Elephant kills women with baby: Erin tẹ obìnrin kan àti ọmọ rẹ̀ pa lọ́jọ́ ọdún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eleduwa ko maa ni jẹ ki a ṣe agbako iku ojiji bi a ṣe n lọ ninu ọdun tuntun yii.
Obinrin kan ati ọmọ rẹ ni erin ti tẹ pa lẹkun ila oorun guusu orilẹede Zimbabwe.
Obinrin naa ni a gbọ pe o n ki awọn ẹbi rẹ kaakiri igberiko Chipinge lọjọ kinni oṣu kinni ọdọn tuntun 2022 yii.
- Orí tèmi kọ́ ni àṣà Ibadan yóò ti dàrú- Rashidi Ladoja
- Àwọn akẹgbẹ́ Gómìnà Sanwo-Olu f'ohùn sílẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìdójútini tó ṣẹlẹ̀ sí i lọ́wọ́ ọlọ́pàá ní Magodo
- Àwọn òṣìṣẹ́ RUGIPO ti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì àìlópin
- Èsì àyẹ̀wò òkú Sylvester Oromoni kò fihàn pé ẹnikẹ́ni ló pa á - Kọmiṣọnna ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
- Nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Bello Turji, afurasí bálógun ajínigbé ní Ariwa Naijiria
- Mọ̀ síi nípa àwọn ọjọ́ tó yàtọ̀ àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú àkọsílẹ̀ láti ṣẹlẹ̀ lọ́dún yìí
Nigba ti obinrin naa n pada bọ wa si ile ni erin lakatabu yii kọlu oun ati ọmọ rẹ ti o si tẹ wọn pa.
Agbẹnusọ ọgba ẹranko ni Zimbabwe, Tinashe Farawo, sọ pe lojiji ni ẹrin ọhun yọ si obinrin yii loju kan naa ti o si tẹ ẹ pa pẹlu ọmọ rẹ.
Amọ wọn ti pa erin naa naa bayii bo tilẹ jẹ pe ohun ti bajẹ ti bajẹ tan.
Ikọlu awọn ẹranko inu igbo atawọn eeyan wọ pọ lawọn igberiko kan lorilẹede Zimbabwe.








