Bello Turji: Afurasí balógun ajínigbé tó n ni ìpínlẹ̀ Zamfara lára

Oríṣun àwòrán, others
Òdú ni orukọ Bello Turjii, kii ṣe aimọ fun gbogbo awọn to n gbe ni Ariwa orilẹ-ede Naijiria.
Ọpọ eeyan lo n sọ pe Turji ni balogun to wa lẹyin awọn iwa ọdaran to n waye ni Iwọ-oorun Ariwa Naijiria.
Lọjọ Iṣẹgun, iroyin jade pe Bello Turji ti yọnda ara rẹ fun ijọba, to si ti tu eeyan bi mẹrindinlọgọta to jigbe lati ile wọn tabi loju popo silẹ.
- Adigunjalè kọlu Kemi Afolabi, wọ́n fi àdá ṣá òun àti awakọ̀ rẹ̀
- Ajimobi kò déédé yan Oba 21, àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Ibadan ló bẹ̀ẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀ náà- Omowe Gbade Ojo
- Mọ̀ síi nípa àwọn ọjọ́ tó yàtọ̀ àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú àkọsílẹ̀ láti ṣẹlẹ̀ lọ́dún yìí
- Ká má rí! Kò sí aàyè fún ìdìbò Gómìnà ní Osun àti Ekiti- Ilana Omo Oodua
- Ìṣẹ̀ṣe, Àṣà àti àwọn ìgbésẹ̀ wọ́nyìí ní a máa fi yan Olubadan tuntun....- Ìgbìmọ̀ Ìṣèjọba Olubadan
Ṣugbọn ṣa, ijọba Naijiria ko ti i fidi awọn ẹsun yii mulẹ. Bakan naa ni ileeṣẹ ologun ko di igba kankan darukọ rẹ gẹgẹ bi ara awọn ọdaran ti wọn doju ija kọ.
Olukọ kan ni fasiti Danfodio, Ọmọwe Murtala Ahmad Rufai sọ awọn nkan ti araye ko mọ nipa Bello Turji fun BBC Hausa.

Oríṣun àwòrán, Sheikh Gumi lo fi aworan Bello yii sita
Nibo lo ti wa?
Ijọba ibilẹ Shinkafi, nipinlẹ Zamfara ni wọn ti bi i.
Lati kekere ni baba rẹ ti ma n mu lọ si ọja ẹran ọsin, gẹgẹ bi iṣe awọn ẹya Fulani.
Ọmọwe Rufai sọ pe ọjọ ori Bello yoo wa laarin ọdun mẹtadinlọgbọn si ọdun marundinlogoji.
"Eeyan daadaa ni baba rẹ, to si n gbe ni alaafia pẹlu awọn aladugbo rẹ ni agbegbe Shinkafi."
Gẹgẹ bi olukọ naa ṣe sọ, gbogbo mọlẹbi Bello lo sa fun-un, nitori wọn ko fẹran tabi faramọ iru iṣẹ buruku to n sẹ.
Koda, "nitori iwa ọdaran to n hu ni baba rẹ ṣe ko kuro ni ilu abinibi rẹ, Kura, to si kọkọ lọ si Kano, ko tun to o fi ipinlẹ Jigawa ṣe ibugbe.
"Gbogbo mọlẹbi rẹ ni ko faramọ nkan to n ṣe. Wọn kii si gba ẹbun kankan to ba ko fun wọn, nitori wọn gbagbọ pe nkan to n ṣe ko dara."
- IPOB fòfin dè kíkọ orin ògo Nàìjíría láwọn ilé ẹ̀kọ́ gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà nítorí pé...
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ Wasiu Eluyẹra tó fẹ́ pa ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó lóyún
- Mọ̀ nípa òfin tuntun tó lé mú kí èèyàn rí ìrànlọ́wọ́ ìjọ̀ba láti gbẹ̀mí ara rẹ̀
- Gomina Wike fi òfin de iṣẹ́ aṣẹ́wó, Night Club, kátàkárà alẹ́ àti àwọn nkan míràn
- Wọ́n ti gbé Olubadan wọ káà ilẹ̀, bí ìsìnkú Ọba Adetunji ṣe lọ nìyí
Ile ẹkọ Keu ni Bello Turji lọ. Ọmọwe Rufai sọ pe Bello ni imọ to pọ ninu ẹsin Islam, ṣugbọn ko lọ ju ile ẹkọ alakọbẹrẹ ti oyinbo .
Gẹgẹ bi balogun ajinigbe, awọn ọmọ awọn gbajumọ lo wa ninu ikọ ajinigbe Bello. Ọmọwe Rufai sọ pe awọn ọmọ ọba kan wa lara wọn.
Lara awọn to darukọ ni:
•Alhaji Auta
•Bello Kagara
•Mallam Ila Manawa
•Umaru Nagona
Fun apẹẹrẹ, o ni ọmọ baalẹ ilu Manawa ni Mallam lla Manawa, ti orukọ rẹ wa lara wọn.
Olukọ naa ṣalaye pe ko ti i pẹ ti Bllo bẹrẹ iṣẹ ijinigbe. Idi ni pe bko ti i dagba pupọ nigba ti ipenija eto aabo bẹrẹ nipinlẹ Zamfara.
Ọmọwe Rufai sọ pe jiji maalu awọn eniyan gbe lo fi bẹrẹ iṣẹ, ko to di akọṣẹmọṣẹ ajinigbe ati janduku.

















