Àrà mérìírí! Ìbejí tí a bí ní ọdun 2021 àti 2022 pẹ̀lú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dògún láàrin wọn ni America

Aylin ati ikeji rẹ Alfredo

Oríṣun àwòrán, @Natividad Medical Center

Lati ri ibeji ti wọn bi ni ọdun ọtọọtọ ko jẹ ohun to wọpọ.

Amọ o tun ti sẹlẹ ni ilu Califonia, USA nibi ti wọn ti bi awọn ibeji kan ni ọdun meji ọtọọtọ.

Ọmọ tuntun akọkọ, Alfredo Antonio Trujillo ni wọn bi ni ọdun tuntun 2022 ku isẹju mẹẹdogun.

Ekeji rẹ to jẹ ọmọbinrin, Aylin Antonio Trujilo si waye ni gẹẹ ti a wọ ọdun tuntun 2022.

Iya àwọn ibeji naa, Fatima Madrigal so wi pe o jẹ ohun iyalenu wi pe awọn ìbejì oun ni ọjọ ibi meji ọtọọtọ.

Ninu Atejade to fi lede lo ti fi idunu ati iyalẹnu rẹ han wi pe ọmọ obinrin oun tuntun de ni aarin oru.

Àkọlé fídíò, Oba Jose Dome ni Ghana

Eleyii lo mu jẹ ọmọ akọkọ ti wọn yoo bi ni ile iwosan ''Natividad Medical Center - Di Salinas' ni ọdun 2022.

Ọmọ akọkọ, Alfredo ni o gbewọn to din diẹ ninu kilo mẹta, amọ ikeji rẹ, Aylin ni iwọn tirẹ ko to bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Young Tolibian

Ile iwosan Natividad Medical Center - Di Salinas' ti wọn bi awọn ọmọ naa si, woye pe afojusun ẹẹkan pere ninu miliọnu meji ibeji ni wọn maa n bi ni ọdun to yatọ si ara wọn.

Àkọlé fídíò, Lori ọrọ Olubadan tuntun

Bẹẹ naa ni ajọ 'Centers for Disease Control and Prevention' fi ye ni pe ẹgbẹrun lọna ọgọfa ni awọn ibeji ti wọn maa n bi lọdun kan nilẹ America.

Àkọlé fídíò, 'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Eyi si jẹ ida mẹta ninu ọgọrun ninu gbogbo ọmọ bibi to n waye lọdun kan.