́n n sọ pé oyè Olubadan kàn
- 'Pelumi Olajengbesi kìí ṣe agbẹjọ́rò Sunday Igboho, Ilana Omo Oodua ló gbà á ṣíṣẹ́'
- Olóòtú ìjọba Sudan, Abdalla Hamdok ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn ìwọ́de àwọn ará ìlú
- Iléewòsàn UCH kò lè bá Aafin Ibadan parọ́, ẹ dẹ́kún gbígbé ìròyìn òfegè nípa Oba Adetunji tó wàjà- Adeola Oloko
- Gomina Wike fi òfin de iṣẹ́ aṣẹ́wó, Night Club, kátàkárà alẹ́ àti àwọn nkan míràn
O tẹsiwaju pe gbogbo awọn ẹka IPO jakejado agbaye ni yoo bẹrẹ si ni se ipolongo lati ri pe wọn tu Kanu silẹ.
Loore koore ni IPOB maa n se agbekalẹ tabi se ikede awọn ofin tọwọ ara wọn.
Bi a ko ba gbagbe laipẹ yi ni wọn kede pe awọn ko ni faaye gba ki idibo waye ni awọn ipinlẹ kan bi Anambra.
Bakan naa IPOB a maa kede konileogbele ti awọn ara ilu a si maa tẹle asẹ wọn.
A ko tii le sọ boya wọn yoo mu ileri wọn se ninu ọdun tuntun yi ati pe ohun to ba sẹlẹ lori ọrọ orin orileede yi yoo jẹ atọna ibi ti ori n bọrun ree ninu ọdun yi.
Bi ikun awọn IPOB lo ba loko ni bi takute ti ijọba Naijiria si ni oju ree iran ree.

















