2022 major calender events: Ètò ìdìbò yóò wáyé ni Osun, Ekiti, Kenya, France àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

Oríṣun àwòrán, Others
Kojẹ iroyin mọ pe ọdun 2021 ti pari, bẹẹ sini odun 2022 ti bẹrẹ pẹlu ọpọlọpọ iṣẹlẹ ti won lakalẹ j'ake jado orilẹ ede agbaye.
BBC Yorùbá ti wa ṣalakalẹ di ẹ ninu awọn iṣẹlẹ gbankọgbi ninu ọdun tuntun yii o.
- Oloye Ladoja nìkan ló le sọ bóyá Lekan Balogun yòó di Olubadan tuntun-Moses Orogade
- Ká má rí! Kò sí aàyè fún ìdìbò Gómìnà ní Osun àti Ekiti- Ilana Omo Oodua
- Ìṣẹ̀ṣe, Àṣà àti àwọn ìgbésẹ̀ wọ́nyìí ní a máa fi yan Olubadan tuntun....- Ìgbìmọ̀ Ìṣèjọba Olubadan
- Èsì àyẹ̀wò òkú Sylvester Oromoni kò fihàn pé ẹnikẹ́ni ló pa á - Kọmiṣọnna ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
- IPOB fòfin dè kíkọ orin ògo Nàìjíría láwọn ilé ẹ̀kọ́ gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà nítorí pé...
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ Wasiu Eluyẹra tó fẹ́ pa ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó lóyún
Idije 2021 African Cup of Nations
Idije Ere idaraya bọọlu afesegba nilẹ adulawọ (AFCON 2021) ti o bẹrẹ ni January 9, 2022 ni o ma pari ni Febuary 6, 2022 ni orilẹ ede Cameroon.Wo àwọn agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà tó ti dé fún ìgbáradì àti ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró lóri AFCON 2022
Olugbalejo idije naa, Orilẹ ede Cameroon ati Burkina faso ni o ma ṣide ifaga gbaga ni January 9.
Orilẹ ede Algeria to mọ bọọlu gba julọ nilẹ adulawọ lọwọ yii yoo waako pẹlu Sierra Leone lọjọ kan naa.
Idije gboogi bii AFCON jẹ oun kan pataki ti n so awọn ọmọ ilẹ Africa pọ, paapaa julọ awọn ọmọ Nigeria.
Orilẹ ede Algeria to jẹ oluaye nidi bọọlu afẹsẹgba nilẹ Adulawọ lọwọ yii yoo waako pẹlu Sierra Leone lọjọ kan naa.
Idije ife ẹyẹ agbaye (FIFA World Cup):
Idije ife ẹyẹ agbaye ni ireti wa pe yoo bẹrẹ lorilẹ ede Qatar ni 21 November, 2022 ti yio si pari ni 18 December, 2022.
Eyi ni yio jẹ igba akọkọ ti ilẹ Arab yio gbalejo idije naa.
Idije Winter Olympics
Idije Winter Olympics ti ọpọ eeyan n pe ni Beijing 2022 yio waye ni February 4 si 20 nilu Beijing lorilẹ ede China.
Beijing ni wọn buwọlu bi olugbalejo idije naa nibi ipade kedidinlaadoje ajọ IOC nilu Kuala Lumpur lorilẹ ede Malaysia ni 2015.
Idibo sipo gomina Osun:
Idibo sipo gomina nipinlẹ Osun yio waye ni July 16, 2022.
Gomina Gboyega Oyetola lo wa lori aleefa lọwọ nipinlẹ naa to si jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC
Gomina ọun lo lẹtọ lati dije lẹẹkeji toripe saa akọkọ lo n lo lọwọ.
Gboyega lo f'agba han Senator Ademola Adelekwe ti ẹgbẹ oṣelu PDP nibi idibo sipo gomina to waye nipinlẹ naa lọdun 2018 gẹgẹ bi esi ti ajọ INEC fi lede.
Idibo apapọ odun 2023.
Awọn oloṣelu yio bẹrẹ sii gbaradi fun idibo apapọ ọdun 2023 lọdun yi, bẹẹ si ni ireti wa pe ọpọ ninu wọn yio paarọ ẹgbẹ oṣelu ti wọn wa.
Pupọ ninu awọn oloṣelu wọnyi ni wọn yio maa darapọ mọ ẹgbẹ miran nireti ati jawe olubori.
Ọpọlọpọ ni yio bẹrẹ ipolongo ti wọn yio si maa ṣe oriṣiriṣi ileri fawọn oludibo.
Idibo apapọ Kenya
Idibo apapọ ti kenya naa ni oma waye ni August 9, 2022.
Awọn ọmọ orilẹ ede Kenya ni won ma dibo fun aarẹ orilẹ ede, awọn ọmọ ile igbimọ asofin togajulo, gomina ipinlẹ ati aṣofin ipinlẹ.
Uhuru Kenyatta ni aare ti owa lori aleefa lọwọ.
Adari igbimọ ijọba tẹlẹ ri ni orilẹ ede Kenya Raila Odinga ti sọpe oun ti ṣetan lati dije fun ipo aare ki oun le gba ijọba lọwọ kenyatta.
Idibo Aarẹ lorilẹ ede France
Eto idibo fun Aarẹ orilẹ ede France ni yoo bẹrẹ ni April 10, 2022 ti yoo si pari ni April 24, 2022.
