Afcon 2022: Àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí balẹ̀ sí ibùdó ìgbáradì ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles

Agbaboolu Naijiria

Oríṣun àwòrán, @NFF

Ahmed Musa, Odion Ighalo, Kelechi Iheanacho wà lára àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n lo tí balẹ̀ sí ibùdó ìgbáradì ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles ni ìgbáradì fún ìdíje ife ẹ̀yẹ Africa Cup of Nations (AFCON).

Àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n lo tí balẹ̀ sí ibùdó ìgbáradì ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles ni ìgbáradì fún ìdíje ife ẹ̀yẹ Africa Cup of Nations (AFCON).

Ìdíje AFCON yóò wáyé fun oṣù bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Ṣẹẹrẹ títí di ọjọ́ kẹfà, oṣù Èrélé, ọdún 2022 ní orílẹ̀ èdè Cameroon.

Ìròyìn fi yé wa pé àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n lo tí balẹ̀ sí ibùdó ìgbáradì nínú àwọn méjìdínlọ́gbọ̀n tí akọ́nimọ̀ọ́gbá fìdíẹ́ fún ikọ̀ Super Eagles, Augustine Eguavoen ráńṣẹ́ sí láti kópa nínú ìdíje náà.

Ní ọjọ́ Ọjọ́rú tó ń bọ̀ yìí ni ikọ̀ Super Eagles yóò fi orílẹ̀ èdè Nàíjíríà sílẹ̀ lọ sí orílẹ̀ èdè Cameroon.

Àkọlé fídíò, Big Abass gbadura ọdun tuntun fún gbogbo ololufe rẹ

Ẹwẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Super Eagles láti ilẹ̀ òkèerè ló ṣì ń wọ ibùdó ìgbáradì lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.

Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn oṣù kan tí àjọ NFF ti fi orúkọ àwọn agbábọ́ọ̀lù tí wọ́n ráńṣẹ́ sí léde.

Bákan náà, àwọn agbábọ́ọ̀lù mìíràn ń fi ibùdó ìgbáradì sílẹ̀ látaàrí ìfarapa àti àìsàn.

Gẹ́gẹ́ bí àlàyé àjọ Confederation of African Football (CAF), rẹfirí mẹ́rìnlélógún àti igbákejì rẹfirí mọ́kànlélọ́gbọ̀n láti orílẹ̀ èdè mẹ́rìndínlógójì ni yóò kópa nínú ìdíje náà.

Àkọlé fídíò, O tó ìdá méjì àwọn ènìyàn àgbáyé to wà nínú ewu àìsàn ibà

Orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, Egypt , Sudan àti Guinea Bissau tó ń ṣẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ló wà nínú gúrùupù kan náà.

Àkọlé fídíò, Prophet Hezekiah New Year Prayer: Gbogbo wa ni ká ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè Naijiria

Awon ti wọn pee ree ati orukọ ẹgbẹ agbabọọlu ti wọn n gba bọọlu fun ki Naijiria to ranṣẹ si wọn:

Adilemu:

Francis Uzoho (AC Omonia, Cyprus)

John Noble (Enyimba FC)

Daniel Akpeyi (Kaizer Chiefs, South Africa)

Maduka Okoye (Sparta Rotterdam, The Netherlands)

Àkọlé fídíò, New year prayers: Gbọgbọọgbọ lọwọ́ n yọ ju orí, gbogbo wa laó yọ ju ọ̀tá wa lọ

Atamatase:

Ahmed Musa (Fatih Karagumruk, Turkey)

Henry Onyekuru (Olympiacos FC, Greece)

Moses Simon (FC Nantes, France)

Sadiq Umar (UD Almeria, Spain)

Taiwo Awoniyi (Union Berlin, Germany)

Alex Iwobi (Everton FC, England)

Peter Olayinka (SK Slavia Praha, Czech Republic)

Àkọlé fídíò, Orí Tẹlifísàn ni mo ti rí Sunday Igboho rí láyé mi, bí ìyà ṣe jẹ mi gbé láti Ibadan, dé Àtìmọ́lé DSS rèé - Ifasooto Dada

Kelechi Iheanacho (Leicester City, England)

Awọn Agbbọọlu laarin lori Papa

Frank Onyeka (Brentford FC, England)

Wilfred Ndidi (Leicester City, England)

Chidera Ejuke (CSKA Moscow, Russia)

Kelechi Nwakali (SD Huesca, Spain)

Àkọlé fídíò, Ṣé o mọ̀ ipò tí ìlú Owo l'Ondo ní lórí ìtẹ́ Ile Ife? Ẹ kálọ sí ìlú mi

Awọn Agbabọọlu to n di ẹyin ile mu:

Chidozie Awaziem (Alanyaspor FC, Turkey)

Kenneth Omeruo (CD Leganes, Spain)

Oluwasemilogo Ajayi (West Bromwich Albion, England)

William Ekong (Watford FC, England)

Olaoluwa Aina (Torino FC, Italy)

Zaidu Sanusi (FC Porto, Portugal)

Olisa Ndah (Orlando Pirates, South Africa)

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Awon miran ti wọn tun pe ni:

Jamilu Collins (SC Padeborn 07, Germany)

Tyrone Ebuehi (Venezia FC, Italy)

Joseph Ayodele-Aribo (Glasgow Rangers, Scotland)

Samuel Chukwueze (Villarreal FC, Spain)

Odion Jude Ighalo (Al-Shabab Riyadh, Saudi Arabia)