Ẹgbẹ̀rúndínlàádọ́ta àwọn Agbéṣùmọ̀mí láti ṣekúpa láàrín oṣù méje- Iléeṣẹ́ ológun Nàìjírà

Ileṣẹ ologun Naijiria

Oríṣun àwòrán, @Nig Army

Àjọ ọmọ ogun orílẹ̀ èdè yìí ti ní kò dín ní Ẹgbẹ̀rúndínlàádọ́ta àwọn Agbéṣùmọ̀mí tí àwọn ti rán sọ́run láàárín oṣù Òkùkú 2021 sí oṣù Ṣẹrẹ 2022.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn Agbébọnjà ọ̀jìlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀tadínmẹ́ta ní àwọn ti yọwọ́ wọn kúrò láwo.

Àwọn wọ̀nyìí kò yọ àwọn èèkàn nínú iṣẹ́ láabi ọ̀hún tó fi mọ́ àwọn Emir kan àti àwọn olórí Agbébọnjà méjì ní ìpínlẹ̀ Zamfara, Alhaji Auta àti Kachala Ruga.

Aṣojú Adarí ẹ̀ka ètò ìròyìn,Ogagaun agba Benard Onyeuko lo ṣíṣọ lójú ọ̀rọ̀ ọ̀hú ní ìlú Abuja nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀.

Àkọlé fídíò, Young Tolibian

Ogagun agba Benard Onyeuko fi kun pé ẹgbẹ̀rún kan àwọn ènìyàn tó wà ní àhámọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ni wọn rí gbà.

Àkọlé fídíò, Lori ọrọ Olubadan tuntun

Ó sọ síwájú pé mọ́kàndínlọ́gọ́rin Agbéṣùmọ̀mí ni ó ti wà ní láàárín àkókò yìí.