Emmanuel Macron ni Aare orile-ede France ti oti wa lori aleefa lati May 14, 2017.
- Mo ti ra ilẹ̀ ìsìnkú mi ní 'Ebony Vault' ṣùgbọ́n....
- Kí ló dé tí Taliban fí fòfin dè kí àwọn obìnrin máa dá rírìn àjò tó bá ti jiná?
- Ìròyìn BBC Yorùbá Márùn-ún tí ó mí ìgboro tìtì lọ́dún 2021
- Àṣìṣe ńlá gbáà ni, a ò mọ̀ọ́mọ̀ tẹ ASP ọlọ́pàá pa - Ilé isẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé lọdún 2021
Ìgbéjọ́ Sunday Igboho
Sunday Adeyemo ti gbogbo aye mọ si Sunday Igboho ni o jẹ ọmọ Yoruba to n ja fun ominira ilẹ Yoruba to si wa ni ihamọ lorilẹ ede Benin Republic.
Sunday Igboho lo ti wa ni ihamọ lati July 19, 2021 ti wọn ti fi panpẹ ọba muu ni papakọ ofurufu Cadjehoun ni Cotonou.
Ṣaaju ki wọn to muu ni Cotonou ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lorilẹ ede Nigeria kede rẹ bi ẹni ti wọn n wa latari ẹsun kiko ohun ija oloro pamọ.
Ijọba ilẹ Benin lo fi ẹsun kan Igboho pe o wọ orilẹ ede naa lọna aitọ ati pe o fẹẹ da laasigbo silẹ nilẹ wọn amọ ti Igboho sẹ gbogbo ẹsun naa.
- Wo bí àwọn gbajúmọ̀ tí ẹ̀ fẹ́ràn yìí ṣe tẹ̀ẹ́ wọ́nú ọdún 2022 àtí ohun t'Ọ́lọ́hun gbé wọn borí
- Ohun tí CAN fi ṣíde ọdún 2022 fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà nìyí
- Australia, New Zealand, Japan,àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ṣáájú Nàìjíríà wọ ọdún 2022
- Ikú d'óróó! Àjálù ikú míì tún ṣe Pásítọ̀ Taiwo, ọkọ Bimbo Odukoya
- Àsọtẹ́lẹ̀ 2022 àti ìgbésẹ̀ tí Pásítọ̀ Enoch Adeboye fẹ́ gbé lórí ìdojúkọ Nàìjíríà nìyí
Bo tilẹ jẹ pe Pelumi Olajengbesi to jẹ agbẹjọro Igboho ti yọwọ ninu ẹjọ ọun, sibẹ ẹjọ naa yio tẹsiwaju lọdun yi.
Ọpọ eeyan lo kawọ gbera lati wo ohun ti yio kẹyin ẹjọ ọun.
Boya wọn yio da Igboho pada sorilẹ ede Nigeria abi awọn alaṣẹ ilẹ Benin yio tẹsiwaju lati fi si ipamọ, asiko diẹ lo ku.
Igbẹjọ adari IPOB, Nnamdi Kanu
Adari ẹgbẹ IPOB ti ijọba Nigeria ti fi ofin de, Nnamdi Kanu ṣi wa ni ihamọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS.
Kanu ni wọn fi oriṣiriṣi ẹsun kan bi iwa ipaniyan and iṣọtẹ si ijọba.
Igbẹjọ naa ni oma tẹẹ siwaju lọdun yii bẹẹni ọpọlọpọ eniyan ni won n reti boya ile ẹjọ ma da Kanu lẹbi.
Igbẹjọ naa ni wọn ti fisi January 19th and 20th 2022.
Ayẹyẹ aadọrin lori itẹ ti Queen Elizabeth
Ọdun 2022 ni o ma pe aadorin ọdun ti Queen Elizabeth di Ọbabirin ilẹ England.
Ọmọ ọdun mẹẹdogbon ni Elizabeth ni igba ti odi Ọbabirin ni ọdun 1952.
- Olóòtú ìjọba Sudan, Abdalla Hamdok ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn ìwọ́de àwọn ará ìlú
- Wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí ní ilé Oloye Lekan Balogun tí wọ́n n sọ pé oyè Olubadan kàn
- Mọ̀ nípa òfin tuntun tó lé mú kí èèyàn rí ìrànlọ́wọ́ ìjọ̀ba láti gbẹ̀mí ara rẹ̀
- Koiki àti Olajengbesi ń jíṣẹ́ ara wọn ni, Igboho kọ́ ló rán wọn níṣẹ́, Agbẹjọ́rò Sunday Igboho faraya
- Gomina Wike fi òfin de iṣẹ́ aṣẹ́wó, Night Club, kátàkárà alẹ́ àti àwọn nkan míràn
Ọbabirin Elizabeth ni Ọba akọkọ nilẹ gẹẹsi ti oma lo aadọrin ọdun lori itẹ.
Awọn eleto ọrọ owo ti gbe owo tuntun jade lati ṣ'ami ọdun 2022 ati ajọdun Ayẹyẹ aadọrin ti Queen Elizabeth
Ọpọlọpọ ọdun ni wọn lo lati fi ṣe agbekalẹ apẹẹrẹ owo eyi ti won fi ṣ'ami awọn ayẹyẹ pataki yii.























