Olubadan in Council: Ìṣẹ̀ṣe àti àwọn ìgbésẹ̀ wọ́nyìí ní a máa fi yan Olubadan tuntun- Ìgbìmọ̀ Olubadan

Aafin Olubadan

Oríṣun àwòrán, Others

Àwọn mẹ́wàá nínú ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mọ́kànlá to jẹ Afọbajẹ ni ìlú Ìbàdàn ti buwọ́lu yiyan Senetọ Lékan Balógun gẹ́gẹ́ bíi Olúbàdàn tuntun.

Ìgbìmọ̀ ọ̀hún tún làá mọ́lẹ̀ pé awuyewuye tó ń wáyé kò lè dínà ẹni tí oyè tọ́ sí gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn láti bọ́ sí orí àpèrè.

Olóyè Òsì Balógun ìlú Ìbàdàn, Tajudeen Ajíbọ́lá ló sọ èyì fùn àwọn akọ̀ròyìn l'ọ́jọ́ Rú.

Olóyè Tajudeen Ajíbọ́lá ní gẹ́gẹ́ bí àṣà ìlú Ìbàdàn, olóyè Balógun ni Olúbàdàn kàn.

Bákan náà ló fi kun un pé koko lara ọta olóyè Balógun le wí pé irọ̀ tó jìnà sí òótọ́ ni pé òjòjò ń ṣe ògún rẹ̀.

Ó ní àhesọ lásán ni gbogbo awuyewuye tó ń lọ lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Àkọlé fídíò, Lori ọrọ Olubadan tuntun

Kini A'sa ilu Ibadan sọ nipa yiyan Olubadan tuntun?

Ni ọpọlọpọ ilu ni ilẹ yoruba, ifa ni o ma n ṣe itọni sọnọ lori ẹni ti o maa jọba lẹyin ti ọba kan ba gbesẹ.

Amọ ni ilu Ibadan, gbogbo ọmọ ilu ni o lẹtọ ati jẹ Olubadan.

Àkọlé fídíò, 'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Oun ti ọ se pataki ni ki ẹni naa jẹ oloye ti osi ma gun akasọ to yẹ ki o to di Olubadan.

Ọna meji ti wọn gba gun akasọ ki wọn to di Olubadan ni lati idi Ẹgbẹ agba ati Ẹgbẹ Balogun.

Ti Olubadan bati gbesẹ, eni to ba kan ninu awọn Oloye agba lati idi mejeeji ni wọn maa de lade gẹgẹ bi Ọba titun.

Àkọlé fídíò, Big Abass gbadura ọdun tuntun fún gbogbo ololufe rẹ

Amọ, tito ni wọn ma n to laarin idi mejeji náà nitori pe ti Olubadan kan ba jẹ lati idi ẹgbẹ Agba, ẹgbẹ Balogun ni Olubadan ti yoo jẹ lẹyin rẹ yoo ti wa.

Lati idi ẹgbẹ agba, ipo Jagun ni akasọ akọkọ lẹyin naa ni Akasọ mọkanlelogun (21) ki oloye naa to di Olubadan.

Àkọlé fídíò, Ọdún tó súnmọ́ ìdìbò ni 2022, wọ́n ó ni ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀

Lati idi ẹgbẹ Balogun, akasọ mejilelogun (22) ni o ṣẹ pataki ki enikeni o gun ko to le di Olubadan lẹyin ti o ba tijẹ oye Jagun.

Olubadan to ṣẹṣẹ gbesẹ, Oba Saliu Adetunji, ni o di Olubadan lẹhin ọdun mejidinlogoji tojẹ oye Jagun.

Ìṣẹ̀ṣe, Àṣà àti àwọn ìgbésẹ̀ wọ́nyìí ní a máa fi yan Olubadan tuntun....- Ìgbìmọ̀ Ìṣèjọba Olubadan

Báyìí ni aṣẹ ma yan Olubadan titun oo- Olubadan-in-Council

Igbimọ iṣejọba Olubadan, iyen Olubadan-in-Council ti sọ pe awọn yoo tẹle aṣa ilu Ibadan lati yan Olubadan titun bo tilẹ jẹ pe àwọn ti jọba tẹlẹ rí.

Wọn ni Aṣa ati Iṣẹṣẹ lagba gbogbo eniyan.

Iroyin yi ni wọn fi lede lẹyin ti wọn ṣe ipade ni ile Oloye àgbà Lekan Balogun ti o jẹ Ọtun Olubadan.

Amọ, Oloye giga Rashidi Ladọja ti o jẹ gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ọyọ ati ọmọ ẹgbẹ igbimọ asejọba Olubadan pẹlu awọn meji miran ni ko kopa ninu ipade naa.

Àkọlé fídíò, Bi mo ṣe fi Ọtí, Igbó, Sìgá mímu sílẹ̀ tí mi ò kó obìnrin tó máa ń ba ayé awọn olórin jẹ́ - J.A Adelakun tó kọ orin "Amona tete

Lẹyin ipade ọun, oloye Balogun salaye pe lẹyin ti wọn ba ti ṣọfọ Ọba Saliu Adetunji tan, wọn yio ṣe ipade mii lati kede Olubadan titun gẹgẹ bi aṣa ilu Ibadan.

Lekan Balogun ṣalaye pe kosi laasigbo lori ẹni ti yio jẹ olubadan titun o.

Àkọlé fídíò, O tó ìdá méjì àwọn ènìyàn àgbáyé to wà nínú ewu àìsàn ibà

O fi kun ọrọ rẹ pe igbega awọn ọmọ igbimọ naa si ọba ko ṣe idiwọ fun aṣa ati iṣe iṣembaye yiyan olubadan titun sipo.

Balogun wa fi da awọn ọmọ Ibadan nile loko loju pe kosi ewu loko nitori pe gẹgẹ bi afọbajẹ ilu Ibadan, awọn yio ṣe ohun totọ lasiko toyẹ.